SERAP: À fẹ́ kílé ẹjọ́ pàṣẹ fún Buhari láti máṣe yá owó aráàlú tó wà ní báǹkì

Muhammadu Buhari ati owo Naira

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Ajọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan nidi ọrọ aje ati ijiyin isẹ iriju ẹni, SERAP, tun ti wọ aarẹ Muhammadu Buhari lọ sile ẹjọ giga tijọba apapọ to wa nilu Abuja.

Igbesẹ naa ni Serap ni oun fẹ fi da ijọba lọwọkọ lati mase ya owo ninu apo asunwọn awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko lo fun igba pipẹ, lawọn banki gbogbo nilẹ wa.

Owo naa, ti wọn lo to biliọnu lọna marundinlẹẹdẹgbẹwa (N895m) , tun wa lara awọn owo ipin idokowo tawọn araalu ko beere fun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajọ Serap ni igbesẹ ijọba naa lodi sofin to si tun tako ofin to wa fun eto isuna ọdun 2020.

Ajọ Serap wa n rọ ileeẹjọ naa lati pasẹ pe ijọba ati aarẹ Buhari ko gbọdọ gba awọn owo naa tabi ya ninu rẹ, ko si tun gbọdọ tọwọ bọ owo awọn ọmọ Naijiria naa tabi gbe kuro ninu apo asuwọn owo ti wọn ko pamọ si.

Àkọlé fídíò, Adebunmi Adeyeye: Mo jẹ gbèsè gbọ́múléláńtà, ìdí iṣẹ́ kabúkabú ni mo ti ri san

Ajọ ajafẹtọ ẹni naa ni bi o tilẹ jẹ pe ọrọ aje Naijiria n saisan lojoojumọ, ti adinku si n ba owo to n wọle fun lojoojumọ, sibẹ awọn adari wa labẹ ijọba apapọ ati lawọn ipinlẹ to fi mọ awọn asofin ko mu adinku ba ilana bi wọn se n nawo.

O ni awọn ọmọ Naijiria ti ori n ta julọ nitori inakuna wọn ọhun naa tun ni ijọba fẹ lọ ya ninu owo wọn.