John Magufuli: Ààrẹ Tanzania tọ́pọ̀ èèyàn ń pè ní 'Bulldozer'

Aarẹ John Mugufuli

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oloogbe Jonh Mugufuli jẹ ọmọ agbẹ alarojẹ, ati atapata dide to di aarẹ orilẹede rẹ, Tanzania lọdun 2015.

Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan kọkọ gboriyin fun, nitori pe o jẹ adari ti ko gba rẹdẹ-rẹdẹ, o pada di ẹni ti aye ń wa ẹnu si lara, nitori iha to kọ si ọrọ aarun coronavirus.

Ọdun 2020 ni wọn dibo yan an sipo aarẹ fun saa keji, lai fi awọn ẹsun jibiti ati didẹru ba ni ti wọn fi kan ṣe.

Ki John Mugufuli to di aarẹ lo ti gba orúkọ inagijẹ 'Bulldozer' nitori bo ṣe ṣe agbatẹru isẹ akanse atunse oju ọna lasiko to jẹ minisita fun àkànṣe isẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, wọn tun kan saara si nigba naa fun bo ṣe korira iwa ibajẹ ati fifi owo ṣòfò.

Gẹgẹ bi aarẹ, wọn tun fi ẹsun kan pe o gbẹsẹ le ominira ni awọn ipele kan, sugbọn lẹyin iku rẹ bayii, iha aibikita to kọ si ọrọ Covid-19, ni yoo jẹ koko nkan ti wọn o fi ranti isejọba rẹ.

'Èṣù ni Coronavirus'

Nigba ti Covid-19 de si orilẹ-ede Tanzania, Aarẹ Magufuli ko ni igbagbọ ninu pe ki eeyan o joko sile. Ni ṣe lo fẹ ki wọn o lọ si sọọsi ati mọsalasi lati gbadura.

O ni "coronavirus to jẹ èṣù, ko le yè ninu ara Kristi.... kiakia ni yoo jona.

Bayii ni Magufuli, to jẹ ọmọ lẹyin Kristi tootọ ṣe sọ lori pẹpẹ ìjọ kan ni olu ilu orilẹ-ede naa, Dodoma.

Magufuli ni awọn eeyan maa fin agbo lati dena arun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Ericky Boniface/AFP

Lasiko kan, Magufuli polongo awọn ọna iwosan ibilẹ, bi fi fin ooru omi gbigbona si imu, gẹgẹ bi ọna lati gbogun ti Coronavirus.

Lati oṣu Kẹfa, ọdun 2020 si lo ti kede pe ko si coronavirus mọ ni Tanzania.

Koda, ni ṣe ni oun ati awọn to jẹ Ọga lara awọn ọmọ igbimọ rẹ n fi awọn orilẹ-ede to yi wọn ka ṣe ẹlẹya, nitori awọn ofin coronavirus ti wọn ṣe, to fi mọ wiwọ ibomu ati ayẹwo ṣíṣe.

Wọn ko fi bẹ ẹ ṣe ayẹwo ni Tanzania, ko si si eto kankan fun ipese abẹrẹ ajẹsara.

O ṣe ni laanu pe nigba ti wọn bura wọlé fun Magufuli lọdun 2015 gẹgẹ bi aarẹ, ọpọ lo gbagbọ pe iru eeyan bi i rẹ, ti ko gba igbakugba, to tun jẹ olotitọ, ni Tanzania nilo.

'Bulldozer bẹrẹ isẹ'

Awọn igbesẹ rẹ ni ọpọ sapejuwe gẹgẹ bi iru nkan ti Africa nilo.

Ni ọjọ rẹ lẹnu isẹ gẹgẹ bi aarẹ, ikilọ akọkọ to fi sita ni pe oun ko ni i fi aye gba bi awọn oṣiṣẹ ijọba ṣe ma n pa ibi'ṣẹ jẹ, lasiko to bẹ ileesẹ eto inawo wo, to si beere nipa àwọn ti ko wa si ibi'ṣẹ.

Bakan naa lo tun pa ọrọ awọn ẹgbẹ ẹgbẹrun oṣiṣẹ ti ko si i, sugbọn ti wọn n gba owo oṣu, run.

O si gba isẹ lọwọ àwọn Ọga to jẹ oniwa ibajẹ, tabi ti ko ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ ni gbangba. Nigba miran, ori amohunmaworan lo ti ma n da wọn duro.

John Magufuli

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O fi opin si awọn nkan to ri bii inakuna, o tun wọgile ayẹyẹ ọjọ ominira, fun igba akọkọ lati ọdun mẹrinlelaadọta. Dipo bẹ ẹ, o kede eto kiko idọti laarin ilu, oun paapa ko idọti nile ijọba.

O tun fi ofin de irinajo silẹ okeere laarin awọn olori ijọba.

Bi awọn kan ṣe n fi awọn ilana isejọba rẹ ṣe yẹ yẹ, ni awọn mii n kan saara si pe ki awọn adari yooku ni Africa fi ṣe awokọse.

Amin iyasọtọ kan

Itan igbeaye Magufuli ni ranpẹ

Ilu Chato, ni agbegbe Iwọ oorun Tanzania ni wọn ti bi, ni ọdun 1959.

  • O kekọọ nipa Kẹmisiri ati ìṣirò ni Fasiti Dar es Salam
  • O sisẹ gẹgẹ bi olukọ Kẹmisiri ati ìṣirò
  • Ọdun 1995 ni wọn kọkọ dibo yan si ile aṣofin
  • O di minisita ni ọdun 2000
  • O wọle saa akọkọ si ipo aarẹ lọdun 2015
  • O wọle fun saa keji lọdun 2020
Amin iyasọtọ kan

Ni oṣu Kinni, ọdun 2016, lẹyin asiko diẹ to de isakoso, o kede pe ko ni i si afihan ijiroro àwọn aṣofin mọ lori amohunmaworan, gẹgẹ bi ọna lati sọwo naa.

