T.B Joshua: Ọjọ́ ìbí ayọ̀ fún mi àmọ́ ń kò ní lè ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà

Oríṣun àwòrán, others
Ọjọ Kejila, oṣu Kẹfa, lo yẹ ki Woli Temitope Balogun T.B Joshua ṣe ọjọ ibi ọdun mejidinlọgọta rẹ loke eepẹ.
Ṣugbọn o se ni laanu pe o ku ni ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ṣaaju ọjọ naa, nigba to ku ọsẹ kan pere ki ọjọ naa ko.
Amọ nkan to tun jẹ iyalẹnu ni pe, wooli naa ti sọ nipa ọjọ ibi rẹ pe oun ko ni ṣe ayẹyẹ kankan ni ọdun yii.
- Wòlíì TB Joshua sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ lọ́jọ́ Satide tó kú - Ìjọ SCOAN
- Ìtàn ayé TB Joshua tó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta nínú ìyà rẹ̀
- Ikú kò m'ọmọdé, kò màgbà, ẹ gbàdúrà fún ìdílé mi àti aya pẹ̀lú ọmọ olóògbé- Pásítọ̀ Adeboye
- Mi ò bú Baba Adeboye, mo kàn gégùn-ún fún àwọn tí kò ṣàtìlẹyìn fún Oduduwa Republic ni- Sunday Igboho
- Ìjọ Islam fìwé pe Wòlíì Genesis bíi àlejò pàtàkì sí òru Lailatul Quadir, ariwo sọ
Ninu fidio kan to jade sori ayelujara lẹyin iku rẹ, Joshua n kọ orin ọjọ ibi fun ara rẹ pe "Happy Birthday to you...."
Nibẹ naa lo si ti kede pe oun ko ni i ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi kankan ni ọdun yii nitori pe awọn iṣẹlẹ to n waye ni agbaye ko dun mọ oun ninu.

Oríṣun àwòrán, TB Joshua Ministries
O ni "ko ni i rọrun fun mi lati ṣe ajọyọ ọjọ ibi mi, nitori pe ọpọ eeyan to fẹ ẹ wa ni wahala ati idaamu to n ṣẹlẹ ni agbaye n ba ninu jẹ.
"Ibanujẹ ati ibẹru wọn kan mi. Nitori naa, ẹ jẹ ki a fi ọjọ naa ṣe ọjọ aawẹ ati adura, kẹ ma si gbagbe awọn alaini."
O ni "lagbara Ọlọrun, ọpọ ayẹyẹ ọjọ ibi si wa niwaju fun mi ta maa se."
Bo tilẹ jẹ pe o kọ orin ọjọ ibi fun ara rẹ ninu fidio naa, oloogbe T.B Joshua sọ pe ọpọlọpọ ọjọ ibi lo ṣi wa niwaju lati ṣe.
Nigba aye rẹ, ẹlẹyinju aanu, oloore ati olufifunni ni ọpọ eeyan mọ ọ si, paapaa awọn ololufẹ rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjọba, ẹ bá mi wá ẹni tó pa ọmọ mi jáde - Ẹ̀bí olóògbé gbarata
- Aláìmọ̀kan àti òmùgọ̀ ló ń pè fún ìdásílẹ̀ Yorùbá Nation - Aregbesola
- Gbogbo ǹkan tí à ń ṣe láti jà fún ''Yoruba Nation'', ìjà àwọn bàbá wa là ń gbé - Sunday Igboho
- Àgbẹ̀ míì tún fara gbọgbẹ́ ìbọn ní Igangan láti ọwọ́ afurasí darandaran
- Ìjọba ẹ ṣọ́ra! gbígbégilé ojú òpó Twitter tako ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ Naijiria - Gómínà Ṣeyi Makinde
- Ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án pa
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ìjìyà fún àwọn tó ṣì n lo Twitter ní Naijiria
- Mọ̀ si i nípa ìtàn eégún Gelede àti pàtàkì eégún náà sí àwọn obìnrin nílẹ̀ Yoruba
- Wo àwọn nkán tó ṣẹlẹ̀ níbi ìwọ́de Yoruba Nation tó ti wáyé sẹ́yìn

Wo awọn eeyan to n daro iku TB Joshua lori ayelujara:
Nkan yii naa si ni awọn eeyan kan n sọ nipa rẹ lori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Twitter
















