SERAP gbé Fashola lọ sílé ẹjọ́ nítorí ìpèsè iná mànàmáná

Raji Fashola

Oríṣun àwòrán, @lagosstategov

Àkọlé àwòrán, Ofin ọfẹ lohun, FOI ni SERAP n lo lati fi pe Fashola lẹjọ

Ẹgbẹ ajafẹtọ kan, SERAP ti gbe minisita fun ipese ina ọba, iṣẹ ode ati ile gbigbe, Raji Fashọla lọ si ile ẹjọ lori ẹsun pe o kuna lati daruks awọn ileeṣẹ agbaṣẹṣe to ni o gba owo iṣẹ ipese ina manamana lọwọ ijọba lai ṣe iṣẹ naa.

Ajọ naa n fẹ ki ile ẹjọ giga apapọ to wa ni Ikoyi, nipinlẹ Eko o kan an nipa fun minisita Fashọla lati gbe orukọ ati awọn ẹkunrẹrẹ iroyin nipa awọn ileeṣẹ tọrọ kan jade.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ipẹjọ naa ko ṣẹyin igbesẹ ajọ ọhun lati lo ofin ọfẹ lohun (FOI) labẹ eyi ti wọn ti fun Fashọla ni gbedeke ọjọ mẹrinla lati fi orukọ naa sita bẹrẹ lati ọjọ kẹrin oṣu kini ọdun 2019.

Fashola n ba awọn oniroyin sọrọ

Oríṣun àwòrán, @lagosstategov

Àkọlé àwòrán, SERAP ní kò yẹ kí mínísítà fún iná ọba ó ṣe orúkọ àwọn kọngílá tó gbowó láì ṣiṣẹ́ ìpèsè iná ọba lóòkú òru

Ajs naa ni bi minisita naa ba lee daruks awọn ileeṣẹ naa si gbangba, yoo mu ko di iṣoro fun wọn lati ko owo naa jẹ.

"Bi Fashọla ba lee daruks wọn, awọn sms orilẹede Naijiria yoo lee so wọn mu fun gbigbe owo ilu to yẹ fun akanṣe iṣẹ lori ipese ina manamana sa lọ."

Àkọlé fídíò, Ọ̀nà tí àwọn olùdíje ipò gómínà ní Ìpínlẹ̀ Ọyọ fẹ̀ gbà yànjú ọ̀rọ̀ ààbò rèé