Oduduwa Nation: Àwọn ọlọ́pàá bíi 200 ló dènà dè wá níbi tí a ti fẹ́ ṣe ìwọ́de l'Abeokuta - Ilana Omo Oodua

Oríṣun àwòrán, Ìlànà Ọmọ Oòduà International Facebook
Ẹgbẹ to n ja fun ominira ilẹ Yoruba, Ilana Ọmọ Oodua ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi sikun ofin mu eeyan marundinlọgbọn ti wọn n ṣe iwọde niluu Abeokuta.
Ninu atẹjada kan ti akọwe ẹgbẹ naa, Maxwell Adeleye buwọlu, eyii to fi ṣọwọ si BBC lo ti kede bẹẹ.
O ni nnkan bii igba ọlọpaa lo yii awọn eeyan naa ka ki wọn to fi ofin mu wọn l'Abeokuta.
Gẹgẹ bo ṣe sọ "A fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi panpẹ ofin mu marundinlọgbọn ninu awọn eeyan wa lasiko ti wọn gbaradi lati bẹrẹ iwọde fun ominira ilẹ Yoruba."
"A si fẹ jẹ ko wa ni akọsilẹ pe awọn eeyan naa ko tapa si ofin kankan, ni ṣe ni wọn n ṣe ohun to tọ si wọn gẹgẹ bii ẹtọ wọn labẹ ofin lati ja fun ominira ati lati korajọ pọ gẹgẹ bii ofin ṣe la a kalẹ."
O ni awọn gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua kii ṣe oni jagidijagan, nitori naa, awọn n ke si ijọba lati tu awọn eeyan naa silẹ ni kankan, bi bẹẹ kọ awọn yoo gbenu woju ẹkun ileeṣẹ ọlọpaa kaakiri ilẹ Yoruba.
- Obìnrin tó n wá orí adé láti fi ṣe ọkọ pàdánù ₦51m sọ́wọ́ gbájúẹ̀ l'Eko
- Ìjọ Islam fìwé pe Wòlíì Genesis bíi àlejò pàtàkì sí òru Lailatul Quadir, ariwo sọ
- Wo ẹ̀sùn mẹ́rin tí ìjọba fi kan Baba Ijesha àti ìjìyà tí ìkọ̀ọ̀kan ní lábẹ́ òfín
- Ẹ má da ẹnikẹ́ni lẹ́bi, ẹ jẹ́ ká wà ní ìṣọ̀kan láti borí ọ̀tá - Tinubu
Ẹgbẹ naa tun ke si gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapo Abiodun ko ma ṣe gba awọn kan laye lati lo ipinlẹ rẹ lati fi ti tẹ ẹtọ awọn ọmọ Yoruba loju.
Iroyin ni iwaju aafin Alake ti ilu Ẹgba ni awọn ọlọpaa naa ti ko awọn oluwọde ọhun sinu ọkọ Black Mariac ti wọn gbe wa.
Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kọkọ ki awọn oluwọde naa nilọ pe wọn ko gbọdọ gunle iwọde naa, bi bẹẹ kọ, awọn eeyan naa yoo foju wina ofin.
Ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ naa fesi pada pe ti ọlọpaa ni wọn n wi nitori awọn yoo tẹsiwaju pẹlu iwọde naa.

Oríṣun àwòrán, Ìlànà Ọmọ Oòduà International Facebook
Ọrọ iwọde ti awọn ajijagbara to n fẹ orilẹede Yoruba, eyi ti ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun wọgile ti n fa awuyewuye bayii.
Idi ni pe awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lorisirisi lo ti n leri leka pe bi ọlọpa ba fẹ, bi wọn si kọ, ohun to ni ki awọn mase yẹn, awọn yoo se, se isu atẹnumọran kii jona.
Ọjọbọ ni ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun fi atẹjade kan sita pe oun ti wọgile iwọde tawọn ajijagbara fẹ se nilu Abeokuta lati beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìwádìí fihàn pé Baba Ijesha bá ọmọdé lòpọ̀, a kò gba béèlì rẹ̀ - Ọ̀gá Ọlọ́pàá Eko
- Wo ohun mánigbàgbé mẹ́fà nípa Gbenga Adeboye lẹ́yìn ọdún 18 tó kú
- Ọjọ́ àkọ́kọ́ tí Baba Ijesha bá ọmọ mi lòpọ̀ ní mo ti mọ̀ àmọ́ kò sí ẹ̀rí - Princess
- Ọlọ́pàá kò lè dá wa dúró, á ṣe ìwọ́de Yoruba Nation l‘Abeokuta lọ́la - Yoruba Nation Agitators
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn tẹ ara wọ́n pa, ariwo ẹkún sọ
- Saidi Balogun figbe ta pé wọn ń ba òun lórúkọ jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Iyabo Ojo gbé fídíò jáde nípa bí ọwọ́ ṣe tẹ Baba Ijesha
Amọ Ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua, IOO, ninu atẹjade kan to fisita ati lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ kede pe, gbogbo agbara ti awọn ajijagbara naa ni lawọn yoo fi tako awọn ọlọpaa nilu Abeokuta loni.
Atẹjade naa ti akọwe ẹgbẹ, Maxwell Adeyemi Adeleye fọwọsi, tun kesi awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lorisirisi lati maa bọ nilu Abeokuta lọjọ Satide oni lati wa tọpinpin bi iwọde naa yoo se lọ.

