Oluwo Jogbodo Orunmila: Oluwo sọ ìtàn bí Orunmila ṣe jìyà nílùú Iwo àti ayọ̀ tó gbẹ̀yìn rẹ̀ torí sùúrù

Àkọlé fídíò, Itaniji: Oluwo sọ ìtàn bí Orunmila ṣe jìyà nílùú Iwo àti ayọ̀ tó gbẹ̀yìn rẹ̀ torí sùúrù

Yoruba ni Suuru ni baba iwa, ibinu ko si da nnkan fun ẹnikẹni, abuku ni ko ba ni.

Bi onibinu ati alagidi ba si fi ogun ọdun sisẹ, ọjọ kan soso ni yoo fi ẹsẹ yi danu.

Oluwo, ninu ọrọ itaniji wa fun ti ọsẹ yii, salaye ohun to faa ti wọn fi n pe aya ni iyawo ati bi Orunmila se jiya niwo amọ to se suuru, eyi to mu ki ayọ gbẹyin ọrọ rẹ nigbẹyin.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa gba awọn ọdọ nimọran lati maa ni suuru, ki wọn si pa ibinu ti nitori suuru ni baba iwa, agba to ba si ni suuru, ohun gbogbo lo ni.

Oluwo ni ẹni to ba ni suuru, yoo ni ifarada, ipamọra ati gbogbo nnkan.

Fun iwọ ti o jẹ onibinu, oninufufu ati alagidi, ẹ sunmọ ibi kẹ wa kọgbọn lati ẹnu baba awo Oluwo Jọgbọdọ Orunmila.