Yollywood artists: Mide Martins ní Kìí ṣe gbogbo ìgbéyàwó ló ń túká nítorí àgbèrè

Mide Martins, Zlatan Ibile ati DJ Cuppy

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọpọlọpọ iṣẹlẹ lo waye ni agbo ere awọn oloṣere ni ọsẹ yii, to fi mọ gbajugbaja osere, Iyaafin Fọlakẹ Arẹmu ti ọpọlọpọ eeyan mọ si Oriṣabunmi to padanu ẹmi rẹ lẹyin aisan ranpẹ, ti aburo rẹ naa si tun dagbere fun aye laarin ọjọ meji.

Eyi ya awọn ololufẹ rẹ lẹnu pupọ nitori ko si ẹni to gburo aisan nipa rẹ, ki ọlọjọ to de.

Amọṣa ninu fidio kan to fi si ori ikanni ayelujara, Facebook, eekan apanilẹrin ati elere itage, Ọlanrewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijeṣa jẹ ko di mimọ pe "ikọ lasan" lo pa oloogbe Oriṣabunmi.

Laarin ọjọ meji ti iṣẹlẹ iku orisabunmi waye, ni a tun gbọ pe aburo rẹ̣ naa tun jẹ Olorun nipe.

Ki o to di oloogbe, oun ni adari ikọ agbabọọlu Kwara State Falcon Football club.

Mide Martins

Gbajugbaja oṣere Yoruba, Mide Martins ti gba awọn ololufẹ rẹ ni iyanju wi pe ọpọlọpọ nkan lo n ba igbeyawo jẹ yatọ si ki ọkọ abi iyawo ma a ṣe agbere.

Mide Martins lo sọ bẹẹ loju opo ikansiraẹni Instagram rẹ,nibi ti o ti n gba awọn ololufẹ rẹ ni iyanju lori igbeyawo ati awọn ohun to n fa idarudapọ ninu ile.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Mide ni igbeyawo mii n daru nitori ọkọ tabi aya ko koi bi ara si ekeji rẹ, ti ẹlomiran ko si mọ bi wọn ṣe n tọrọ idariji ẹsẹ lọwọ ọrẹkunrin ati ọrẹbinrin.

Mide Martins fikun wi pe awọn ohun to le gbe igbeyawo duro ni ki eniyan ni irẹlẹ ọkan ati imumọra loore-koore.

Bobrisky

Gbajugbaja ilumọọka to jẹ ọkunrin, amọ to n wọ asọ obinrin ti darukọ ''Honourable Deji'' lasiko ti o n kọ awọn obinrin ni ọna ati ma fi igbadun wọn han fun ọkunrin lasiko ibalopọ.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Eyi ti mu ki ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ma a bere nipa ẹni to n jẹ ''Honourable Deji'' lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter kaakiri.

DJ Cuppy ati Zlatan

Oju opo ikansiraẹni Twitter n gbona jainjain lowurọ Ọjọ Ẹti ni lẹyin ti gbajugbaja olorin ati ọmọ Femi Otedola, DJ Cuppy ke gbajare sita pe ọrẹ ati akẹgbẹ oun, ti awọn jọ kọ orin 'Gelato' ti gbegile oju opo ikansiraẹni Instagram ati Whatsapp rẹ fun osu mẹwaa bayii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

DJ Cuppy fikun wi pe oun ko mọ idi to fi gbe igbesẹ bẹẹ, ti kii si ṣe pe awọn ni ija ti tẹlẹ.

Vee - BB Naija

Arabinrin to kopa ninu idije BBNaija lockdown, Vee ti kesi awọn eniyan lati ṣe suuru nipa wiwa ọrọ ati owo ni aye ti a wayii.

Vee ni ti awọn ẹlomiran ba sọ bi awọn ṣe n ri owo awọn, awọn eniyan yoo ma ṣe suuru ni igba gbogbo.