Oluwo Jogbodo: Ìmẹ́lẹ́ jẹ́ orísun àìnílárí, Ifá ṣe ìkìlọ̀ rẹ̀ fáwọn ará Ibadan kí wọ́n tó làlùyọ-Olúwo Jọ̀gbọ̀dọ́

Àkọlé fídíò, Oluwo Jogbodo Series: Ìmẹ́lẹ́ jẹ́ orísun àìnílárí, Ifá ṣe ìkìlọ̀ rẹ̀ fáwọn ará Ibadan kí

Lọsẹ yii, lori ọrọ iṣiti ọlọọọsẹ BBC News Yorùbá pẹlu Oluwo Jọgbọdọ ti a pe ni "Itaniji lori BBC News Yoruba", titẹpa mọṣẹ, jijina si iwa imẹlẹ la gbe yẹwo.

Ohun ti eyi si tumọ si pe ko si iṣẹ kan to ṣe e fi ọwọ rọ sẹyin ninu iṣẹ aṣejẹ ẹda. Iba jẹ iṣe birikila, iba jẹ iṣẹ apọnmita, iṣẹ ni iṣẹ njẹ.

Koda awọn agba bọ wọn ni iṣẹ kii pa ni, aiṣe rẹ gan an ni abuku.

A mu ọrọ iṣiti ọtẹ yii jade lati inu ẹsẹ ifa to ys si awọn ara Ibadan ni igba iwasẹ nipa titẹpa iwa imẹlẹ.

Eekan agbaṣaga, Oluwo Jọgbọdọ tun mu ọrọ itaniji jade, paapaa fun awọn ọdọ lori titẹpa mọ ẹkọ tabi iṣẹ ti wọn ba yan laayo nitori iṣẹ ni mu ni bọ loko igbekun oṣi ati iṣẹ.