Stolen watch: Ilé ẹjọ́ gba béèlì, John Okonkwo ọkùnrin kan tó jí aago ọwọ́ tí iye rẹ̀ tó ₦33.8 mílíọ̀nù l'Eko

Ile ejo

Oríṣun àwòrán, others

Ọkùnrin ẹni ọdun mejidinlogoji kan ti foju bale ẹjọ majisreeti to wa ni Yaba, nílùú Eko, lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o ji aago ọwọ ti iye owo rẹ le ni mílíọ̀nù mẹtalelọgbọn.

Wọn fi ẹsun mẹta kan John Okonkwo pe o ditẹ, o wọ dukia ẹlomiran lai tọrọ aye, pẹlu ero lati jale.

Ṣugbọn Okonkwo ti sọ pé òun kò jẹbi ẹsun náà.

Agbofinro to gbe afurasi ọhun lọ ile ẹjọ, DSP Roman Unuigbe sọ fún ile ẹjọ náà pé Okonkwo ṣe iṣẹ ibi naa lọlọ kejilelogun, oṣu Karun ùn, ọdun 2020, ni ọja Trade Fair to wa ni ilu Eko.

O ni afurasi naa fọ ṣọọbu Chidi Dimugonabo, o sí ji pálí aago ọwọ ti iye rẹ jẹ N33.8 mílíọ̀nù.

Unuigbe sọ pé iwa ti afurasi naa wù lòdì sí òfin ipinlẹ Eko, eyii to tako iwa òdaran ti wọn gbé kalẹ lọdun 2015.

O sàlàyé fún ile ẹjọ ọhun pe ìjìyà ohun ti Okonkwo ṣe ni ẹwọn ọdun meji, ati ọdún méje gẹgẹ bí òfin ipinlẹ naa ṣe sọ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Adajọ Adeola Adedayo gba beeli afurasi naa pẹlu mílíọ̀nù méjì naira ati oniduuro to dantọ.

Lẹyìn náà ló sún ẹjọ ọhun sí ọjọ keji, oṣù Kejì, ọdún 2021.