School resumption: Ìjọba Eko ní òun kò s'éwu lórí covid-19 pẹ̀lú ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Twitter/Lagos Ministry of Education

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lonii ọjọ kejilelogun oṣu kinni ọdun 2021 yii lawọn akẹkọọ pada sile iwe ni Naijiria fun saa igbẹkọ tuntun, bo tilẹ jẹ pe covid-19 n pọ sii lojoojumọ.

Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ eeyan pe awọn akẹkọọ wọlẹ pada sile iwe nipinlẹ Eko to jẹ wi pe nibẹ lawọn eeyan ti ko arun coronavirus julọ ni Naijiria.

Ati wi pe ijọba ipinlẹ Eko paṣẹ fawọn oṣiṣẹ ìjọba ti wọn ko to ipele Kẹrinla lati tubọ maa ṣiṣẹ lati ile wọn lọnà ati dẹkùn itankalẹ aarun Covid-19.

Ṣugbọn kọmiṣọnna eto iroyin ati ọgbọn inu ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbenga Omotoso ṣalaye lẹkunrẹrẹ idi ti ipinlẹ Eko fi gba ki awọn akẹkọọ wọle pada lọjọ Aje.

Lakọkọ, Ọgbẹni Omotoso ni ijọba apapọ lo paṣẹ pe ki awọn akẹkọọ pada sile iwe fun saa eto igbẹkọ tuntun.

Bakan naa ni kọmiṣọnna sọ pe awọn akọṣẹ-mọṣẹ nipa eto ilera lo ni ko si ewu pe awọn akẹkọọ le wọle.

''Ti awọn akọṣẹ-mọṣẹ ba sọ pe ewu wa nibi ṣiṣi ileewe pada, ijọba ko ni ṣi ileewe pada,'' Omotoso lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Itaniji: Oluwo sọ ìtàn bí Orunmila ṣe jìyà nílùú Iwo àti ayọ̀ tó gbẹ̀yìn rẹ̀ torí sùúrù

Omotoso ni oun ti n kaakiri awọn ileewe nipinlẹ Eko, oun si rii pe awọn ileewe n tẹle awọn ilana lati dẹna ajakalẹ arun coronavirus.

Kọmiṣọnna ni awọn olukọ atawọn akẹkọọ lo n lo ibomu, bẹẹ ni wọn n fi omi fọwọ, koda wọn n takete si ara wọn gẹgẹ bi ajọ NCDC to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria ṣe laa kalẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O ni ọrọ awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn ko tii pada si ẹnu iṣẹ yatọ si ọrọ iwọle awọn akẹkọọ.

Ọgbẹni Omotoso ni ijọba ipinlẹ Eko tun n pin ibomu fawọn ti ko ni lawọn ileewe.

Àkọlé fídíò, Ado Ekiti Blind Couple: Tọkọ-taya Oke ní Ọ́ba òkè ló fi àwọn dá àrà tó wù ú

Kọmiṣọnna eto iroyin ati ọgbọn inu sọ pe ijọba ko fi ẹmi awọn akẹkọọ wewu nipa wiwọle pada wọn.

O ni imọran awọn akọṣẹ-mọṣẹ ni ijọba ipinlẹ Eko n tẹle lori ọrọ ati wọle pada awọn akẹkọọ ati ajakalẹ arun coronavirus.