Wo nkan tó mú òṣìṣẹ́ akólẹ̀-kódọ̀tí fún LAWMA kàgbákò ikú l'ẹ́nu iṣẹ́ nípìnlẹ̀ Eko

Awọn oṣiṣẹ ajọ LAWMA lẹnu iṣẹ

Oríṣun àwòrán, Twitter/@lawma_gov

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ to n kolẹ-ko idọti nipinlẹ eko, LAWMA, Ọgbẹni Nasiru Saheed ti jade laye lẹyin to kagbako iku ojiji lẹnu iṣẹ lọjọ Satide.

Iroyin sọ pe Saheed jabọ lori ẹrọ to fi n ṣiṣẹ ni opopona Alexander, Ikoyi, nipinlẹ naa. Oju ẹsẹ lo ku.

Fidio kan to n lọ lori ayelujara ṣafihan Saheed ninu agbara ẹjẹ rẹ.

Ajọ LAWMA sọ ninu atẹjade to fi sita loju opo ayelujara Twitter rẹ lori iṣẹlẹ naa pe "pẹlu abamọ ni ajọ LAWMA fi kede iku ọkan lara awọn to n ba ko idọti to waye lasiko ijamba lowurọ ọjọ Satide".

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

"Awọn alaṣẹ ti n sọrọ pọ pẹlu ẹbi rẹ, ao si duro ti wọn ni asiko adanu yii."

LAWMA fikun ọrọ rẹ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ oun ni ipele gbogbo lo ni eto adojutofo. Ati pe oun yoo lo eto adojutofo naa lati mu adinku ba inira ti iku Ọgbẹni Saheed le mu ba ẹbi rẹ.

Okùnrin kan gbẹ́mi mì lẹ́yìn tó dákú nídìí ọkọ̀ rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko

ọkọ

Oríṣun àwòrán, Lasema

Awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, ti gbe oku okunrin kan lọ ile igbokupamọsi lẹyin to daku rangbandan nidi ọkọ rẹ lopona CMD, ni Magodo.

Ninu atẹjade kan ti ọga agba LASEMA, Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu fi ṣọwọ si BBC Yoruba, o ni wọn ri okunrin naa leyin ti awọn gba ipe pajawiri.

O ni "awọn oṣiṣẹ ẹka LASEMA to n ri si eto ilera gba ipe pajawiri nipa okunrin kan, lẹyin ti wọn de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, wọn ri awakọ kan nidi ọkọ rẹ ti ko si emi lẹnu rẹ."

"Lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo finifini ni wọ ri pe o ti gbẹmi mi."

Atẹjade naa sọ pe awọn ẹbi oloogbe ọhun ti gba lati gbe lọ ile igbokusi to wa nitosi.

O fi kun pe yatọ si awọn si awọn oṣiṣẹ eto ilera, ọrọ naa ṣoju awọn ọlọpaa, wọn si ti gbe ọkọ ologbe ọhun kuro nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ.

Titi di igba ti a fi n kọ iroyin yii, ko si eni to tii le sọ ohun to ṣokunfa iku okunrin naa.

Ijinigbe

Oríṣun àwòrán, Google

Ọmọ ogún odún jí bàbá ara rẹ̀ gbé, ó gba ₦2m owó ìtúsílẹ̀

Okunrin ẹni ogun ọdun kan, Abubajar Amodu, ti jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe oun wa lara awọn to ji baba oun gbe, ti wọn si gba miliọnu meji naira owo itusilẹ lọwọ rẹ.

Amodu lo sọ ọrọ naa nibi ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba, ti fi oju awọn afurasi kan lede fun awọn akọroyin niluu Abuja.

Afurasi naa sọ pe "ọrẹ ni emi atawọn ajijigbe naa, wọn sọ fun mi pe olowo ni baba mi ati pe a le ti ara rẹ ri obitibiti owo, ni a ṣe ji gbe."

"Lẹyin ti a ji baba mi gbe tan, o fun wa miliọnu meji naira, iye to kan mi lara owo naa ni ẹgbẹrun lọna igba naira."

Ẹwẹ, awọn ọlọpaa naa tun fi oju afurasi miran lede ti wọn fẹsun kan pe o n pe ara rẹ ni ọlọpaa ati oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, EFCC."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Wọn ni Mohammed Abdulrahman maa n da awọ eeyan lọna lagbegbe Mabushi, ti yoo si ma a pe ara rẹ ni oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa, eyii ti wọn ni o n tabuku orukọ ileeṣẹ naa.

Lara awọn ohun ti wọn ri gba lọwọ awọn afurasi naa ni ada ati ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry.