Insecurity in Nigeria: Soyinka ní Buhari kò le jókòó síle ìjọba láti dojú Boko Haram bolẹ̀

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
Gbajumọ onkọwe nni, Ọjọgbọn Wole Soyinka ti pe aarẹ Muhammadu Buhari nija lori eto aabo to mẹhẹ to n ba ilẹ Naijiria finra.
Ọjọgbọn Soyinka ni ala ti ko le sẹ ni fun ijọba Buhari, ti aarẹ ba joko fẹytinti nile ijọba Aso Rock, to si lero pe yoo ri ẹyin awọn agbesunmọmi ati atajẹsilẹ ni gbẹfẹ.
Soyinka woye ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto ori mohunmaworan kan nilu Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- August Agboola Brownie, ọmọ Yorùbá tí wọ́n n wárí fún ní Poland
- Sójà àti awakọ̀ fìjà pẹ́ẹ́ta nítorí ọgọ́rùn náírà, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sòfò
- Agbẹjọ́rò àgbà ní Nàìjíríà ti pàsẹ kí wọ́n dáwọ́ ètò ìgbanisíṣẹ́ NDLEA dúró
- Njẹ́ o mọ̀ pé àṣírí rẹ kò bò mọ́ lórí Whatsapp nítorí ìlànà tuntun tí wọ́n gbé síta?
- Nǹkán márùn ún tó yẹ ko mọ̀ nípa Elon Musk, bàbá olówó tó lówó jùlọ lágbàáyé
- Yollywood: Kìí ṣe gbogbo ìgbéyàwó ló ń túká nítorí àgbèrè – Mide Martins
Gbajugbaja onkọwe naa wa kede pe, agbajọ ọwọ lo yẹ ka fi ọrọ eto abbo to mẹhẹ naa se nitori ikọ fẹjẹwẹ Boko Haram, agbegbọn atawọn ọdaran miran ti gbakoso Naijiria.
Soyinka ni ipo ti Naijiria wa bayii ti de ipo koyemimọ, ti ijsba si gbọdọ setan lati sanwo fun awọn eeyan ti yoo ran wa lọwọ lati doju ija kọ awọn ọdaran ati ikọ afẹjẹwẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Professor Wole Soyinka's Admirers
"Awọn eeyan kan wa to yẹ ka di ẹbi ọrọ eto aabo to mẹhẹ le lori, lara wọn si ni asn asaaju orilẹede yii to ti tukọ Naijiria sẹyin, ti wọn ko tete riran pe ohun gbogbo le buru to bayii.
Inu mi si dun pe awọn ọlaju lapa oke ọya naa ti n sọrọ soke lori awọn isẹlẹ yii, ti wọn si ti n gbe awọn igbesẹ to yẹ ki wọn ti gbe ni aimọye ọdun sẹyin.
Koda, lara wọn gan jẹwọ fun mi pe awọn ti n sanwo aabo ẹmi fawọn apaayan lati jẹ ki wọn rile aye gbe.
Amọ Soyinka wa daba pe oun ko ba fara mọ ilana sise koriya fun araalu ninu eyi ti wọn yoo ti se idanilẹkọ fun wọn,.
O ni idanilẹkọ nipa ibọn lilo se koko, paapa fawọn agbẹ, ki wọn le fi ọwọ kan mu ọkọ to fi n ro oko ati ọwọ keji mu ibọn, ti yoo fi daabo bo ẹmi ati eto ikore rẹ.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ondo mú ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ tó gbé ọmọ ọ̀gá rẹ̀ àti káàdì ìgbowó ATM sálọ

Oríṣun àwòrán, unicef usa
Saaju la ti sọ fun yin pe, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti mu ọmọ ẹkọṣẹ ti wọn pe orukọ rẹ ni Temitope Adeniyi, to gbe ọmọ ọga rẹ ati kaadi igbowo ATM ọga rẹ sa lọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Tee-Leo Ikoro lo fidi ọrọ naa mulẹ fawọn akọroyin.
Iṣẹlẹ ọhun waye ni ṣọọbu telọ kan lagbegbe Oke-Bola niluu Ondo.
- "Ikọ́ lásán ló pa Orisabunmi"
- Orisabunmi ti jáde láyé, ohun tí a mọ̀ nípa ayé àti ikú rẹ̀ nìyí
- Wo ọ̀nà tí Yoruba ń gbà dá ọmọ àlè mọ̀ nínú ìdílé- Elebuibon
- ''Ewu ń bẹ pẹ̀lú coronavirus táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ba wọlé padà báyìí l'Eko''
- Ẹ̀gbọ́n baba Barakat ṣàlàyé bí ó ti gbé e lọ sílé kọmísọ́nà Ogun tí wọ́n ní kó lọ rọ́kún nílé
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tó gé ojú-ara ọmọdébìnrin ọdún mẹ́fà fún ètùtù ọlà
- Ìwúre ọdún tuntun rèé láti ẹnu Oluwo Jogbodo Orunmila
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe awọn ti gba ọmọ ti ọdọbinrin naa gbe sa lọ lọwọ rẹ.
