Ritual killers: : Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tó gé ojú-ara ọmọdébìnrin ọdún mẹ́fà fún ètùtù ọlà

Ọwọ ọmọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ariwo eemọ, irú kileyi lo ṣi n gba ẹnu ọpọ eniyan ni Naijiria, nitori iroyin kan to jade pe awọn eeyan buruku kan gé abẹ́ ọmọbìnrin ọdun mẹfa nipinlẹ Bauchi.

Iroyin sọ pe ọgbọnjọ, oṣu Kejila, ọdun 2020 ni iṣẹlẹ naa waye.

Botilẹjẹ pe ọmọdébìnrin naa si n gba itọju nileewosan, agbenusọ awọn ọlọpaa nipinlẹ Bauchi, DSP Muhammad Wakil sọ nkan ti awọn obi le ma a ṣe lati daabo bo awọn ọmọ wọn lọwọ irú awọn ọdaran bẹ ẹ.

"Nkan akọkọ ni pe ki awọn obi o ma a mojuto ìrìn ọmọ wọn; mọ ibi to wa, awọn to wa nibẹ pẹlu rẹ ati nkan to n ṣe."

Nkan keji ni pe da ẹnikẹni to ba n pe ọmọ rẹ ni ọkọ tabi iyawo mi, lẹ́kun.

Idi ni pe nipasẹ iru nkan bẹ ẹ lo ti n bẹrẹ, titi ti nkan buruku yoo fi ṣẹlẹ.

" Ti o ba fi aaye gba ẹnikẹ́ni lati ma a pe ọmọ rẹ to jẹ ọmọde ni iyawo mi, o ma n mu ki iru ọmọ bẹ ẹ gba ki ẹni naa ṣe ohunkohun to wu si i."

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye Ọga ọlọpaa naa sọ pe iṣẹlẹ to ṣẹlẹ sì ọmọ ọdun mẹfa yii jẹ ọkan lara awọn nkan to buru ju ti oun riri gẹgẹ bi ọlọpaa.

" Eletutu ọlà kan lo ni ki awọn ọdọmọkunrin mejeeji lọ mu ojú ara ọmọdebinrin wa, ki wọn o le di olowo.

Ohun lo mu ki wọn o fi ọgbọn tan ọmọ ọdun mẹfa naa pe awọn fẹ ẹ ran nisẹ.

Nise ni wọn fi aṣọ penpe bo ẹnu rẹ, ti wọn si gbe lọ sinu ile kan ti wọn n kọ lọwọ.

" Ninu ile naa ni wọn ti fi nkan ge idọ 'clitoris' rẹ ti eletutu sọ pe yoo sọ wọn di olowo.

Wọn fi ọmọ naa silẹ ninu agbára ẹjẹ, wọn si salọ.

" DSP Wakil tun sọ pe ọwọ ti tẹ ẹnikan lara awọn eeyan to ṣe iṣẹ ibi naa, sugbọn wọn ṣi n wa ẹnikan to ku ati ẹni to fẹ ẹ bá wọn ṣe etutu.

Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed ti gbé miliọnu kan Naira silẹ fun itọju ọmọdebinrin naa, o si tun pasẹ fun awọn oṣiṣẹ alaabo lati se gbogbo nkan ti yoo mu ki ọwọ tẹ awọn meji to ku.

Bakan naa ni dokita nileewosan ti ọmọ naa ti n gba itọju sọ pe owo ti gomina gbé kalẹ ti tẹ àwọn lọwọ, ati pe ara rẹ ti n ya diẹdiẹ.

O ṣalaye pe awọn tun gbọ pe awọn eeyan kan n fi orukọ ọmọ naa tọrọ owo lori ayelujara. O ni ki awọn eeyan naa jawọ, nitori pe ijọba ti ṣèlérí lati san gbogbo owo itọju rẹ.