TB Joshua's death: Ìyàwó TB Joshua sọ bí ọkọ rẹ̀ ṣe kú àti òhun tó fà á

Oríṣun àwòrán, TB Joshua Ministries
Evelyn to jẹ iyawo gbajugbaja Woli Temitope Balogun ti gbogbo eniyan mọ si TB Joshua, ti sọ bi ọkọ rẹ ṣe ku.
Lasiko to n sọrọ, gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Post ti sọ, Evelyn ni TB Joshua lo igbẹyin aye rẹ lati fi gbadura fun awọn ara ilẹ India lori ohun ti wọn n la kọja lati igba ti aarun Coronavirus ti bẹ silẹ nibẹ.
O ni Woli naa ni wọn ri ninu ọfisi rẹ to ti ku lẹyin to ṣe isin tan ni irọlẹ ọjọ Satide naa.
- Mo rí Áńgẹ́lì mẹ́fà tó wá gbé Wòlíì TB Joshua lọ sọ́run - Àlúfáà kan kéde
- Àdánù láéláé ni fún wa tí wọn kò bá sin òkú T.B Joshua sí ìlú abinibí rẹ̀ - Ọba Arigidi-Akoko
- Ìkọlù Igangan tọ́ka si pé ogun ń bọ̀ ní Nàíjíríà láìpẹ́ - Gani Adams
- Gbajúmọ̀ òjíṣẹ́ Ọlọ́run míràn tún jáde láyé tẹ̀lé TB Joshua
- Ẹ wo àwọn Pásítọ̀ jàǹkàn-jànkàn tí ikú wọn tí mí orílẹ̀èdè Naijiria
- Wo ojú táwọn Pásítọ̀ fi wo T.B Joshua nígbà ayé rẹ̀, tó fa awuyewuye
Awọn ti wọn sunmọ iyawo oloogbe naa ni Evelyn sọ awọn ọrọ yii lasiko ti awọn eniyan lati ilẹ okeere ba obinrin naa ṣe ipade lẹyin iku ọkọ rẹ.
''Ọkọ mi ṣe iṣẹ rẹ tan ninu igbagbọ nitori wakati mẹta lo fi gbadura, ki o to lọ si isin ori oke, ti ilera ara rẹ si pe samu samu.''
''Ko fi igba kankan fi ami han bi ẹni to n ṣe aisan, ti gbogbo ọrọ rẹ si da le lori gbigba adura fun awọn ara ilẹ India ti aarun covid-19 n ba finra.''
''Ko pẹ si igba yii, ni o wa si yara lati wa wẹ, ti mo si fi silẹ ko lo akoko to nilo lati fi mura, ki isin to bẹrẹ.
''Laipẹ lo jade ninu ile lati lọ waasu laarin isin, to si sọ wi pe ohun gbogbo ni igba ati asiko wa fun, igba ki eniyan wa, ati igba ki eniyan lọ''
''Ọrọ rẹ kun fun ẹmi ati ipaya nitori lọgan to sọ awọn ọrọ yii, naa lo dede kuro ni ile ijọsin to si lọ si inu ile.
Mo duro fun igba diẹ lati wo boya yoo jade, nigba ti n ko gburo rẹ ni mo wọle, ti mo si ba lori ijoko bi ẹni to dorikodo, amọ ko mọ ara mọ.''
''Ni kiakia ni mo pe awọn amugbalẹgbẹ rẹ ki wọn ji i, amọ ko si ohun ti wọn le ṣe lasiko naa.''
''Mo gba lootọ wi pe o lọ ba Ọlọrun nile ni nitori o ṣiṣẹ takuntakun nigba ti o wa pẹlu wa, ti opin ọrọ rẹ si awọn eniyan ni lati ''ma a ṣọra, ki wọn si ma a gbadura''.
Ọjọ Karun un, Oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ni gbajugbaja Woli agbaye TB Joshua jade laye ni ẹni ọdun mẹtadinlọgọta.



