Ọgbẹni Ikoro fiku ọrọ rẹ pe ko si ohun kan to ṣe ọmọ naa nigba tawọn gba a lọwọ rẹ.
Èèmọ̀ wọ̀lú, Ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ gbé ọmọ ọ̀gá rẹ̀ àti káàdì ìgbowó ATM sálọ l'Ondo!
Ọmọ ẹkọṣẹ telọ kan ti gbe ọmọ tuntun jojolo ọga rẹ salọ ni ilu Ondo pẹlu kaadi igbowo ATM rẹ.
Gẹgẹ bi iroyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo fi idi rẹ mulẹ fun BBC News Yoruba, ọkọ iya ọmọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Stella Babatunde lo mu arabinrin naa ti orukọ tirẹ n jẹ Temitọpẹ Adeniyi wa kọ iṣẹ lọdọ rẹ.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, iyawo ọrẹ rẹ ni ọkọ arabinrin yii pe Temitọpẹ ki o to di pe akara tu sepo.
- Òṣìṣẹ́ Amotekun kò mọ̀ọ́mọ̀ yìnbọn lu ọlọ́pàá l’Oyo, ìdí tó fi yìnbọn rèé -Olórí ikọ̀ Amotekun l’Oyo
- Ìpínlẹ̀ Eko yí ohùn padà, Ó kéde ọjọ́ tuntun fún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Wo ọ̀nà tí Yoruba ń gbà dá ọmọ àlè mọ̀ nínú ìdílé-Elebuibon
- Ọlọ́pàá Oyo n wa afurasí tó ṣekú pa oníṣòwò àti ọmọ ọdún mẹ́sán án méjì ní Ibarapa
Nigba ti ọrọ di ifanfa lẹyin to ji ọmọ ati kaadi igbowo ATM ọga rẹ gbe salọ tan ni ọrọ to han sita pe wọle-wọde ikọkọ n lọ laarin ọkọ Stella ati ọmọ ẹkọṣẹ rẹ naa, Temitọpe, ati pe ololufẹ rẹ ni.
Gẹgẹ bi ohun ti arabinrin Stella Babatunde sọ, ọkọ rẹ mu arabinrin naa wa kọṣẹ ni ọdọ rẹ ni ọjọ kẹta oṣu kejila ọdun 2020, ṣugbọn o ni oun maa n ṣakiyesi pe ibasọrọ ori foonu maa n waye laarin ọkọ oun ati arabinrin naa lasiko to ba wa ni ṣọbu ti oun ti n ṣe iṣẹ telọ oun.
Ni ọjọ keji oṣu kini ọdun 2021 yii ni arabinrin naa gbe ọmọ ọga rẹ pọn ti ọga rẹ si fun un ni kaadi igbowo ATM rẹ pe ki o ba oun gba ẹgbẹrun mẹta Naira ti ọkan lara awọn onibara rẹ fi ranṣẹ sii lori ẹrọ igbowo POS.
Amọṣa Stella Babatunde ni lilọ rẹ ni oun ri lati igba naa ati pe "Ko pada wale mọ lati igba naa o.''
Araabinrin naa ṣalaye siwaju sii pe ni kete ti oun ko ti kẹfin ọmọ ẹkọṣẹ rẹ naa mọ loun ti pe ọkọ oun to mu wa lati ṣalaye fun un ṣugbọn iha ko kan mi ni ọkọ naa n kọ si ọrọ naa, to bẹẹ gẹ to fi jẹ wi pe awọn ara adugbo gan fẹ pawọ pọ luu ni alubami nigba to de.
Amọṣa ni agọ ọlọpaa ni ọkọ arabinrin naa ti wa jẹwọ pe lootọ ere ifẹ n bẹ laarin oun ati ọmọ ẹkọṣẹ iyawo oun naa ṣugbọn oun ko mọ nipa ọmọ to gbe salọ.
Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Leo Ikoro fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, O si ṣalaye fun BBC News Yoruba pe iwadi ti nlọ lori rẹ ati pe ileeṣẹ ọlọpaa ti mu awọn afurasi kan lori rẹ.
















