Covid-19: Oluwo ní àṣẹ Ọlọ́run ni pé coronavirus ò lè wọ ìlú Iwo, àmọ́ òun ń wọ ìbòmú tórí olórí t'óun jẹ́

Oríṣun àwòrán, Instagram/oluwoofiwoland
Oba AbdulRasheed Akanbi, Oluwo ti ilẹ Iwo ti sọ idi to fi n wọ ibomu lẹyin to ti sọ tẹlẹ pe arun coronavirus ko le wọ Iwo laelae.
Oluwo sọ fun BBC Yoruba pe oun si duro lori ọrọ ti oun sọ pe covid-19 ko le wọ ilẹ Iwo, ṣugbọn oun n lo ibomu nitori ipo olori ti oun wa ni.
''Aṣẹ Ọlọrun Ọba ni pe gbogbo arun bi coronavirus ko le wọ ilẹ Iwo, ohun lo jẹ ki sọ tẹlẹ pe covid-19 ko gbọdọ wọ ilu Iwo.
- Àbámọ̀ ni yóò gbẹ̀yin ẹgbẹ́ ''Association of Stingy Men'' tí kò fẹ́ náwó f'óbìnrin- Akeugbagold
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlà lọ́sẹ̀ tó kọjá tó fi mọ́ bí Covid-19 ṣe gbẹ̀mí èèyàn 23 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Covid-19: Ilé aṣojú-ṣòfin l'Abuja dábàá kí ìjọba sún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ síwájú pẹ̀lú oṣù mẹ́ta
- Mo ti ní ìyàwó àfẹ́sọ́nà, ayẹyẹ ìgbeyàwó mi ń bọ̀ láìpẹ́ - Lateef Adedimeji
- Irọ́ ni pé ọba tuntun má a ń jẹ ọkàn ọba tó bá wàjà ní ìpèbí - Elebuibon
- Èèyàn 1,598 míì tún ti lùgbàdì covid-19 ní Nàijíríà, 1,420 ló ti kú báyìí
Mo si tun sọ pe ki arun coronavirus to ba fẹ wọ Iwo pe ki o wa mu mi nitori ọfiisi Ọlọrun ni mo wa, ti coronavirus ba ti mu mi, o ti mu Ọlọrun naa niyẹn.
Nitori emi kọ ni ọba, Ọlọrun ni ọba. Ọdọ rẹ si ni gbogbo arun ati gbogbo nkan wa.
Lati igba ti mo si ti paṣẹ yii naa, ko si ẹni to ko arun coronavirus niluu Iwo, amọ Ọlọrun ni ilu Iwo nikan ni Oun fun mi.
Awọn ọba ilu miiran naa to ba lẹmi iru rẹ le paṣẹ bẹẹ niluu ti wọn naa,'' Oluwo lo sọ bẹẹ.
Oluwo ni oun si gbagbọ pe ẹnikẹni to ba gbe ailera wọ ilu Iwo, aṣẹ naa loun maa pa ti Ọlọrun yoo si fun wọn lalaafia.
Kabiyesi ni oun n wọ ibomu lati jẹ awokọṣe rere fawọn ọmọ Naijiria nitori ifẹ ti oun ni si wọn.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Oluwo ni ko ni boju mu ki oun maa lo ibomu lawujọ gẹgẹ bi olori.
Oba AbdulRasheed Akanbi gbadura pe ki Eleduwa ''ba wa le covid-19 wọlẹ lọ ni Naijiria.''
''Mo fẹ ki ọrọ aje Naijiria pada gbeeru si, kawọn eeyan si wa lalaafia kaakiri orilẹede Naijiria,'' Oluwo lo sọ bẹẹ.


















