Arsenal vs Newcastle: Ọba àwọn góòlù! Aubameyang àti Saka ṣá Newcastle pa lálẹ́ ọjọ́ Ajé

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal rọ bajinatu fun Newcastle ni papa iṣere Emirates lalẹ ọjọ Aje ninu idije Premier League.
Balogun ikọ Arsenal, Pierre-Emerick Aubameyang gba goolu meji sawọn nigba ti Bukayo Saka naa gba goolu kan si awọn lẹyin Arsenal lu Newcastle pẹlu ayo mẹta sodo.
Aubameyang lo kọkọ gbayo sawọn ni iṣẹju marun un lẹyin ti ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ.
- Seyi Makinde pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá láti wádìí Sunday Igboho lórí gbèǹdéke tó fún àwọn Fulani
- Ẹ wo ohun tí Seriki Fulani sọ fún gómìnà Makinde nípa Sunday Igboho
- Àwọn agbébọn ti jí àwọn arìnrìnàjò gbé ní ìpínlẹ̀ Osun!
- Iyaafin Fọlakẹ Arẹmu, Orisabunmi ti wọ káà ílẹ̀ sún
- Coronavirus tún ṣekúpa èèyàn mẹ́rìnlá lọ́jọ́ Ajé, ẹni 1,617 míì tún kó
Saka gba goolu keji sawọn nigba ti ere bọọlu naa pe ọgọta iṣẹju ọgọta.
Aubameyang fi ọba lee nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ku iṣẹju mẹtala ti yoo pari.
Nibayii, Arsenal ti goke lọ si ipo kẹwaa lori tabili idjije Premier League.
Akọnimọọgba Arsenal, Mikel Arteta ko ṣai fi idunnu rẹ han si Aubameyang to gba goolu meji sawọn lẹyin to n tiraka lati fakọyọ lawọn ifẹsẹwọnsẹ ti Arsenal ti sẹyin.
Bakan naa lo gboṣuba fawọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu bii Bukayo Saka ati Emile Smith-Rowe ti wọn fakọyọ bakan naa.












