Sunday Igboho: Farounbi ní Igboho kò ní gbòǹgbò ìpìlẹ tó fi ń jà, àmọ Kanu àti Dokubo ni

Oniruuru ẹgbẹ ajijagbara lo wa ni ẹkun kọọkan lorilẹede Naijiria, ti wọn n ja fun alaafia, irọrun ati igbayegbadun ẹkun ti wọn ti wa.
Lara wọn la ti ri ikọ ajijagbara MEND, IPOB, MASSOB, OPC ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn n wa idẹrun agbegbe wọn.
Ohun kan soso tawọn ikọ ajijagbara naa si n ja fun ni ibaradọgba nidi pinpin ohun alumọọni ilẹ yii laarin awọn ẹkun to wa ni Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- O kéré sí Number! 'Àwa ológún ò fi ara wa wọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti máa ṣe alamí lórí irú ẹ Sunday Igboho'
- Ọwọ́ Sunday Igboho tẹ ‘Sọ́jà’ àti aráàlú mẹ́rin tó ní wọn ń dọdẹ òun
- Agbébọn pa èèyàn 13, ṣun ile 56, ọkadà 16 ní Kaduna
- Gani Adams àti Seyi Makinde ṣèpàdé, àbọ̀ wọn rèé
- Ẹyọ kan lára agbára tí mo ní, ni mo lò láti mú Wakili - Gani Adams
- Sunday Igboho ṣẹ̀ sí òfin ète ìdìtẹ̀ gbàjọba, ó sì le fojú winá òfin - Amofin
- Bí ọlọ́pàá bá tó bẹ́ẹ̀, kó dá wa lọ́nà, Yoruba kìí ṣe ara Naijiria mọ́ - Sunday Igboho
- Ẹ gbọ́ ná, kí ló lè mú kí àfín 114 di àwátì?
- Afurasí olóṣèlú tí ọlọ́pàá mú lórí ikú ọmọ mi, ló jẹ́ alátakò rẹ̀ nínú PDP - Baba Aborode
- Jimoh Odutola, akọni oníṣòwò tí kò kàwé, àmọ́ táwọn Ààrẹ orílẹ̀-èdè ń ké sí láti wá dá iléesẹ́
- Akẹ́kọ̀ọ́ kò yọjú sílé ẹ̀kọ́ lẹ́yìn tí àwọn olùkọ́ padà sẹnu iṣẹ́ nílèèwẹ tí rògbòdìyàn Hijab ti wáyé n'Ilorin
Ni ẹkun ariwa Naijiria, ẹgbẹ Arewa wa to n gbẹnu sọrọ fun ẹkun naa, amọ ko fi bẹẹ si ikọ ajijagbara to n ja fun irọrun wọn.

Oríṣun àwòrán, Asari Dokubo
MEND:
Ẹgbẹ apapọ awọn eeyan agbegbe Niger-Delta, MENd, lo n pariwo fun idẹrun awọn eeyan agbegbe naa.
Lara awọn adari wọn ni Asari Dokubo, ẹni to fi Naijiria logbologbo lasiko kan, to si n fọ awọn ọpa epo rọbi tii se orisun ọrọ aje wa.
Eredi ijijagbara rẹ ni pe agbegbe Niger Delta ti oun ti wa ni epo rọbi ti Naijiria n ta sodo si julọ, to si n mu owo wa fun orilẹede yii.
Sugbọn o ni o se ni laanu pe agbegbe naa ni isẹ, iya ati osi ti n bawọn finra julọ, tijọba ko si pese awọn ohun eelo amayedẹrun to yẹ nibẹ, amọ ti awọn ẹkun yoku n gbadun owo epo to n wa lati ọdọ awọn.
Amọ lẹyin o rẹyin ni ijọba apapọ joko se ipade pẹlu wọn, o n fun awọn ajijagbara naa ni owo iranwọ losoosu, to si ran ọpọ wọn ni ile ẹkọ labẹle ati ni oke okun.
Amọ laipẹ yii ni Asari Dokubo tun jade sita lati kede pe agbegbe Niger Delta ti darapọ mọ orilẹede Biafra, ti awọn si ti yapa kuro nilẹ wa Naijiri.

Oríṣun àwòrán, Nnamdi Kanu
IPOB:
Nnamdi Kanu lo da ẹgbẹ IPOB silẹ, afojusun rẹ si ni lati ya agbegbe ila oorun ariwa kuro lara orilẹede Naijiria.
