Iskilu Wakili: Baálẹ̀ Itamofin Ayete ní Wakili sọ pé Ọlọrun ló ni ilẹ̀ nígbà ti òun le kúrò lágbègbè náà

Oríṣun àwòrán, @SaharaReporters
Baalẹ ilu Itamofin Ayete, nipinlẹ Oyo, Oloye Saubana Oyewole ti sọ iriri rẹ fun awọn akọroyin lasiko itakurọsọ nipa Iskilu Wakili.
Ti ẹ ko ba gbegbe, ọsẹ to kọja ni awọn ọmọ ikọ OPC fi ṣinkun ofin mu Wakili lẹyin ti wọn fẹsun kan pe oun ni baba isalẹ awọn ajinigbe lagbegbe Igangan, ti wọn si fa le awọn agbofinro lọwọ.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, Oyewole sọ pe ibẹru Wakilki ti mu ki ọpọlọpọ awọn olugbe ilu oun fi ilu naa silẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mò ń lọ ibùdó tí Fulani ti ń wa kùsà ní Idere, màá lé wọn dànù pátápátá - Sunday Igboho
- Àwọn agbébọn láti Òkè Ọya ń wa góòlù ní Ilesa, Owo àti Igangan láì sí ìdíwọ́ - Gani Adams
- Oloolu lọ ṣètùtù kí òjò rọ̀ n‘Ibadan, áwọn jàǹdùkú kọ lù ú, ọ̀pọ̀ ṣèṣe, ẹ̀mí sì bọ́
- Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá làwọn ọkùnrin ti ń fipá bá mi lòpọ̀ nígbà márùn-ún - Iyabo Ojo
- Ẹ fi ilẹ̀ tí a kò lò hááyà fáwọn darandaran bíi ibùdó ọ̀sìn màálù - Tinubu
- Ondo ló lékè nínú ìpínlẹ̀ tó lùgbàdì àrùn Coronavirus júlọ ní Ọjọ́ Àbámẹ́ta
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá tún wa sílẹ̀, àwọn àjínigbe yìí le ṣe ohunkóhun fún wa
O ni "ibẹru Wakili ti mu ki awọn eeyan mi fi awọn abule wọn silẹ, wọn si ti ko ẹru wọn lọ si awọn ilu nla to wa ni itosi, mi o da wọn lẹbi nitori ko si igba ti awọn ọmọlẹyin Wakili kii ṣakọlu si wa."
Nigba ti Oyewole n ṣalaye bi Wakili ṣe di araba si ilu Kajola, o ni nnkan bii ọdun mejidinlogun ṣeyin ni ọkunrin naa gunlẹ sagbegbe ọhun, ti ẹnikẹni ko si mọ ibi to ti wa.
O ṣalaye pe "lẹyin ti mo gbọ nipa rẹ ni mo ke si lati wa sọ bo ṣe jẹ, ti mo si beere ẹni to fun ni aṣẹ lati tẹdo si Kajola to jẹ ọkan lara ilẹ ti mo n ṣakoso le lori."
"Idahun to fun mi ni pe, Ọlọrun lo ni gbogbo ilẹ to wa nile aye, mo si fesi pe lootọ ti Oluwa ni ilẹ, ṣugbọn o ti fi awọn ilẹ naa si abẹ iṣakoso mi."
Oyewole sọ siwaju si pe, lẹyin ọdun diẹ si akoko naa ni oun bẹrẹ si n gbọ nipa oriṣiriṣi awọn iwa ipa to n wu atawọn ẹsun ti wọn fi n kan an."
Baalẹ naa ni gbogbo igbiyanju oun lati le Wakili kuro lori ilẹ oun lo ja si pabo, koda, o ni oun gbiyanju lati gbe lọ sile ẹjọ.
O ni "mo kọwe lọ siwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo ni nnkan bii ọdun mẹrin ṣẹyin, ṣugbọn nigba ti ẹjọ naa de saa kan ni adajọ sọ pe ki a lọ yanju ọrọ naa laarin ara wa."
"Mo gba si adajọ lẹnu, mo pe agbẹjọro mi ati agbẹjọro rẹ a si fẹnuko lati fun ni ilẹ miran ṣugbọn o kọ lati lọ si ibi ti a fun."
Oyewole pari ọrọ rẹ pe, ki ijọba apapọ wa ojutu si ọrọ awọn darandaran, ati pe o yẹ ko fofin de bi awọn Fulani ṣe maa n da maalu laarin ilu.





















