TB Joshua: Ọba Arigidi ní àwọn kò ní ró òkú wòlíì náà torí ó tí sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ mọ́ ikú rẹ̀ sẹ́yìn

Oríṣun àwòrán, others/bbc
Kabiyesi ilu Arigidi Akoko, to jẹ ilu abinibi oloogbe Temitọpẹ Joshua ti sọ pe ifẹ gbogbo ọmọ ilu naa ni pe ki wọn o sin oku gbajugbaja wolii naa sibẹ.
Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Zaki ilu Arikidi, Ọba Yisa Olanipekun sọ pe awọn iranṣẹ Ọlọrun nla bi Mose Orimọlade, Ayọdele Babalọla, Samson Ọbadare, ni wọn sin si ilu abinibi wọn.
O ni lootọ awọn ko ti i ba iyawo oloogbe sọrọ, ṣugbọn dandan ni ki wọn o gbe wa sile.
- Mo rí Áńgẹ́lì mẹ́fà tó wá gbé Wòlíì TB Joshua lọ sọ́run - Àlúfáà kan kéde
- Ẹ wo àwọn Pásítọ̀ jàǹkàn-jànkàn tí ikú wọn tí mí orílẹ̀èdè Naijiria
- Ìdí rèé tí ń kò fi ní ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mi ní June 12 - TB Joshua sàsọtẹ́lẹ̀
- Ìtàn ayé TB Joshua tó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta nínú ìyà rẹ̀
- Wòlíì TB Joshua sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ lọ́jọ́ Satide tó kú - Ìjọ SCOAN
- Gbajúmọ̀ òjíṣẹ́ Ọlọ́run míràn tún jáde láyé tẹ̀lé TB Joshua
- Wo ojú táwọn Pásítọ̀ fi wo T.B Joshua nígbà ayé rẹ̀, tó fa awuyewuye
Lori iroyin to n lọ ni ori ayelujara pe awọn ara ilu Arigidi fẹ ẹ wa idi iku to pa Joshua, Ọba sọ pe ko si nkan to jọ iwadii kankan.
O ni "ko si idi ti ẹnikẹni fi fẹ ẹ pa, a gba pe o ti pari iṣẹ ti Ọlọrun ran wa si aye lati ṣe ni, paapaa ninu ọrọ to sọ ni ọjọ diẹ sẹyin.
"Ṣugbọn nkan ti a n sọ ni ẹ ba wa gbe oku ẹ wa si Arigidi fun isinku."
O ni ilu naa yoo di ibi ti gbogbo agbaye yoo ma a wa, lati wa gbadura nibi iboji rẹ, ti wn ba sin sibẹ.
O ni lootọ ni iyawo rẹ kii ṣe ọmọ Arigidi, bẹẹ ni awọn ọmọ rẹ ko de ilu Arigidi ri.
"Ti wọn ko ba fi sin si ile, ko si bi awọn ọmọ tabi iyawo rẹ yoo ṣe de ilu wa mọ.
"Oun (Joshua) kọ lo ni ara rẹ mọ, awa la ni ọmọ wa. Ọmọ ologo wa ni, ko si gbọdọ sun sita."
Kabiesi sọ pe nkan ti gbogbo ọmọ ilu fẹ ni oun sọ, ti oun ko si ni i fẹ ki ọrọ ibi ti wọn yoo sin oloogbe si da wahala silẹ.
"O ti pẹ ti TB Joshua ti maa n sọ pe oun yoo ku, ta ni yoo rọpo rẹ fun wa"

Oríṣun àwòrán, T.b joshua minisries
Abẹwo si ilu Arigidi, ipinlẹ Ondo, to jẹ ilu abinibi oloogbe Woli T. B Joshua fihan pe, ẹni to dara nita, dara nile ni.
Ọkan lara awọn agbaagba ni agboole rẹ to ba BBC Yoruba sọrọ, Solomon Olotu, sọ pe awọn mọ iku rẹ lara pupọ.
"A ko ti mọ ẹni ti ọlọrun yoo fi rọpo fun wa, nitori pe oun ni imọlẹ ilu yii.
T.B Joshua ti ma n sọ tẹlẹ pe oun yoo ku, oun ni imọlẹ ilu yii, ibanujẹ lo jẹ fun wa pe o papa ku.
Nigba to n tọka si awọn nkan to ṣe fun ilu Arigidi, Olotu naa sọ pe Joshua lo ra ẹrọ amunawa transformer fun ilu naa, to si tun ma n ko ounjẹ fun awọn arugbo ati alaini loore-koore.
Ẹlomiran to tun sọrọ, ọgbẹni Isaac Olumọfẹ sọ pe, oun ati Joshua jọ gbe papọ ni ilu Eko ni, ko to o dipe aisan da oun pada si ilu Arigidi.

O ni owo ti Joshua fun oun lo da oun pada si aye.
Bakan naa ni Oloye mii sọ pe Joshua lo mu ki ọpọlọpọ ọmọ ilu Arigidi da baalu mọ, nitori pe o ti gbe ẹlikọpita wa si ilu ri, to si gbe si ibi ti gbogbo ara ilu ti ni anfaani lati wọ inu rẹ fun igba akọkọ.
Ọba alade ilu naa, Zaki ti Arigidi, Ọba Yisa Olanipekun sọ pe ilu abinibi rẹ ni awọn fẹ ki wọn o wa sin oku rẹ si.
Ọkan lara awọn ẹbi oloogbe to ba BBC sọrọ, Arabinrin Bọsẹ Balogun sọ pe, iku rẹ dun oun pupọ, ki Ọlọrun si gba a si afẹfẹ rere.
"Baba mi lo jẹ, bo tilẹ jẹ pe aburo lo jẹ fun mi. Amọ o dun mi pe iku mu u lọ ni ọsan gangan."




















