Akomolede Eko round up: Àwọn Olùkọ́ ìpínlẹ̀ Eko dárà lórí Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC

Akomolede

Akomolede ati Asa lori BBC Yoruba jẹ ọkan lara eto akanse ti BBC Yoruba ṣagbekalẹ rẹ fun igbadun ẹyin ololufẹ wa.

Eto naa jẹ ajọṣepọ ẹgbẹ awọn Onimọ Yoruba, iyẹn Yoruba Studies Association of Nigeria àti apapọ ẹgbẹ Akomolede Naijiria.

Ipinlẹ Eko ni a ti bẹrẹ pẹlu awọn akọsẹmọṣẹ Olukọ lati ipinlẹ Eko

Àkọlé fídíò, Ìtàn ọ̀rẹ́ tó fi ògùn gba ọkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Akomolede BBC Yorùbá fẹ́ kọ́ wa lònìí

Arabinrin Olaitan Zainab kọ nipa iwe: Ọrẹ Mi ninu ẹkọ oke yii.

Ile iwe Gbagada Girls Junior school ni olukọ wa ti wa.

o ṣalaye iru oju ti ọrẹ meji fi wo ọkunrin kan ti wọn pade ti ọkan fi oju tẹmbẹlu rẹ amọ oun gan lo pada n wa lati fa oju rẹ mọra tori owo

Ṣe ẹ ranti bi inu kilaasi yin ṣe maa n ri lasiko ti ẹ ba fẹ ka awọn iwe ayọka Yoruba nigba ti ẹ ṣi wa nileewe girama?

Àkọlé fídíò, Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá

Arabinrin Faleke lo kọ wa nipa oge sise ninu ẹkọ ti Oke yii.

Ile iwe Ikeja Central Primary School ni olukọ wa lori oge ṣiṣe ti wa.

Oge sise laye atijọ ati laye ode oni pẹlu awọn apẹrẹ loriṣiriṣi ni wọn fi kọ wa lọsẹ naa.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Oriṣi ẹya litireṣọ Yoruba to wa ati ọna ti koowa n gba jẹyọ ni alagba Lawanson Olumuyiwa kọ wa ninu ti oke yii.

Litireṣọ alohun ati apilékó tun jẹyọ pẹlu awọn apẹẹrẹ to yẹ ni a gbe yẹwo

Àkọlé fídíò, Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú "Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ - Noun Phrase

Arabinrin Adeyẹmọ lati Oke Ira Junior High school yannana Isọri Orọ Yoruba.

Apola Orukọ ni olukọ wa sọrọ ni kikun le lori.

Mọ sii nipa ẹka isọri ọrọ Yoruba.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Mọ̀ si nípa oríṣìí ẹ̀ka ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ àti ìwúlò wọn

Aya Peters sọ ohun ti apola orukọ jẹ lati ile iwe Ogba Junior Grammar school.

Awọn akoonu gbolohun kọọkan ati koṣeemani ninu ọrọ Yoruba ni Olukọ wa ṣlaye fun wa.

Eyin Olukọ Yoruba ni ipinlẹ Eko ati alaga ati awọn oloye ẹgbẹ Akomolede to ku, BBC n dupẹ lọwọ yin fun iṣẹ takuntakun ti ẹ ṣe ti ẹ fi kọ wa ni awọn koko ọrọ wọnyii.