Oríṣun àwòrán, Ìlànà Ọmọ Oòduà International Facebook
Lara awọn ẹgbẹ to kesi ni ẹgbẹ awọn akọroyin lobinrin ati lọkunrin, ẹgbẹ ajafẹtọẹni Huriwa, Serap, CDHR, ẹgbẹ awọn agbẹjọro atawọn ẹgbẹ miran.
Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Yoruba naa ni ileesẹ ọlọpaa kede ogun si ẹtọ ọmọ Yoruba lati korajọ se iwọde alafia ni, pẹlu bo se ni oun wọgile iwọde naa.
Ẹgbẹ IOO naa wa n fewe ọmọ mọ ileesẹ ọlọpaa leti pe, gbogbo ohun to ba gba nilana ofin ati lọdọ awujọ agbaye, ni awọn yoo fun to ba, to ba fi gbe igbesẹ lati da iwọde naa duro.
Ẹgbẹ IOO, ti alagba Banji Akitoye n ko sodi wa n ke tantan sileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun pe oun yoo se iwọde naa lọni gẹgẹ bo se wa ni akọsilẹ nitori wọn ko ni agbara labẹ ofin lati da awọn duro.

Ọlọpaa ko le da wa duro, a se iwọde Yoruba Nation l‘Abeokuta lọjọ Satide

Oríṣun àwòrán, Oduduwa Grand Alliance For Independence
Awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati awọn eekan nilẹ Yoruba, ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun lati tako iwode Yoruba Nation ti yoo waye ni ilu Abeokuta lọla.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lede ni wọn ti fi ẹsun kan awọn ti wọn n ṣe iwode lati beere fun idasilẹ orilẹede ilẹ Yoruba wi pe wọn n da alaafia ipinlẹ Ogun ru.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni igba mẹrin ni wọn ti ṣe iwode naa laarin osu kan, ti o si mu wahala ati ipalara dani fun awọn eniyan ara ipinlẹ Ogun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọjọ́ àkọ́kọ́ tí Baba Ijesha bá ọmọ mi lòpọ̀ ní mo ti mọ̀ àmọ́ kò sí ẹ̀rí - Princess
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn tẹ ara wọ́n pa, ariwo ẹkún sọ
- Saidi Balogun figbe ta pé wọn ń ba òun lórúkọ jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Ìwọ́de fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Yorùbá di kọ̀ l‘Ogun, ọlọ́pàá yarí pé kò ní wáyé
- Iyabo Ojo gbé fídíò jáde nípa bí ọwọ́ ṣe tẹ Baba Ijesha
- Yekeen Ajileye, ọ̀gá mi nínú iṣẹ́ tíátà ṣẹ̀ mí, ó ṣẹ ẹlẹ́dàá mi - Abija
Amọ, Banji Akintoye to jẹ agba ọjẹ nilẹ Yoruba ati adari ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Ilana ọmọ Yoruba ni, ko si otitọ kankan ninu ọrọ ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ.
Akitoye ni awọn ni aṣẹ labẹ ofin orilẹede Naijiria lati ja fun ẹtọ awọn nipa ṣiṣe iwọde lai fa wahala.
Bakan naa ni ẹgbẹ Oodua People's Congress ni dandan iwọde naa yoo waye ni Satide, Ọjọ Kinni, Osu Karun un, ọdun 2021.
A ko fẹ pada si asiko ''Abacha must go'', ẹyin ọlọpaa Ogun ẹ ṣọra yin - Ẹgbẹ OPC
Ẹgbẹ Oodua people's Congress OPC, ti ni ko si ohunkohun ti o le da awọn duro iwọde ni ipinlẹ Ogun ni Ọjọ Satide.

