Ekiti budget: N1.4bn ni ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti yòó ná lórí Amotekun lọ́dún 2021

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kayode Fayemi
Biliọnu kan ati irinwo miliọnu (N1.4bn) ni ipinlẹ Ekiti yoo na lori ẹṣọ eleto abo Amotekun lọdun 2021.
Kọmiṣọnna eto iṣuna fun ipinlẹ naa, Ọgbẹni Femi Ajayi lo fọrọ yii lede nigba to n ṣe atupalẹ eto iṣuna N109.666bn fun ipinlẹ Ekiti lọdun 2021.
Kọmiṣọnna ṣalaye pe owo ti ijọba ya sọtọ lati na lori Amotekun ṣe pataki nitori bi eto abo ti mẹhẹ kaakiri orilẹede Naijiria bayii.
- Sunday Igboho fún Fulani Oyo ní gbèǹdéke, Seriki fulani yarí, ọlọ́pàá dá síi...
- Àbámọ̀ ni yóò gbẹ̀yin ẹgbẹ́ ''Association of Stingy Men'' tí kò fẹ́ náwó f'óbìnrin- Akeugbagold
- Èèyàn 1444 ló tún kó coronavirus lórílẹ́èdè Nàijíríà lọ́jọ́ Àìkú
- Wo ìdí tí Oluwo fi ń wọ ìbòmú lẹ́yìn tó ní covid-19 ò lè wọ ìlú Iwo láéláé
- Covid-19: Ilé aṣojú-ṣòfin l'Abuja dábàá kí ìjọba sún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ síwájú pẹ̀lú oṣù mẹ́ta
O ni iṣẹlẹ ijinigbe, aawọ laarin awọn agbẹ atawọn darandaran n pọ si lojoojumọ ni Naijiria.
Kọmiṣọnna eto iṣuna ṣalaye pe ojuṣe ijọba ni lati daabo bo awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ati dukia wọn, ''ohun lo jẹ ki Gomina Kayode Fayemi da ẹṣọ eleto abo Amotekun silẹ.
Ọgbẹni Ajayi sọ pe N550m ni ijọba ya sọtọ fun rira ẹrọ kamẹra ''drone'' ti wọn fi maa ṣe iwadii awọn ọdaran lati mọ ibi ti wọn wa.
Kọmiṣọnna eto iṣuna tun ṣalaye pe N2.4bn ni ijọba ya sọtọ lati bẹrẹ fasiti ẹkọ imọ ẹrọ Bamidele Olumilua nipinlẹ naa.
Bakan naa ni Ọgbẹni Ajayi sọ pe biliọnu mẹjọ ni ipinlẹ Ekiti yoo na lori eto ẹkọ, eto ilera ati awọn eto ṣiṣe iranwọ fawọn eeyan ipinlẹ ọhun.
Kọmiṣọnna ni eto iṣuna ọdun 2021 da lori imupada sipo ọrọ aje ipinlẹ Ekiti lẹyin ti arun covid-19 ti ṣakoba fun ọrọ fun ọrọ aje Naijiria.
Ọgbẹni Ajayi ni ijọba ṣetan lati rii pe gbogbo iṣẹ to ya owo sọtọ fun lati ṣe lo di ṣiṣe lọdun 2021.


















