Joseph Hanlon: Ogójì tọ́ọ́nù heroin ló ń gba Mozambique kọjá

Apo ogun oloro

Oríṣun àwòrán, iStock

Àkọlé àwòrán, Pupọ lara ogun oloro to n wọ ilẹ Europe n wa lati Mozambique.

Apo oogun oloro to to ogoji n gba orilẹede Mozambique ni ọdọọdun, Onimọ Joseph Hanlon lo sọ bẹẹ.

Iwadi ti Hanlon lati Mozambique se fihan wipe, orilẹede Mozambique ni orilẹede kẹta ni agbaye, ti wọn ti n gbe oogun oloro kuro lorilẹede naa lo si omiran pẹlu iranwo oju opo ikansiraẹni Whatsapp.

Hanlon ni awọn onifayawọ naa n gbe oogun oloro lati Afghanistan lọ si guusu-iwọ oorun Pakistan, lati ibẹ lọ si ariwa Mozambigue nibi ti wọn ti n gba ọna ẹburu gbe wọ ilẹ Europe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, #EkitiDecides: Fayose sùn lórí ibùsùn aláìsàn

Iwadii fihan wipe awọn to n se isẹ fayawọ naa maa n ko o pamọ si inu paali, ti wọn si n lo atẹjisẹ lori ẹrọ ikansiraẹni Whatsapp lati ba ara wọn sọrọ pẹlu orukọ bii 555, Tokapi ati Africa Demand.

Oko ogun oloro heroin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Orilẹede Afghanistan ni wọn ti n gbin ogun oloro, ti wọn a si gbe gba Mozambique lọ si Europe

Onimọ naa fi kun wipe, awọn onibara ma n ra oogun oloro heroin naa ni ọgọọrọ, ti wọn yoo si gbiyanju lati gba a ni orilẹede Mozambique, lẹyin ti wọn ba ti lo Whatsapp lati seto gbogbo nkan ti wọn nilo. Lẹyin naa ni won yoo pin heroin naa ka lo si Olu-ilu South Africa tii Johanesburg.