Nigerian Navy Ondo: Ikọ̀ ọmọogun orí omi fi páńpẹ́ mú olè mẹ̀rìnlélógún tó ń jí epo rọ̀bì

Adigunjalè

Oríṣun àwòrán, Google

Ileeṣẹ ọmọogun oju omi ni okeere tan awọn ti fi panpẹ ọba mu awọn ole mẹrindinlogun nibi ti wọn ti n ji epo rọọbi ji nipinlẹ Ondo.

Ileeṣẹ ọmọgun naa ni ikọ Forward Operating Base(FOB) ni Igbokoda lo mu awọn ole naa ni agbegbe ijọba ibilẹ Ilajẹ ni ipinlẹ Ondo.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro lo fi idi ọrọ naa mulẹ.

Ọjọ Kẹtala, Oṣu Kini, ọdun 2021 ni awọn fi oju awọn ole naa han kaakiri ipinlẹ Ondo.

Wọn ni wọn ri awọn ole naa mu lasiko ti ikọ naa ṣe iṣẹ wọn lasiko awọn oju omi naa.

Adari ikọ ọmọogun oju omi naa, Shuaibu Muhammed-Ahmed, ni awọn ọmọogun naa mu ileri wọn ṣẹ lati fi oju awọn aṣebajẹ han ni agbegbe oju omi to wa lorilẹede Naijiria.

Ikọ ọmọogun

Oríṣun àwòrán, Nigerian Navy

Lara awọn ohun ti wọn rigba pada lọwọ awọn adigunjale naa ni epo rọọbi to le ni lita ẹgbẹrun lọna igba(150 drums of 250 litres), ohun ifa epo, ati awọn engine nlanla.

Bakan naa ni wọn ri ọkọ oju omi gba pada to si kun fun lita to le ni ẹgbẹrun mẹrin.

Ileeṣẹ ọmọogun naa wa kesi awọn eniyan lawujọ, paapaa awọn agbegbe to wa ni eti omi lati ri wi pe aabo ẹmi ati dukia jẹ wọn loju.

Wọn fikun un wi pe gbogbo awọn ẹsọ alaabo ni o ti fi ọwọ sowọpọ loti ri wi pe awọn adigunjale ati awọn oniwakiwa miran ko ni ba dukia awọn eniyan ati ọrọ aje orilẹ-ede Naijiria jẹ.

Àkọlé fídíò, Ado Ekiti Blind Couple: Tọkọ-taya Oke ní Ọ́ba òkè ló fi àwọn dá àrà tó wù ú