Osun Kidnap: Àwọn agbébọn ti jí àwọn arìnrìnàjò gbé ní ìpínlẹ̀ Osun

Agbebon

Oríṣun àwòrán, others

Ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Osun ti ke gbajare pe awọn agbegbọn ti ji awọn arinrinajo gbe ni agbegbe Omoh / Erin-Ijesha, ni ijọba ibilẹ Ori-Ade nipinlẹ Osun.

Iwadii fihan pe awọn agbebọn naa ṣe ikọlu si awọn arinrinajo naa, ti wọn si ko wọn lọ si inu igbo to wa ni ayika Ori-Oke Omoh naa.

Amọ wọn ni wọn fi awọn arinrinajo miran silẹ si oju titi ọhun.

Adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Osun, Bashir Adewinbi fi idi ọrọ naa mulẹ, amọ o ni awọn ko lee sọ iye awọn arinrinajo ti wọn jigbe ni pato.

Amọ ikọ Amọtẹkun fikun wi pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati sawari awọn ti wọn jigbe naa.

''Awọn meji ni wọn jigbe ni Ọjọ Isinmi, ti a si ti ran awọn eniyan wa lọ sibẹ lati doola ẹmi wọn.''

Bakan naa ni ikọ ọlọpaa si ti bẹrẹ si ni wa awọn ajinigbe naa, ti iwadii si ti bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Wọn fikun wi pe agbegbe ti wọn ti ji awọn eniyan gbe yii n fun wọn ni ọpọlọpọ ipaya ati ifoya lati bi igba diẹ sẹyin.

Laipẹ yii ni eekan ni ilẹ Yoruba, Sunday Igboho fun awọn Fulani darandaran ni gbedeke ọjọ mẹwaa lati kuro ni agbegbe Ibarapa ni ipinlẹ Oyo nitori ijinigbe to n waye nibẹ lojoojumọ.

Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu naa paṣẹ ki awọn darandaran kuro ni igbo ijọba ti awọn ajinigbe n lọ lati ṣọṣẹ.

Àkọlé fídíò, BBC findings on lekki shooting: Ẹ wa wo àwọn tó ṣì ń wá ẹbí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ End SARS 2020