Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

Àkọlé fídíò, Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

Yoruba ni ẹnu ẹni laa fi n pe Temidire nitori ohun ta ba beere, bẹẹ ni yoo ri.

Ohun ti Ibitoye Olatunde Michael gba lero pe ọkọ ti oun ba se funra ara oun, ni oun yoo kọkọ lo, ti wa si imusẹ.

Olatunde, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe ọdun 2016 ni oun bẹrẹ si jo irin mọ irin lati se mọto naa, to si gba oun ni odidi ọdun mẹta ko to pari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ Olatunde ni aisi owo lo mu ki msto naa pẹ, ko to dide amọ ti owo ba wa, ko gba oun ju osu mẹta lọ.

Ọkunrin naa to kẹkọjade nile ẹkọ fasiti ni ẹka imọ nipa eweko tun fikun pe oun ko ms isẹ ajorinmọrin tẹlẹ, amọ aniyan oun lo ti oun de idi rẹ.

O ni ọda owo, ohun eelo ati irinsẹ lo n da oun laamu, erongba oun si ni lati maa se mọto fun lilo awọn ọmọ Naijiria.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: