Owode-Ketu Killing: Àwọn agbébọn kọlu àwọn àgbẹ̀ ní abúlé Owode-Ketu àti Ijoun nípìnlẹ̀ Ogun

Lọjọbọ ni iroyin jade pe awọn afurasi Fulani daran-daran kọlu awọn olugbe abule Owode-Ketu ati Ijoun, to wa ni ijọba ibilẹ Yewa-North nipinlẹ Ogun.
Iroyin naa fi kun un pe eeyan meji ni awọn daran-daran naa pa.
A gbọ pe lasiko ti eeyan meji naa, Isiaka Apesin ati Oguntosin Adebayo n lọ si oko wọn, ni awọn daran-daran naa kọlu wọn, ti wọn si pa wọn.
Bakan naa ni awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ni kia ti wọn pa awọn ọkunrin naa, ni wọn ya wọ inu abule mejeeji, ti wọn si bẹrẹ si ni i yinbọn lati dẹru ba awọn ara abule.
Iṣẹlẹ naa si ti mu ki awọn ileewe, ile itaja ati ileewosan di titi pa ni abule mejeeji.
Eyi waye lai pe ọsẹ meji ti awọn janduku kan kọlu abule Eggua ni agbegbe naa, ti iroyin si sọ pe wọn kọlu awọn daran-daran Fulani to n gbe nibẹ.
- Àwọn darandaran tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ wọ ọgbà Soyinka, kí ló tẹ̀yìn rẹ̀ bọ̀?
- Tó bá jẹ́ pé à ń gbé AK47, ìgbà táwọn àgbẹ̀ dáná sun ilé wa, ṣé aò ti ní pa wọ́n dànù? -Ọmọ Seriki Fulani
- Gbèǹdéke ku àsìkò díẹ̀, Seriki Fulani fohùn ránṣẹ́ sí Sunday Igboho
- Wo ohun tí BBC rí nílé Seriki Fulani ní Igangan
- Ǹkan tÍ Sunday Igboho ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Olórí Miyetti Allah ilẹ̀ Yorùbá
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ pe lootọ ni isẹlẹ naa waye.
Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle si ti sọ pe gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti fi ikilọ sita pe ki awọn to n da wahala silẹ ni Owode-Ketu, Eggua, Igan-Alade ati Igbogila lati ṣọra ṣe.
Rogbodiyan larin awọn Fulani daran-daran ati agbẹ ko ṣẹṣẹ ma a waye ni Iwọ-oorun Gusu Naijiria.
Eyi si lo mu ki ajijagba, Sunday Igboho, bẹrẹ irinajo kaakiri ilẹ Yoruba, lati fi opin si bi awọn afurasi Fulani daran-daran ṣe n kọlu awọn agbẹ.








