Iskilu Wakili arrested: Ṣé èèyàn máa ń gba ìran ẹ̀ sílẹ̀ kó di ogun ní? - Oyo OPC

Àkọlé fídíò, Bí ìjọba, ọlọ́pàá, ológun, Amotekun ò bá le gbà wá, àwa mú Wakili láti gba ìran Yorùbá sílẹ̀ ni - OPC

Adari ẹgbẹ Oodua Progressive Congress ni ipinlẹ Oyo labẹ isakoso Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba Iba Gani Adams, Comrade Rotimi Olumo ba BBC Yoruba sọrọ nilu Ibadan lati fesi si bi wọn ṣe fi panpẹ ofin ko awọn ọmọ ẹgbẹ wọn si atimọle torii pe wọn mu ogbontarigi Fulani to jẹ afurasi apaayan, Iskilu Wakili.

Rotimi ni ajoji nikan lo lee ma mọ ipenija aisi aabo to n doju kọ ẹkun Guusu Ila Oorun Naijiria.

O ni ogun ni nkan to n ja awọn ilu Ibarapa mejeeje toripe iṣoro ti wọn doju kọ yatọ si ohun ti awọn ilu igboro n dojukọ.

"Bi ijọba o ba le gba wa, ti ọlọpaa o le mu u, awọn Amotekun lọ ibẹ wọn o ri Wakili mu..."

Rotimi ni awọn ọdọ ilu wa pawọpọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu OPC lati wọ inu igbo naa lati le Wakili kuro ti wọn si ri i mu amọ o ni "o ba ni lọkan jẹ pe ọlọpaa tun wa n mu awọn ọmọ wa".

Rotimi ni oun soju gbogbo ọmọ Yoruba lati sọ fun ijọba pe ki wọn tu awọn ọmọ OPC to ṣe akitiyan lati gba iran wọn silẹ ki wọn maa lọ ile wọn.