Israel Crush: Èèyàn 44 kú, 103 farapa níbi ọdún Lag B‘Omer

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ariwo ẹkun ti gbode lorilẹede Israel nibi ajọdun ẹsin kan ti wọ̀n n pe ni Lag B‘Omer
Ko din ni eeyan mẹrinlelogoji to kú lasiko ti awọn eeyan tẹ ara wọn pa nibi ọdun isẹse naa to waye ni Ariwa ila oorun Israel.
Yatọ si awọn to ku, ọpọlọpọ lo tun fi ara pa níbi ọdun Lag B'Omer ọhun, to ma n waye lọdọọdun ni isalẹ ori oke Mount Meron.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọjọ́ àkọ́kọ́ tí Baba Ijesha bá ọmọ mi lòpọ̀ ní mo ti mọ̀ àmọ́ kò sí ẹ̀rí - Princess
- Saidi Balogun figbe ta pé wọn ń ba òun lórúkọ jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Ìwọ́de fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Yorùbá di kọ̀ l‘Ogun, ọlọ́pàá yarí pé kò ní wáyé
- Iyabo Ojo gbé fídíò jáde nípa bí ọwọ́ ṣe tẹ Baba Ijesha
- Yekeen Ajileye, ọ̀gá mi nínú iṣẹ́ tíátà ṣẹ̀ mí, ó ṣẹ ẹlẹ́dàá mi - Abija
- Ìwọ́de alágbára ń bọ̀ l‘Eko láàrọ́ òní láti tako béèlì Baba Ijesha
- Ta ló gbé fọ́tò Aishal Lawal síta pé ó kú lọ́jọ́ ìkúnlẹ̀?
- Ọwọ́ ṣìnkún Àmọ̀tẹ́kùn tẹ afurasí agbẹ́bọn darandaran mọ́kànlá l‘Oyo
- Mò ń ké tantan, tí Buhari kò bá fí ipò sílẹ̀, ìbò 2023 kò ní wáyé - Father Mbaka
- Olórùka ti gba òrùka, n kò sí lórí àtẹ mọ́, ẹ má sanwó láti fẹ́ mi - Oluwo figbeta
Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu sapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi àjálù nla, to si ni oun n gbadura fun awọn to kagbako.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún eeyan lo kóra jọ pọ sibi ọdun iṣẹẹse awọn Júù, eyi to mu ko jẹ ipejọpọ to tobi julọ lati igba ti coronavirus ti bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin to kọkọ jáde nipa iṣẹlẹ naa ni pe ilé kan nibẹ lo wó, sugbọn awọn alamoju iṣẹlẹ pajawiri pada sọ pe awọn eeyan tẹ ara wọn pa ni nkan bi aago kan òru nibẹ.
Ileesẹ ọlọpaa sọ pe ijamba naa bẹrẹ leyin ti ẹsẹ àwọn olukopa kan yẹ̀ lori àtẹ̀gùn, eyi to fa bi ọpọlọpọ ṣe ṣubú lu ara wọn.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe bi awọn to rebọ láti ori àtẹ̀gùn ṣe ṣubú lu àwọn to wa nilẹ lo fa isubu ọpọlọpọ.
Fidio kan to wa lori ayelujara nipa iṣẹlẹ naa safihan bi awọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún eeyan ṣe n tiraka lati gba oju ọna tooro sa kuro bi àjálù naa ṣe n waye.
Olukopa kan sọ oun kọkọ ro pe ado oloro fẹ ẹ dun ni lasiko ti ikede bẹrẹ si ni jade pe ki awọn eero tuka.

Oríṣun àwòrán, Screen Shot BBC
"Ko si ẹni to lero pe nkan bayii le waye níbi. Ajọyọ di ibanujẹ, imọlẹ ńlá si di okunkun biribiri."
Koda, ogunlọgọ ọkọ ambulansi lo sare de ibi iṣẹlẹ naa, ti awọn alamoju iṣẹlẹ pajawiri si to òkú awọn eeyan si ilẹ.
Baalu ẹlikọpita ni wọn si fi ko awọn to farapa, lọ sileewosan.
Awọn alasẹ ijọba sọ pe ko din ni eeyan 103 to farapa, lara wọn ni ni eeyan 38 to wa ni ẹsẹ̀ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.
Ọga Agba ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri, Magen David Adom sọ pe awọn ko ni i sinmi titi wọn o fi doola gbogbo àwọn to farapa kuro nibi ajalu naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Bawo ni ọdun Lag B'Omer ṣe jẹ?
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ Júù to jẹ ẹlẹ́sìn abalaye lo ma n rinrinajo mimọ lọ si Meron ni ọdọọdún fun Lag B'Omer.
Ọjọ isinmi lẹ́nu isẹ ni ọjọ ọdun naa. Ti wọn si ma n ko ina jọ ni òru di owurọ. Bẹẹ ni ijo ati adura ma n lọ kíkankíkan.
Ìlú naa jẹ ibi ti wọn sin oku Olukọni Shimon Bar Yochai, to jẹ gbajugbaja Aríran ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Oun lo si pasẹ pe ki wọn o ma a ṣe ajọdun iku rẹ̀ pẹlu ariya, lati mọriri igbeaye rẹ.

Gẹgẹ bi akọsilẹ iwe iroyin Times ti Israel, ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan lo ti de sibẹ ni alẹ Ọjọbọ, pẹlu ireti ọpọ eeyan si lọjọ Ẹti.
Botilẹjẹ pe awọn to kopa nibi ayẹyẹ naa lọdun yii pọ ju ti ọdun to kọja lọ, nitori Covid-19, sibẹ o tun kere ju iye eeyan to ma n kopa lọdọọdun.