Kanu yii lo kede lakoko kan pe orilẹede Naijiria ti yapa kuro ni Naijiria amọ awọn agbofinro lọ si ẹkun naa lati lọ tako igbesẹ yii.
Koda, ẹgbẹ IPOB ti se asia, orin ibilẹ ati owo kọrẹnsi ti wọn yoo maa na ni orilẹede Biafra tuntun to ni oun da silẹ, to si tun ni awọn ọmọ ogun pẹlu.

SUNDAY IGBOHO:
Ajijagbara fun ilẹ Yoruba ni wọn n pe Sunday Igboho, laipẹ yii si lo bọ sita lati tako bi awọn afurasi ọdaran Fulani se n pa awọn ẹya Yoruba.
Atako yii lo mu ko kede ni ọjọ kejidinlogun osu kẹta ọdun 2021 pe ilẹ Yoruba to wa lẹkun iwọ oorun guusu kii se ara Naijiria mọ.
Ikede rẹ yii lo ti n fa awuyewuye yika orilẹede Naijiria, idi si ree ti BBC Yoruba fi se iyatọ ati afiwe to wa laarin awọn ajijagbara mẹtẹẹta yii.
Kí ni ìyàtọ ati afiwe tó wà láàrin Sunday Igboho, Nnamdi Kanu àti Asari Dokubo?
Sunday Igboho ko ni gbongbo ẹgbẹ ajijagbara ti yoo lewaju rẹ lati ja amọ Kanu ni IPOB ti Dokubo si ni MEND
Nigba to n sọrọ lori eleyi, Ọmọwe Yemi Farounbi tii se asoju tẹlẹ fun ilẹ Naijiria si orilẹede Phillipines sọ pe iya to n jẹ awọn eeyan wọn lo n ta awọn eeyan naa lara.
Amọ o ni Nnamdi Kanu ati asari Dokubo ni wọn ni pepele tabi ipilẹ ti wọn fi n ja pẹlu ijsba, eyi ta le pe ni ẹgbẹ ajijagbara amọ Sunday Igboho ko ni.
O fikun pe awọn eeyan agbegbe Niger Delta ri Dokubo bii asaaju wọn, ti ẹya Igbo naa si ri Kanu bii olori ikọ ajijagbara wọn sugbọn Igboho ko ni ẹgbẹ to fi n jija gbara, debi pe wọn yoo mọ ni asaaju.
"Aṣiwaju awọn eeyan agbegbe Niger Delta ni Asari Dokubo jẹ, ṣugbọn emi o ro pe Sunday Igboho ti de iru ipo bẹẹ nilẹ Yoruba.
"Lootọ ni Igboho ṣe gudugudu meje lati daabo bo awọn ara ilu Ibarapa, ṣugbọn pe o ti di alakoso fun Yoruba gẹgẹ bii Asari ṣe jẹ fun ẹgbẹ MEND nigbayẹn, ati Kanu fun ẹgbẹ IPOB, Igboho ko tii de iru ipo bẹẹ."
Farounbi ni o ṣoro lati fi ohun ti Sunday Igboho n ṣe we ohun ti Asari Dokubo n ṣe, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan Dokubo naa ti sọ pe awọn ko ran ni iṣẹ lati ko wọn mọ ilẹ Biafra.
Farounbi ṣalaye siwaju pe, Nnamdi kanu ti ni gbongbo to duro le pẹlu awọn eeyan rẹ, bẹẹ naa ni Asari Dokubo, ṣugbọn Sunday Igboho ko ni irufẹ gbongbo bẹẹ.
"Ikọ wo Sunday Igboho yoo ni ohun n ja fun? Abi awọn wo gan lo ran nisẹ pe ko lọ ko ẹya Yoruba kuro ni Naijiria? Se APC ni abi PDP, Afenifere ni abi ẹgbẹ agbaagba Yoruba?"
Kanu gbọ eebo lati ja fun iran rẹ amọ Igboho ko le sọ gẹẹsi dan mọran:
Yatọ si eyi, awọn ọmọ Yoruba kan lo ti woye pe Nnamdi Kanu lo ka iwe, to si le soju iran rẹ niwaju awujọ agbaye pẹ́lu ede oyinbo to yanranti, amọ̀ Sunday Igboho ko kawe, ti ko si le sọ̀ Gẹẹsi to nnkan.
