John Magufuli: Àwọn ǹkan ti aarẹ Magufuli fi yàtò si awọn ààrẹ Afíríkà tó kù

Oríṣun àwòrán, AFP
Aarẹ orilẹede Tanzania to di oloogbe, John Magufuli lo de koto nla lọjọ kẹrinlelogun, osu keji ọdun yii nibi to ti n ṣe ayẹyẹ ṣiṣi oju popo tuntun ni Darsalaam, to si fi n yangan pe ẹgbẹ oselu to n bẹ lode CCM nikan lo le se iru nkan nila bẹẹ.
" Lọgan ni a pari opopona naa nitori ko si ẹni to n fi ọrọ Coronavirus kẹwọ lati fi iṣẹ wọlẹ," O sọ eyi lasiko to n to gboriyin fawọn kọngila to se oju popo naa nibi ifilọlẹ to ṣe, bakan naa lo kilọ f'awọn oṣiṣẹ ijọba lati ma gba ẹnikẹni laaye lati fi ọrọ ajakalẹ aarun Covid-19 kẹwọ lẹnu iṣẹ ijọba tabi ninu iṣẹ ode.
"Orilẹede to ni ọla ati ọrọ ni Tanzania a si gbọdọ lo lati mu idagbasoke ba orilede yii" Bakan naalo tun bu énu atẹ luawọn ti kii san owo ori wọn deede, lẹyin ọjọ mẹta wọn ko mọ pe igba ikẹyin ti wọn yoo ri aarẹ ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Òpùrọ́ ló pọ̀ nínú àwọn oníṣẹ̀ṣe, olóòtọ́ọ́ wọn ṣọ̀wọ́n - Olugbon
- N kò ní baba ìsàlẹ̀ nínú òṣèlú, Ọ́lọ́run nìkan ni mo bẹ̀rù - Seyi Makinde
- A ń lọ ṣí ẹnu bodè Yorùbá tíjọba tìpa sílẹ̀, kí oúnjẹ wọlé nírọ̀rùn - Sunday Igboho
- Ẹyọ kan lára agbára tí mo ní, ni mo lò láti mú Wakili - Gani Adams
- A kọ òrìṣà babańlá wa sílẹ̀ ló jẹ́ kí ọ̀daràn darandaran máa pa wá bí ẹ̀fọn - Àwọn Oníṣẹ̀ṣe
- Ìtàn ayé John Magufuli, Ààrẹ Tanzania tọ́pọ̀ èèyàn ń pè ní 'bulldozer'
- Wo ohun tí o kò mọ̀ nípa Ààrẹ Tanzania, John Magufuli tó jáde láyé
- Wo ewu tó rọ̀ ma kí wọn sin ọba tó ṣètùtù nílànà ẹ̀sìn Krìsítẹ́nì àti Islam
Lati asiko ti aarẹ Magufuli ti di aarẹ lọdun 2015 lo ti maa huwa ko kan mi ti kii si fi ti ẹnikẹni ṣe , eyi yatọ gedegede si bi aarẹ to kuro lori oye se maa n ṣe.
Awọn ololufẹ rẹ maa n pe ni adari to moye, eyi si tun jẹ ki ọpọ nifẹ pupa ni orilede Tanzania ati lawọn ilẹ okere, to fi ma àwọn ila-oorun ilẹ Afirikanibi ti wọn ti ma n daṣa pẹlu #WhatWouldMagufuliDo loju opo twitter, ti wọn si maa n gboriyin fun ìwá aigboregbe rẹ, ọna to n gba gbogun ti iwa ajẹbanu ati bi o se maa n moju to awọn ise ode amayedẹrun fun ara ilu titi awọn kọgila yoo fi pari rẹ.
Nkan ti ọpọ awọn eniyan Tanzania fẹran rẹ fun ni pe, o maa n moju to iṣẹ idagbasoke ati ilọsiwaju ti ijọba ba n ṣe, eyi ni wọn sọ pe, o yẹ ki awọn adari orilede ilẹ Afirika maa wo awokọṣe rẹ.
O jẹ ẹni ti awọn eniyan fẹran
Ọpọ awọn ololufẹ rẹ ko ni gbagbe rẹ fun awọn irinajo oju popo ati bi o se maa n duro ki awọn eniyan ti yoo si ba wọn sọrọ ni gbangba ita.
