How to get us number for whatsapp: Ìlànà tuntun Whatsapp yóò má a pín àkọsílẹ̀ nípa rẹ fún Facebook

Idanimọ Whatsapp

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Omi tuntun ti ru, ẹja tuntun ti wọ inu rẹ ni ọrọ da bayii fun awọn eyan to n lo oju opo ibaraẹnisọrọ Whatsapp, nitori ilana tuntun ti ileeṣẹ naa gbe sita.

Nkan akọkọ ni pe awọn to n lo Whatsapp ko lanfaanni lati sọ pe awọn ko faramọ, nitori pe ileeṣẹ naa sọ pe dandan ni fun ọ lati tẹwọgba awọn ilana ati ayipada tuntun naa, to o ba ṣi fẹ ẹ ma a lo Whatsapp.

Ọjọ kẹjọ, oṣu Keji, ọdun 2021 ni ilana tuntun naa, ati aṣiri bibo yoo bẹrẹ, ti o ko ba si tẹwọgba a o ko ni le lo Whatsapp mọ.

Ilana tuntun naa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Kini awọn ayipada pataki to waye?

Lori Whatsapp atijọ, ileeṣẹ naa kọ ẹjẹ pe bibọwọ fun aṣiri rẹ wa ninu ẹjẹ oun.

Ṣugbọn, ẹjẹ yii ko si ninu ilana tuntun, botilẹ jẹ pe ileeṣẹ naa sọ pe oun ṣi ni end-to-end encryption, eyi to tumọ si pe ko ni i pin awọn atẹjiṣẹ rẹ fun ẹni ti o ko fi ranṣẹ si.

Nkan miran tun ni pe tẹlẹ, o le yàn lati pin akọsilẹ nipa rẹ fun Facebook tabi bẹẹkọ, fun ọgbọn ọjọ akọkọ.

Amọ bayii, ko si anfaani naa mọ- nkan ti wọn yoo beere lọwọ rẹ ni pe ṣe o fẹ ẹ pa Whatsapp rẹ rẹ.

Awọn nkan miran to yẹ lati mọ

Ti o ba faramọ awọn ayipada naa, wo awọn akọsilẹ nipa rẹ ti Whatsapp yoo fun awọn ileeṣẹ mii bi Facebook:

  • Orukọ ati nọmba ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ
  • Awọn atẹjiṣẹ ti o n fi ranṣẹ, to fi mọ ti o ba duna-dura okoowo
  • Akọsilẹ nipa ẹrọ ibanisọrọ alagbeka rẹ
  • Ati adirẹsi ibi to ti n lo foonu ati ayelujara