Awọn eeyan yi lo wa n beere pe se iru ẹni ti eebo rẹ ko kunju iwọn yii ni yoo gbẹnu iran Yoruba sọrọ, ti rogbodiyan to n se ba de oju ọgbagade.
Aya ati ọmọ Kanu, Dokubo ati Igboho ko si ni Naijiria:
Afiwe mii ti awọn eeyan tun se akiyesi nipa awọn ajijagbara yii ni pe mọlẹbi awọn mẹtẹẹta ko si ni orilẹede Naijiria tabi gbe ni ẹkun wọn ti wọn n ja fun.
Nnamdi Kanu ni aya ati ọmọ rẹ wa loke okun, Asari Dokubo ni awọ̀n okoowo ati ẹbi rẹ wa ni ilẹ olominira Benin to mule ti wa nigba ti awọn ọmọ ati aya Sunday Igboho naa wa lorilẹede Amẹrika.
Sunday Igboho ṣẹ̀ sí òfin ète ìdìtẹ̀ gbàjọba, ó sì le fojú winá òfin - Amofin

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho
Amofin kan lorilẹede Naijiria ti fi oju ofin wo ikede ti Sunday Igboho se ni Ọjọru, nibi to ti ni ẹkun iwọ oorun kii se ara orilẹede Naijiria mọ.
Amofin Stephen Ajibola James, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe ta ba fi oju ofin wo o, ete lati ja ijọba gba ni ikede ti Igboho se ọhun.
James ni Igboho ko ni agbara lati kede pe apa ibikan ti yapa kuro lorilẹede Naijiria, ikede rẹ yii si lo wa lati mu ki awọn ọmọ Naijiria ni ikunsinu si ara wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Afurasí olóṣèlú tí ọlọ́pàá mú lórí ikú ọmọ mi, ló jẹ́ alátakò rẹ̀ nínú PDP - Baba Aborode
- Jimoh Odutola, akọni oníṣòwò tí kò kàwé, àmọ́ táwọn Ààrẹ orílẹ̀-èdè ń ké sí láti wá dá iléesẹ́
- Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Samia Suluhu Hassan tó di aarẹ Tanzania lẹ́yìn ikú Magufuli
- Ọ́lọ́pàá gbé èèkàn PDP l‘Oyo lọ ileẹjọ́ lórí ikú Fatai Aborode
- Bí ọlọ́pàá bá tó bẹ́ẹ̀, kó dá wa lọ́nà, Yoruba kìí ṣe ara Naijiria mọ́ - Sunday Igboho
- Ẹ ràgà bo àwọn igbó ọba yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn àti ajínigbé - Ìjọba àpapọ̀
- Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Samia Suluhu Hassan tó di aarẹ Tanzania lẹ́yìn ikú Magufuli
- Olùkọ́ tí kò bá yọjú sí kíláàsì láwọn iléẹ̀kọ́ tí ìjà tí ń wáyé rugi oyin - Ìjọba Kwara
"Ile igbimọ asofin apapọ nikan lo ni agbara lati kede iyapa agbegbe kan lẹyin tawọn ọmọ Naijiria ba ti dibo pe awọn fara mọ pe ki ẹya kan yapa kuro lara Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho
Bi wọn ti se ree lasiko ti orilẹede Cameroon fẹ yapa kuro lorilẹede Naijiria, bakan naa lasiko ti agbegbe Bakassi naa fẹ kuro, awọn eeyan si sọ ohun ti wọn fẹ.
Eeyan kan ko le dede wa jade lati kede iyapa agbegbe kan lai jẹ pe onitọun jẹ asofin, Sunday Igboho kan sọ tiẹ lasan ni, ọrọ rẹ ko ni itumọ kankan, sajẹ lasan ni."
Amofin James tẹsiwaju pe, gbogbo nnkan lo ni eto lati tẹle nitori awọn nnkan kan lo so gbogbo ẹkun to wa ni Naijiria papọ, kii se ọrọ ẹnu la fi se, ọrọ ẹnu lasan ko si le ya wa.
Ki ni ki ijọba se lori ikede ti Sunday Igboho se?
Amofin James salaye pe, Sunday Igboho ti sẹ si ofin ete lati ditẹ gbajọba, ẹsẹ nla si ni labẹ ofin, ijọba si le gbe lati jẹjọ.
