Genesis: Ariwo sọ lórí bí ìjọ Mùsùlùmí ṣe pe wòlíì sí òru Lailatul Quadir

Oríṣun àwòrán, Suphian Opeyemi Sodiq/Facebook
Yoruba ni ẹsin ko fa ija, bo ba se wu ni laa se ẹsin ẹni.
Amọ eyi ko ri bẹẹ pẹlu isẹlẹ kan to n waye lori ayelujara eyi tawọn eeyan n gba bii ẹni gba igba igba ọti, ti wọn si n tutọ si ara wọn loju lori ọrọ ẹsin.
Ohun to sokunfa isẹlẹ yii ni ti ijọ ẹsin Islam kan, Ahbaab li-Islam pẹlu ajọsepọ Markazu Ahbaab Uloomudeen to fẹ se isin oru abiyi taa mọ si lailatul Quadir.
- Ẹ̀tanú pé Olùṣọ́ Genesis kò fẹ́ Laide Williams-Oni ló ṣe rán an lọ́ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan - CCC Genesis Global
- Genesis Global: Sáká lara Woli Israel Ogundipe dá, kìí ṣe àìlera ló mú kí wọn fi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n
- Wo bi wọ́n ṣe n ṣe àmójútó ilé ìjọsìn Prophet Israel Oladele, CCC Genesis Global
- Wo àwọn èèkàn, ìlúmọ̀ọ́ka olórin tó ṣàbẹ̀wò sí ijọ Celestial Church ti Genesis Global
- Àwọn ìwàásù akọnilẹ́nu hàà tí Prophet Israel Oladele CCC Genesis Global ti ṣe rèé
- Báyìí ni ìsìn ṣe lọ lónìí nílé ìjọsìn CCC Genesis Global
- Wo nkan tó sọ Woli ìjọ Genesis Global di ọmọ ìjọ Cele lẹ́yìn tó kúró nínú ìjọ C.A.C.
Ijọ naa ti Fadheelatul Ustaz Alhaji Habeebulah se alakoso rẹ, lo wa ladugbo Iju Ishaga nilu Eko, ti isin oru abiyi naa yoo si waye ni ọjọ Keje osu karun taa wa yii, laago mẹwa owurọ.

Oríṣun àwòrán, Suphian Opeyemi Sodiq/Facebook
Amọ ohun to wa jẹ iyalẹnu fawọn ọmọ Naijiria to ri iwe ipe ti wọn fisita fawọn alejo, ni bi wọn se ni Wolii ati Ojisẹ Ọlọrun Oladele Ogundipe, ti ọpọ eeyan mọ si Wolii Genesis, ni alejo pataki nibi eto naa.
Iwe ipe yii ni Suphian Opeyemi Sodiq fi soju opo Facebook rẹ.
Bẹẹ ba gbagbe, awuyewuye waye laipẹ yii nipa Wolii Genesis ati ẹsun ti obinrin kan fi kan pe o gba owo lọwọ oun lati fi ra ilẹ amọ ti ko ri owo ati ilẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Orí yọ ẹ́ o Baba Ijesha tí mi ò rí fídíò èpè tí wọ́n ní ò ń ṣẹ́, ǹkan tí mi ò bá ṣe fún ẹ... - Iyabo Ojo
- A kò bá ti lé Baba Ijesha àmọ́ kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, a kò sì fọwọ́ sí ìwà tó wù - Mr Latin
- Ẹ má da ẹnikẹ́ni lẹ́bi, ẹ jẹ́ ká wà ní ìṣọ̀kan láti borí ọ̀tá - Tinubu
- Ìwádìí fihàn pé Baba Ijesha bá ọmọdé lòpọ̀, a kò gba béèlì rẹ̀ - Ọ̀gá Ọlọ́pàá Eko
- Wo ohun mánigbàgbé mẹ́fà nípa Gbenga Adeboye lẹ́yìn ọdún 18 tó kú
- Ọjọ́ àkọ́kọ́ tí Baba Ijesha bá ọmọ mi lòpọ̀ ní mo ti mọ̀ àmọ́ kò sí ẹ̀rí - Princess
- Ọlọ́pàá kò lè dá wa dúró, á ṣe ìwọ́de Yoruba Nation l‘Abeokuta lọ́la - Yoruba Nation Agitators
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn tẹ ara wọ́n pa, ariwo ẹkún sọ
- Saidi Balogun figbe ta pé wọn ń ba òun lórúkọ jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Iyabo Ojo gbé fídíò jáde nípa bí ọwọ́ ṣe tẹ Baba Ijesha
Ọrọ yii lo di tile ẹjọ, ti wolii Genesi si lo osu meje lọgba ẹwọn, ki wọn to gba beeli rẹ laipẹ yii.
Haa, ki ni eleyi si lo n gba ẹnu ọpọ eeyan lori ayelujara to ri iwe ipe naa.

Oríṣun àwòrán, Al-Mudeer Ar-Rashādy Oladele/Facebook
Ọpọ ọmọ Naijiria to si fesi lori isẹlẹ naa lo koro oju si igbesẹ pipe wolii wa sibi isin musulumi nigba ti awọn eeyan miran ni ko si ohun to buru ninu rẹ.
Ni ero awọn ọmọ Naijiria to da si ọrọ naa, wọn ni igbesẹ naa tako ẹsin Islam pupọ, nitori oru abiyi ni ọwọ ju ọwọ ti wọn fi mu yii lọ.
Koda, Rashady Oladele lero tiẹ ni se lo yẹ ki wọn fi iya to jopin jẹ ẹni to se iru eyi, ti awọn miran si lero pe tori owo ni wọn se hu iwa naa.

Oríṣun àwòrán, Ibitoye Farian/Facebook

















