Coronavirus: Ibidapo Obe, Femi Odekunle àti Duro Ajeyailemi wà lára àwọn tí Covid-19 pa

Ọjọgbọn

Ẹni to ba leti, ko gbọ ohun ti ẹmi n sọ fun ijọ ni ọrọ ọwọja arun Coronavirus to n gbalẹ kan bii ọwara ojo bayii.

Lati osu keji ọdun 2020 ti arun naa ti ran de orilẹede Naijiria, ọpọ ẹmi lo ti ba rin eyi ti ko yọ olowo abi talaka silẹ, koda ati ọkunrin ati obinrin ni arun naa n da ẹmi wọn legbodo.

Bakan naa, ọpọ awọn ilumọọka ọmọ ilẹ yii ni arun naa ti ran sọrun lairotẹlẹ, lara wọn si ni Abba Kyari, Abiola Ajimobi, Buruji Kashamu, Tunde Oshinowo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nibayii ti isi keji ọwọja arun naa tun n gbilẹ siwaju lọdun 2021, ọpọ ẹmi lo tun ti ba rin, to fi mọ awọn ọjọgbọn nile ẹkọ fasiti, marun lara wọn si ree.

Ọjọgbọn fasiti marun ti Coronavirus ti mu lọ:

Ọjọgbọn Olufemi Odekunle:

Femi Odekunle

Oríṣun àwòrán, @Presidency

Ọjọ Isẹgun, ọjọ Kọkandinlọgbọn osu Kejila ọdun 2020 ni Coronavirus mu ẹmi gbajumọ olukọ fasiti yii lọ lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin.

Ibudo iyasọtọ fun itọju awọn alarun Covid-19 to wa nilu Abuja ni Odekunle ju awa silẹ si, lasiko ijagudu pẹlu arun Coronavirus, eyi to mu ko maa gba ẹrọ to n fun ni ni afẹfẹ sara.

Onimọ to pegede nipa ihuwasi ọdaran ni Odekunle lorilẹede Naijiria, to sisẹ olukọ fun ọpọlọpọ ọdun ko to fẹyinti.

Titi to fi di ọjọ iku rẹ, Ọjọgbọn Olufẹmi Odekunle jẹ ọmọ igbimọ oludamọran fun aarẹ Buhari lori iwa ajẹbanu.

Ọjọgbọn Oye Ibidapo Obe:

Oye Ibidapo Obe

Oríṣun àwòrán, Unilag

Oye Ibidapo Obe jade laye lọjọ Kẹta osu Kinni ọdun 2021 lasiko to wọja ija pẹlu arun Coronavirus.

Obe, tii se ọmọ bibi ilu Ile Ifẹ ni baba isalẹ ati alaga igbimọ alakoso fun ileeẹkọ fasiti ẹkọsẹ ọwọ akọkọ ni Naijiria to wa nilu Ibadan, eyi to di mu titi di ọjọ iku rẹ.

Bakan naa ni oloogbe yii ti jẹ ọga agba fun fasiti Eko nigba kan ri, laarin ọdun 2000 si 2007, ko to fẹyin ti.

Ọdun mọkandinlaadọrin ni Ibidapo Obe, tii se onimọ nipa imọ ẹrọ, lo loke eepẹ, ko to dagbere faye.

Iroyin kan ti wọn n pin kiri lori ayelujara ni ko pẹ ti Obe de lati ibi ayẹyẹ kan lo wolẹ aisan, to si n fi ami arun Coronavirus han, ki wsn to gbe lọ sile iwosan.

Amọ aisan lo se wo, ko si ẹni to ri ti ọlọjọ se.

Ọjọgbọn Duro Ajeyailemi:

Duro Ajeyailemi

Oríṣun àwòrán, Unilag

Duro Ayeyailemi ni oludari agba tẹlẹ fun ẹka imọ ẹkọ ni fasiti Eko.

Lẹyin ọjọ kẹta ti wọn kede iku Ọjọgbọn Ibidapo Obe, naa ni wọn kede iku Ajeyailemi pe arun Coronavirus lo da ẹmi rẹ legbodo laipe ọjọ.

Iroyin kan ni ayẹyẹ kan naa ni oloogbe yii ati Ibidapo Obe dijọ lọ, to si see se pe ibẹ ni wọn ti ko arun Coronavirus to n pa ọpọ eeyan.

Ibudo iyasọtọ fun itọju awọn alarun Coronavirus fun fasiti Luth ni Idi Araba nilu Eko, ni ọjọgbọn naa ku si .

Ẹni aadọrin ọdun ni ọjọgbọn Ajeyailemi ko to dagbere faye, to si kaye nilẹ Naijiria ati loke okun.

Àkọlé fídíò, Oluwo Jogbodo Orunmila: Ẹsẹ odù Ifa ló fi ṣúre fún ọmọ Nàíjíríà ní àyájọ́ ọdún tuntun

Awọn ọjọgbọn mẹta miran la tun gbọ pe wọn jade laye amọ ti a ko le fi idi ootọ ọrọ nipa iku wọn mulẹ.

Ọjọgbọn Kayode Adesogan, Ọjọgbọn obinrin abiona ati Ọjọgbọn Folabi Olumide.

Awọn iroyin kan ti ko fẹsẹ mulẹ salaye pe arun Coronavirus lo mu ẹmi awọn ọjọgbọn mẹtẹẹta ọhun lọ.

A wa n gbadura pe ki Ọba oke tẹ awọn alaisi yii si afẹfẹ rere.

''Atiku gba abẹ́rẹ́ ajẹsára coronavirus ní Dubai láti jẹ́ àwókọ́ṣe fọ́mọ Nàìjíríà''

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Abdulrasheed Uba Sharada

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Atiku Abubakar ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti ileeṣẹ apoogun Pfizer ṣe.

Niluu Dubai ni orilẹede United Arab Emirates ni Alhaji Abubakar ti gba abẹrẹ ọhun.

Oluranlọwọ Atiku lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Paul Ibe lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC.

Agbẹnusọ fun Atiku ṣalaye pe oludije ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP gba abẹrẹ ọhun lati jẹ awokọṣe fawọn ọmọ Naijiria.

O ni ohun ti Atiku n sọ fawọn ọmọ Naijiria ni pe ki wọn tu jade ló gba abẹrẹ naa ti ijọba ba ti pese abẹrẹ naa ni Naijiria.

Ọwọja ẹlẹẹkeji arun coronavirus naa n le si lẹnu ọjọ mẹta yii papaa julọ nipinlẹ Eko.