Serap: Ìlànà òfin ni iléẹjọ́ tẹ̀lé tó fi gbé ẹjọ́ kalẹ̀
Oludari ajọ to n polongo fun akoyawọ ninu eto iṣejọba ni Naijiria, SERAP, Adetokunbọ Mumuni ti ni ilana ti ofin orilẹede Naijiria la kalẹ ni ile ẹjọ to ga julọ̀ ni Naijiria tẹle, lati ṣe idajọ lori ẹsun ti ijọba apapọ fi kan Bukọla Saraki.
Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Adetokunbọ ni, niṣe lo yẹ ki ijọba apapọ ṣe akojọpọ awọn ẹri to poju owo, lati lee mu ki ile ẹjọ fi idi rẹ mulẹ pe Saraki jẹbi awọn ẹsun naa.
Saaju ni ijọba apapọ lọdun 2015, fi ẹ̀sùn kan Aarẹ ile aṣofin agba Naijiria, Bukọla Saraki, pe o n ṣe mago-mago lasiko to n kede dukia rẹ, fun igbimọ to n ṣe agbeyẹwo dukia ti awọn to ba fẹ di ipo oṣelu mu ni ki wọn o to bọ s'ipo.
Ṣugbọn, l'Ọjọbọ ni ile ẹjọ da Saraki lare lori ẹjọ naa nitori ohun to sapejuwe gẹgẹ bi aisi awọn ẹri to bojumu lati ọdọ awọn to rojọ tako Saraki.