Samia Suluhu Hassan: Ikú ààrẹ Magufuli sọ igbákejì rẹ̀ di ààrẹ obìnrin àkọ́kọ́ ní orílẹ̀èdè náà

Oríṣun àwòrán, AFP
Irọlẹ Ọjọbọ ni isẹ kan Samia Suluhu Hassan, lati tufọ iku aarẹ orilẹ-ede Tanzania, John Magufuli, gẹgẹ bi igbakeji rẹ.
Ni bayii, o ti gba ipo Magufuli gẹgẹ bi aarẹ.
Ọdun 2015 ni wọn kọkọ dibo yan an sipo igbakeji fun Aarẹ Magufuli, wọn si tun jọ wọle fun saa keji lọdun 2020.
Gẹgẹ bi òfin orilẹ-ede Tanzania ṣe laa kalẹ, oun ni yoo pari saa ọlọdun marun naa.
Oun nikan si ni yoo jẹ adari to jẹ obìnrin nilẹ Africa, lọwọlọwọ.
Mama Samia ni wọn ma n pe ẹni ọdun mọkanlelọgọta ọhun - ninu àṣà orilẹ-ede Tanzania, eyi tumọ si pe ẹni ọ̀wọ̀, ti wọn n pọnle ni, kii ṣe pe wọn n fi oju kéré rẹ gẹgẹ bi obìnrin.
Iyalẹnu ni iyansipo rẹ lati dije pẹlu Magufuli jẹ ni ọdun 2015, nitori pe ọpọlọpọ awọn àgbà oloṣelu lo wa ninu ẹgbẹ oṣelu Chama Cha Mapinduzi (CCM), to ti wa ni ipo isakoso lati ọdun 1961.
Ọdun 2000 ni wọn kọkọ yan si ipo àṣẹ, sugbọn lọdun 2014, o di ilumọọka kaakiri orilẹ-ede Tanzania, nigba to di igbakeji alaga igbimọ aṣofin to kọ ofin tuntun.
Ọna to ma n gba mojuto rogbodiyan to ba waye ninu igbimọ, ati ibawi to ma n fun awọn ọmọ igbimọ to ma n sọrọ dáadáa, mu ki o gbayi pupọ.
Iyatọ pupọ lo wa laarin iru eeyan to jẹ, ati ti ọga rẹ, Aarẹ Magufuli.

Oríṣun àwòrán, AFP
Bi Magufuli ṣe jẹ ẹni ti ko gba gbẹrẹ, ti kii si tiju ẹnikẹni, tabi sọ ìhà to ba kọ si nkan, ara Samia balẹ̀ pupọ, o si má n ro arojinlẹ daada.
Bakan naa lo tun jẹ eleti gbaroye, to si ni igbagbọ ninu sise nkan ni ilana to yẹ.
'Adari to kaju ẹ ni'
Ọmọ ile aṣofin kan, January Makamba, to ba a ṣíṣẹ ri ni ọfiisi Igbakeji Aarẹ, ti sọ ri pe "Samia ni oloṣelu ti wọn fi oju di julọ ni Tanzania".
O ni "mo ti sakiyesi bo ṣe n sisẹ, bo ṣe ma n gbe igbesẹ ati ìpamọ́ra rẹ daadaa. O koju oṣuwọn lati jẹ adari".
Sugbọn gbogbo amuyẹ yii ko ti i safihan bi yoo ṣe le ṣe ilana ìṣàkóso. Eyi to ṣe koko ni pe boya yoo tẹsiwaju pẹlu ọwọ yẹpẹrẹ ti asiwaju rẹ fi mu ọrọ coronavirus.



















