Charlie Hebdo: 'Cartoon' nípa Anọbi Muhammed kó Ọ̀jọ̀gbọ́n kan sí ìyọnu ní Egypt

Egypt

Oríṣun àwòrán, Getty Images

'Cartoon' nípa Anọbi Muhammed kó Ọ̀jọ̀gbọ́n kan sí ìyọnu ní Egypt.

Ọjọgbọn kan ninu imọ igbeaye ẹda, lorilẹ-ede Egypt ti gba iwe idaduro ranpẹ lẹ́nu isẹ nitori o sọ erongba rẹ lori fiimu 'cartoon' Charlie Hebdo.

Iwe iroyin kan lorilẹ-ede France ni Charlie Hebdo, ti ọpọlọpọ eeyan si n bu ẹnu ẹtẹ lu 'cartoon' kan to ma n gbe sita nípa Anọbi Muhammad.

Wọn ni o n ṣorọ odi si ẹṣin Islam ni.

Sugbọn awọn alasẹ iwe iroyin naa sọ pe awọn fi n polongo tako aini ìpamọ́ra, ìjẹ gàba ati eto oṣelu Islam, to n dunkooko mọ isejọba awaarawa.

Koda, iroyin sọ pe nitori 'cartoon' naa ni ikọlu ṣe waye ni sọọsi kan ni France laipẹ yii.

Ori eto igbohunsafẹfẹ kan lori ayelujara ni Ọjọgbọn naa ti sọrọ.

Awọn akẹkọọ ileewe Higher Institute for Social Work, si lo kọ iwe ẹsun mọ Ọjọgbọn Mohammed Mahdali, nitori pe ọrọ to sọ "bi wọn ninu".

Koda, wọn fi fidio ibi to ti sọ ọrọ naa si gbangba, lẹyin ti oun fúnra rẹ mu kuro lori ayelujara, to si tọrọ aforijin.

Lẹyin naa ni Minisita fun eto ẹkọ nileewe giga pasẹ pe ko lọ rọọkun nile naa, ati pe ki iwadii ijinlẹ waye lori ẹsun ti wọn fi kan.

Àkọlé fídíò, Bose Okeowo: Àárẹ̀ kékeré ló sọ mi dí aláàbọ̀ ara yìí ṣùgbọ́n...