Sexual assaul Katsina: Èèyan gidi ni ọ̀rẹ́ mi, èṣù ló mú kó fún ọmọ ọdún mẹ́jìlá lóyún - Ọ̀rẹ́ afurasí

Oloyun

Oríṣun àwòrán, Google

Igbakeji ọga ile iwe girama kan ti dero agọ ọlọpaa lẹyin ti wọn feṣun kan pe o ba akẹkọọ kan to jẹ ọmọ ọdun mejila lajọṣepọ.

Jamilu Shuaibu to jẹ ọrẹ Ibrahim Tukur, to jẹ igbakeji adari ile iwe girama Kadandani ti awọn ọlọpaa fẹsun ọhun kan ti sọ pe eeyan daadaa ni Ibrahim ọrẹ oun.

Awọn ọlọpaa fẹsun kan Ibrahim Tukur to jẹ igbakeji ọga agba ile iwe naa to wa ni ijọba ibile Rimi, nipinlẹ Katsina pe o fi ipa ba akẹkọọ ọhun to jẹ ẹni ọdun mejila lopọ, to si tun fun loyun.

Nigba to n ba BBC sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Jamilu ni o ti le lọdun mẹwaa ti ibadọrẹ oun ati afurasi naa ti n bọ, eeyan gidi si ni, ṣugbọn ẹmi eṣu lo jẹ ko fun ọmọ naa loyun.

O sọ pe "ọdun mẹwaa ree ti a ti n ba ọrẹ wa bọ, o si damiloju pe eeyan gidi ni ọrẹ mi ṣugbọn mo gbagbọ pe ẹṣu lo ti i to fi ba ọmọ naa laṣepọ."

"Iyawo mẹta lo ni, o si ni awọn ọmọ pẹlu, nitori naa kii ṣe iru eeyan bẹẹ, iṣẹ eṣu ni."

Jamuli ṣalaye pe oun ko fi igba kan ri ọmọ ọdun mejila naa pẹlu afurasi ọhun ri, ati pe ko sọrọ ọmọ naa leti oun ri.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina ti fi oju afurasi ọhun lede lẹyin ti wọn fi ṣikun ofin mu tan, wọn sọ pe ọwọ tẹẹ lẹyin ti arakunrin kan, Ibrahim Sale ta ileeṣẹ wọn lolobo.

Awọn ọlọpaa sọ pe afurasi naa ti jẹwọ pe lootọ ni oun n ba ọmọ ọdun mejila naa lajọṣepọ, ati pe ibaṣepọ wọn bẹrẹ ni nnkan bii oṣu mẹjọ sẹyin.

O fi kun oun maa n fun ni igba naira si ọọdunrun naira ni gbogbo igba ti wọn ba ti ṣere ifẹ tan.

Awọn ọlọpaa ni afurasi naa yoo foju bale ẹjọ laipẹ.