Oríṣun àwòrán, OPC
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ OPC, Shina Akinpelu ni oun ni igbagbọ pe ko to di asalẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn adari yoo ti wa ojutu si ọrọ naa.
''Ọlọpaa yẹ ko fun wa ni 'caution paper' ti a tọ wọ bọ pe ko ni si wahala nitori awọn onijagidijagan to ba fẹ lo iwọde naa lati da wahala silẹ.
''Wọn fẹ sọ wa di ẹranko ni, a ko ni gba fun wọn lati da wa pada si igba ''Abacha must go'', amọ ti wọn ba fẹ wahala wọn yoo ri.''
Bakan naa ni ẹgbẹ OPC ni ti ileeṣẹ ọlọpaa ba ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn, ohun gbogbo a lọ ni irọwọrọṣẹ.
- Ìwọ́de alágbára ń bọ̀ l‘Eko láàrọ́ òní láti tako béèlì Baba Ijesha
- Ta ló gbé fọ́tò Aishal Lawal síta pé ó kú lọ́jọ́ ìkúnlẹ̀?
- Ọwọ́ ṣìnkún Àmọ̀tẹ́kùn tẹ afurasí agbẹ́bọn darandaran mọ́kànlá l‘Oyo
- Mò ń ké tantan, tí Buhari kò bá fí ipò sílẹ̀, ìbò 2023 kò ní wáyé - Father Mbaka
- Olórùka ti gba òrùka, n kò sí lórí àtẹ mọ́, ẹ má sanwó láti fẹ́ mi - Oluwo figbeta
Ọlọpaa yẹ ko pese aabo fun wa lasiko iwọde, kii ṣe ko halẹ mọ wa - Ilana Ọmọ Yoruba
Ẹgbẹ Ilana ọmọ Yoruba ti ni ko si ẹnikẹni to lee da awọn duro lati ṣe iwọde lati pe fun orilẹede ilẹ Yoruba.
Lasiko ti Akọwe Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Odua, Opeoluwa George Akinola n ba BBC News Yoruba sọrọ, o ni awọn ni aṣẹ gẹgẹ bi ọmọ Yoruba lati ṣe iwode.

Oríṣun àwòrán, Facebook
''Ẹni kankan ko laṣẹ lati ni ki a ma rin ni ilẹ wa nitori ilu wa lawa, a ma rin, a ma yan fanda nitori a kii ṣe onijagidijagan nitori naa ko ni si wahala''
''A ṣe ni Ibadan ko si wahala, nitori naa a ma ṣe ni Abeokuta lai si wahala''
Ọlọpaa ipinlẹ Ogun yẹ ki wọn pese eto aabo fun wa nitori a ko gbe ibọn ati ada lati sewọde, a fẹ ba awọn araalu sọrọ lori nkan ti a fẹ''
Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Yoruba fikun wi pe ọmọluwabi ni awọn, nitori naa ki ileeṣẹ ọlọpaa ma da wahala silẹ.
A kii ṣe o ni jagidijadan, a ko ni fi tipatipa ṣe iwọde ni Ogun - Banji Akinoye
Banji Akitoye to jẹ adari ẹgbẹ Ilana Ọmọ Yoruba ti ni awọn yoo tiraka lati ba ileeṣẹ ọlọpaa jiroro, ki ilẹ Ọjọ Satide to mọ.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Amọ, o ni ti ileeṣẹ ọlọpaa ba tẹnumọ pe dandan wọn ko gbọdọ ṣe iwọde naa, ko ni waye.
Banji Akintoye fikun wi pe, kii ṣe tipatipa ni Yoruba gbọdọ duro ni Naijiria nitori naa ni awọn ṣe n pe fun Yoruba Nation nitori iṣekupani ojojumọ yii gbọdọ dopin.
''A ti wi pe kii ṣe ẹṣẹ pe awọn ko ṣe Naijiria mọ, ki onikaluku lọ nilọ tirẹ''
Bakan naa ni Akintoye ni awọn to wa si iwode to waye ni Ibadan le ni miliọnu meji, ti ko si si rogbodiyan kankan.