Ni ọpọ igba ni o maa n se awọ eto yii lo amohunmaworan, eyi si lo mu ki ọpọ ri gẹgẹ bi adari ti awọn le ba sọrọ ti isoro awọn yoo si yanju loju ẹsẹ.
Ni ọpọ igba ni awọn eniyan maa n pejọ si ẹgbẹ moto rẹ lasiko to ba duro lawọnb ilu lẹba ọna
Ọpọ awọn to ba pinu lati ba sọrọ pẹlu maa n ri ba sọrọ lasiko naa, ọpọ yoo rawọ ẹbẹ si lori isoro wọn, yala fun oju popo, iṣẹ akanṣe agbegbe wọn ti ko pari lasiko , tabi eto idajọ ti wọn ko pari, ọrọ omi tabi ikusinu ti wan ba ni si oloṣelu kan.

Oríṣun àwòrán, AFP
Lasiko kan, Magufulia maa rin ninu oorun ti yoo si mu ẹrọ agbohun dani lati tẹti ati dahun si ibere awọn ara ilu.
Ní ọpọ igba, awọn idahun rẹ maa n jẹ bakan meji sugbọn, nigba ti yoo ba pari ọrọ rẹ awọn ofin tuntu miran ni wọn yoo tun ti ri nibẹ, igba miran ẹwẹ, eyi yoo gba iṣẹ lọwọ ẹnikan tabi ki o fun ẹlomiran ni igbega, nigba miran si ni yoo doju ti ẹni to ba beere igbeere naa.
Lọjọ kan ni Magufuli yẹyẹ ọkunrin kan ni Dar salam lasiko to sọ pe o nira gidi o si tun wọn lati lo ile igbọnsẹ igboro,Magufuli da lohun pé " fi igbẹ rẹ kalẹ sinu ile"
Ọpọ awọn alatako rẹ ni apaṣẹ waa ni kii si gbọ ti ẹlomiran mọ tirẹ, kii gba imọran ẹlomiran mọ ti ẹ, bakan naani kii fé ki eniyan ba se awada ko ba jẹ olorin tabi awọn adẹrinposonu.
O fi ibẹru sinu ara ilu, koda laarin oṣẹ meji ti ko farahan lawujọ ko si ẹni to yẹ ijọba rẹ lọwọ wo, koda ọlọpaan mu ẹnikẹni to ba sọrọ pe nibo ni aarẹ Magufuli wa?
Magufuli lo agbara lori ọpọ awọn ile iṣẹ iroyin ti o si ti ọpọ ile iroyin pa, fi mọ radio, tẹlẹfisọn ati ori ayelujara nitori wọn n royin nkan ti ijọba ko fẹ.
Bakan naa ni wọn naka alebu si John Magufuli pe o fi ofin de awọn ọmọbinrin to ba ti loyun lati ma lọ ile iwe mọ.
Sugbọ ọna to gba se ọrọ coronavirus ni o jẹ aṣiṣe to buru julọ
Magufuli to jẹ olukọ imọ kẹmisitri tẹlẹ tun fi igba kan sọ pe awọn oyinbo n gbiyan lati pa awọn eniyan Tanzania lara ni, to si n ṣiye meji lori lio ibomu ati gbigba abẹrẹ Covid-19.
Lasiko kan o fi ibẹpẹ ati ewurẹ ranṣẹ pe ki wọn se ayẹwo boya wọn ni aarun coronavirus lati fi wi awijare pe ko si aarun naa ni Tanzania
Ootọ ibẹ ni pe aibikita lori ọrọ coronavirus ati kukuna lori ojuṣe rẹ jẹ idi fun ọpọ ẹmi to ti sofo.
Se Ijobo Magufuli lo lagbara abi oun tikara rẹ?
Ifọrọwerọ yoo wa ni Tanazania bayii pe boya ẹni to gba ijọba lẹyin rẹ yoo tẹsiwaju ninu awọn iṣesi rẹ tabi yoo ṣe awọn ayipada tuntun.
Ifọrọwerọ naa ko tun ni pari si ibeere pe boya alagbara ni awọn orilede Afrika nilo tabi ijọba to lagbara.
Wọ́n ni aarun ọkan lo pa aarẹ Magufuli, sugbọn ọpọ gbagbọ pe ààrun coronavirus naa dakun.