Bakan naa, Igboho tun dete lati mase jẹ ki inu awọn ọmọ Naijiria dun si ijọba to wa nita nitori iru ikede to se , ẹnu rẹ ko gba a.
"Ma a rọ ijọba lati maa wo Igboho niran, ki wọn ma si gbe si ahamọ rara lọna ati dena akọtun rogbodiyan to le fẹ tidi gbigbe rẹ yọ nilẹ Yoruba.
Ki ijọba sa ri ihalẹ Sunday Igboho bii ẹni to n pala sẹnu, ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kanun, nitori ti wọn ba gbe, wọn yoo kan jẹ ko dabi akọni ajijagbara ni."
Yorùbá kò fún Sunday Igboho láṣẹ láti dá orílẹ̀èdè Oodua sílẹ̀ - Yemi Farounbi

Awọn agbaagba kan nilẹ Yoruba kan ti n fi erongba wọn han lori ikede ti Oloye Sunday Igboho se pe ilẹ Yoruba ko si lara Naijiria mọ.
Bakan naa ni Igboho tun kede pe akoko ti to ki ẹya Yoruba da wa gẹgẹ bii orilẹ-ede to ti gba ominira, eyi to ti n da awuyewuye silẹ yika apapọ orilẹede Naijiria.
Lara awọn eeyan to woye igbesẹ ti Igboho gbe yii ni aṣoju tẹlẹ fun Naijiria ni orilẹede Philipines, Ọmọwe Yemi Farounbi.
- Bí ọlọ́pàá bá tó bẹ́ẹ̀, kó dá wa lọ́nà, Yoruba kìí ṣe ara Naijiria mọ́ - Sunday Igboho
- Ẹyọ kan lára agbára tí mo ní, ni mo lò láti mú Wakili - Gani Adams
- Òpùrọ́ ló pọ̀ nínú àwọn oníṣẹ̀ṣe, olóòtọ́ọ́ wọn ṣọ̀wọ́n - Olugbon
- Ẹ lo Amotekun, OPC, Fijilanté àti ọ̀dẹ ìbílẹ̀ fétò ààbò - Ọba Tejuosho
- N kò ní baba ìsàlẹ̀ nínú òṣèlú, Ọ́lọ́run nìkan ni mo bẹ̀rù - Seyi Makinde
- Wo ewu tó rọ̀ ma kí wọn sin ọba tó ṣètùtù nílànà ẹ̀sìn Krìsítẹ́nì àti Islam
Farounbi ni erongba Sunday Igboho lasan lo fi lede nitori ko si ibi ti gbogbo Yoruba ti jokoo lati yan ẹnikẹni pe ko lọ da orilẹede Oduduwa silẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ki ẹya kan to le yapa lati da orilẹede tiwọn silẹ, oriṣiriṣi ipade ni yoo waye, pẹlu ijiroro lori bi wọn ṣe le da orilẹede naa silẹ pẹlu ifọwọsowọpọ ajọ agbaye, UN.
O ni "lootọ inu Yoruba bajẹ si ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria, ko si igba kankan ti awọn agba joko Yoruba lati yan ẹnikẹni lati ṣoju wọn nipa dida orilẹ-ede tuntun silẹ."
"Ara lasan lo n ta Sunday Igboho nipa bi orilẹede Naijiria se bajẹ to, ṣugbọn emi o ro pe bi ara ṣe n ta eeyan lo yẹ ko gbe ọrọ naa kalẹ, o yẹ ko fi suuru mu ẹkọ gbigbona.
Bi eeyan ba si fi ẹkọ gbigbona, ahọn rẹ ni yoo jo, abi se a ti ni olori fun orilẹede Oduduwa ti wọn n polongo ni? Se wọn ti ni eto aabo fun ilu naa ni?
Se wọn ti ni ilana fun eto ijọba awa ara wa fun orilẹede Oduduwa ni? Awọn igbesẹ kan maa n wa ki eeyan to se iru nnkan bẹyẹn."
O fikun pe, ọrọ ilẹ yii gbọdọ kọkọ dun gbogbo wa bakan naa, ka jọ fẹnu ko bakan naa, ka le mọ igbesẹ ta jọ gbe bakan naa, Igboho ko ba se suuru ki gbogbo wa jọ fẹnu ko na lori yiyapa kuro ni Naijiria.