Ìwọ́de fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Yorùbá di kọ̀ l'Ogun, ọlọ́pàá yarí pé kò ní wáyé

Oríṣun àwòrán, Oduduwa Grand Alliance For Independence
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, o dabi pe nnkan ti n pakasọ fun awọn eeyan to n beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba lori iwọde ti wọn n gbero lati se nipinlẹ Ogun ni ọla ọjọ Satide.
Idi ni pe ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti faake kọri lati gba awọn oluwọde naa laaye lati wa se iwọde wọn, ti wọn si rọ wsn lati jami lori iwọde ọhun.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fisita l'Ọjọbọ lori ọrọ yii salaye pe awọn iwọde ti awọn ẹgbẹ yii ti se latẹyinwa lo n fa sunkẹrẹ fakẹrẹ yika ipinlẹ naa.
- Àwọn tó ń polongo Oduduwa Nation fẹ́ ba àláàfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ni- YWG
- Àwọn olùpolongo Oduduwa Nation àti ọlọ́pàá kojú ara wọn ní Sagamu
- Ẹ má lọgun ‘Oduduwa Nation’ mọ́, Yorùbá ló kàn láti jẹ ààrẹ - Oluwo
- Àwọn tí àkóso ìjọba bọ́ lọ́wọ́ wọn ló ń ti Igboho lẹ́yìn lórí ìdásílẹ̀ Oodua Nation - YWG
Bakan naa ni ileesẹ ọlspa sọ pe iwọde ọhun tun le sokunfa rogbodiyan nipinlẹ naa, tawọn ọmọ isọta yoo si ja iwọde naa gba lati da araalu laamu.
"Bẹẹ ba gbagbe, awọn ikọ to n polongo fun idasilẹ orilẹede Yoruba se iwọde lọjọ Kọkanlelogun osu kẹta ọdun yii nilu Isara Remo, ti wọn si di awọn opopona, eyi to mu lilọ-bibọ ọkọ pakasọ.
Irufẹ iwọde yii naa tun waye nilu Sagamu lọjọ Kẹrindinlogun osu Kẹrin yii, ti wọn si fẹ doju ija kọ agọ ọlọpaa to wa nilu naa lainidi.
Tun wẹ, wọn tun se iwọde miran ni Ajuwọn lọjọ kẹẹdọgbọn osu yii bakan naa, ti wọn si n pin awọn iwe to n ru eeyan ninu.
Bẹẹ ni wọn n lẹ oko mọ awọn ọlọpaa ati ileesẹ agbofinro miran."
Atẹjade naa ni ikọ yii lo tun n beere lati se iwọde fun igba kẹrin lọla ọjọ kinni osu karun ọdun yii nilu Abeokuta, eyi ti yoo jẹ ikẹrin iru rẹ ni sisẹ n tẹle.
Ileesẹ ọlọpaa ni o maa n nira fawọn lati ka awọn janduku to ba jẹ asawọ laarin awọn oluwọde lọwọko ni awọn iwọde to ti waye saaju, ti wọn si maa n da omi alaafia ilu ru.
"Amọ a ko le kawọ gbera kawọn eeyan kan maa mu awọn araalu yoku lọwọ sẹyin pẹlu ihuwasi wọn, eyi to tun n dunkooko mọ isọkan Naijiria.
Ta ba si sọra, o seese ki ipinlẹ Ogun bọ sinu irora ati ipayinkeke to n ti idi irufẹ iwọde bẹẹ waye ni awọn ipinlẹ miran ti wọn ti gba wọn laaye.
Ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ogun wa n rọ awọn asaaju ikọ to n pe fun idasilẹ Oduduwa lati jami lori erongba wọn lati se iwọde miran nibikibi yika ipinlẹ naa.
- Femi Falana tún ti yọ sùtì ètè sí ìpè fún ìdásílẹ̀ ‘Oduduwa Nation’
- Ìyàtọ tàbí àfiwé wo ló wà láàrin Sunday Igboho, Nnamdi Kanu àti Asari Dokubo?
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
- Ẹ̀yà Yorùbá ti fara ṣiṣẹ́ púpọ̀ fún Naijiria, nítorí nàá à kò le déèdé sọ pé a fẹ́ kúrò - Àgbààgbà Yorùbá
- "Seyi Makinde ló ṣàtìlẹyìn ètò ààbò fún ìwọ́de Oduduwa Nation"
- Àìgbọ́ra ẹni yé ẹ̀yà Yoruba ló ń ṣe ìdíwọ́ fún òmìnira wa - Àkójọpọ̀ ẹgbẹ́ Yoruba l'àgbáyé
- A ò pe Sunday Igboho lọ́mọ alè Yorùbá o àmọ́, a ó jọ́ bèrè lọ́wọ́ Alálẹ̀ Ibadan àti gbogbo Yorùbá ni - Olubadan





















