Abeokuta Petrol tanker fire: Gomina Dapo Abiodun gbégilé ọkọ̀ agbépo lórí afárá ní ìpínlẹ̀ Ogun

Abeokuta

Oríṣun àwòrán, Twitter/Dapo Abiodun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti paṣẹ ki ọkọ agbepo kankan ma gun ori afara mọ nipinlẹ naa.

Eyi ko ṣẹyin ọkọ agbepo to gbina ni ilu Abeokuta, ti ẹmi eniyan mẹfa si lọ si iṣẹlẹ naa pẹlu ọpọlọpọ ọkọ to jona raurau.

Gomina Abiodun lori Twitter rẹ ba awọn ẹbi ati ara to faragba ninu iṣẹlẹ naa kẹdun.

Abeokuta

Oríṣun àwòrán, Twitter/Dapo Abiodun

Bakan naa ni o fikun wi pe awọn ti ranṣẹ si awọn to dokita to mọ nipa itọju awọn ti ina ba jo lati wa ranwọlọwọ pẹlu itọju awọn to farapa ninu ijamba ọkọ naa.

Abeokuta

Oríṣun àwòrán, Twitter/Dapo Abiodun

Tirela naa lo ṣubu lẹyin to ti kọkọ kọlu ọkọ Jeep Lexus kan ko to gbina.

Abeokuta

Oríṣun àwòrán, Twitter/Dapo Abiodun

Wọn ti ra rọ awọn awakọ pe ki wọn gba ọna miiran yatọ si opopona Kuto Road ati banki GTB.

Abeokuta

Oríṣun àwòrán, Twitter/ Dapo Abiodun

Niṣe ni ero lọ biba nibi ti ọkọ agbepo naa ti n jona ti wọn si n ṣe idiwọ fawọn oṣiṣẹ panapana.

Tírélà agbépo bẹntírò gbiná nílùú Abeokuta, ọkọ̀ mérin jóná ráúráú

Ọkọ tirela agbepo bẹntiro kan ti gbana lopopona Kuto Road si Okemosan niluu Abeokuta nipinlẹ Ogun.

Ọkọ tanka agbepo n jona

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ogun State Government

Ọpọ eeyan nin a gbọ pe o farapa nibi iṣẹlẹ naa.

Awọn panapana si n ja fita fita lati pa ina ọhun.

Tirela naa ṣubu lẹyin to ti kọkọ kọlu ọkọ Jeep Lexus kan ko to gbina.

Okere tan ọkọ mẹrin ni a gbọ pe o jona raurau nibi iṣẹlẹ naa ti awọn to wa ninu rẹ si sa asala fun ẹmi wọ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Alagba Ajibola láti Fakunle ní olùkọ́ wa lórí ètò ìró lónìí

Wọn ti ra rọ awọn awakọ pe ki wọn gba ọna miiran yatọ si opopona Kuto Road ati banki GTB.

Niṣe ni ero lọ biba nibi ti tanka naa ti n jona ti wọn si n ṣe idiwọ fawọn oṣiṣẹ panapana.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ẹbẹ lawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana n bẹ awọn ero wi pe ki wọn sun sẹyin ki awọn le ri ina ọhun pa.

Àkọlé fídíò, BBC findings on lekki shooting: Ẹ wa wo àwọn tó ṣì ń wá ẹbí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ End SARS 2020