Ekiti decides: Oshiomole fẹ̀sùn kan Fayose

Alaga gbogbo-gboo fun ẹgbẹ oselu APC, Adam Oshiomole, ti fẹsun kan Gomina Ipinlẹ Ekiti, Ayọ̀délé Fayose pe, o n lo owo osu to yẹ ko san fun awọn osisẹ fun apo ara rẹ.
Oshiomọlẹ fi ẹsun naa kan Fayose ni ibi asekagba ipolongo idibo gomina fún Kayode Fayemi, tó n dije du ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Ekiti.

Aarẹ Muhammadu Buhari, Bola Tinubu ati awọn adari ẹgbẹ oselu APC pẹlu ọgọọrọ awọn ololufẹ wọn wa ni asekagba ipolongo idibo naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Amọ, iroyin ni wipe bi o tilẹ jẹ pe gomina Fayose kéde ìséde ni ìpínlẹ̀ Èkìtì, sugbọn awọn eniyan si jade lọ si ibi ipolongo idibo naa.