Sugbọn, àwọn ọmọ ẹgbẹ alatako ri gẹgẹ bi ọna lati pa wọn lẹ́nu mọ, nitori pe ara ọna ti wọn fi n tọ pinpin ijọba niyẹn.

Wọn gbeero lati ṣe iwọde, àmọ́ fifi ofin de iwọde ni ijọba fi da wọn lohun.

Àpẹẹrẹ mii tun ni igbesẹ Magufuli si orin kan ti gbajugbaja akọrin takasufe ni Tanzania, Nay wa Mitego kọ lọdun 2017.

Ko pe ọjọ kan to gbe orin naa jade, ti Mitego fi ba ara rẹ ni agọ ọlọpaa.

Wọn fi ẹsun kan pe o bu aarẹ, to si tun fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ijọba, nipasẹ orin naa.

Orin naa niise pẹlu ominira ọrọ sísọ, o tun sọ ninu rẹ pe awọn olori to n gbe igbesẹ omugọ wà.

John Magufuli n dibo

Koda, o tun kọrin pe ti oun ba ba ara oun ni atimọle ọlọpaa nitori pe oun sọrọ nkọ?

Bẹẹ gan-an ni ọrọ ri fun.

Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Magufuli pàṣẹ itusilẹ rẹ lẹyin ọjọ kan, o kilọ fun pe ko tun ọrọ inu orin naa kọ, nipa awọn ìṣòro mii, bi aisan owo ori, to wa ni awujọ.

Ni ọdun 2017, alatako, Asofin Tundu Lissu, to dije tako Magufuli fun ipo aarẹ ni 2020,fi ara gba ọgbẹ́ lasiko ti awọn kan yinbọn mọ ni iwaju ile ara rẹ.

Ọgbẹni Lissu fi ẹsun kan ijọba pe o fẹ ẹ pa oun, ni wọn ba tun gbe lọ sile ẹjọ pe o pe aarẹ ni apasẹ wàá. Àmọ́, ijọba sọ pe oun ko lọwọ ninu ikọlu naa.

Magufuli tun fi ofin de awọn iwe iroyin, igbesẹ eyi ti awọn ajafẹtọ pe ni gbígbé ẹsẹ le ominira àwọn oniroyin.

Owo ori gọbọi

Lara awọn igbesẹ akikanju ti isejọba Magufuli tun gbe ni ṣíṣe ofin ti yoo mu ki owo wọlé si i fun ijọba lati ara àwọn ileesẹ ilẹ okeere to n wa kusa.

Lọdun 2017, gbese owo ori, $190bn, ni ijọba sọ pe ileesẹ to n wa kusa, Acasia Mining, to jẹ ẹka ileesẹ kan ni Canada, Barrick Gold, jẹ oun.

Àmọ́ ileesẹ naa sọ pe oun ko jẹbi.

Lara ọna ti wọn gba yanju ọrọ naa ni pe ileesẹ Barrick gba lati san $300m, lẹyin to ra ileesẹ Acasia. Wọn da ileesẹ mii silẹ, Twiga Minerals, ijọba si ni ìdá mẹrindinlogun lara rẹ.

Bakan naa ni Barrick ati ijọba fi ẹnu kò lati ma a pin ere ori awọn ibudo iwakusa naa lọjọ iwaju, ni dọgba.

John Magufuli laarin ero

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nkan pataki miran ti Magufuli tun ṣe ni igbiyanju rẹ lati gbẹsẹ le ofin to ni kí wọn o ma a le awọn akẹkọọbinrin to ba loyun kuro nileewe.

Ni ọdun 2018, Tanzania ṣe ofin pe ẹnikẹni ko gbọdọ beere ìbéèrè lori akọsilẹ ti ijọba ba fi sita.

Sugbọn ṣa, awọn alatako rẹ gan-an gbà pe Magufuli kopa ninu idagbasoke Tanzania, pe o tun ṣe awọn àkànṣe isẹ nla bi i ṣíṣe oju ọna ọkọ reluwe igbalode lati so Tanzania pọ mọ àwọn orilẹ-ede to yi i ka, fifẹ àwọn ojupopo nla, ati eto irinna irọrun nilu Dar es Salam.

O tun ṣe àfikún ipese ina ọba, o si tun gbe ileesẹ ọkọ ofurufu orilẹ-ede naa, Air Tanzania, dide pada.

Awokọse aarẹ akọkọ ni Tanzania, Mwalimu Julius Nyerere ni Magufuli fi ijọba rẹ ṣe. Nyerere kii bẹru, bẹẹni ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu isakoso.

Eyi gan-an lo da bii pe o fa ìhà ti Magufuli fi mu ọrọ coronavirus.

O ni " baba nla wa kii ṣe ẹni ti ẹnikẹ́ni n pasẹ fun tabi sọ nkan ti yoo ṣe fun.... Àwọn to ṣe ofin isede coronavirus jẹ ẹni to ma n pa iru awọn àṣẹ ti baba nla wa tako.

O sọ eyi nipa bi Nyerere ṣe ma n kọ imọran lati ọdọ awọn orilẹ-ede aláwọ̀ funfun, nitori pe ko fi inu tán wọn.

'Mo mọ nkan ti ipo talaka jẹ'

Lọdun 2015, lasiko ipolongo ibo fun ipo aarẹ, Magufuli sọ pe oun mọ itumọ ki eeyan o jẹ talaka.

Asiko isejọba Nyerere ni Magufuli n dagba, nilu Chato.

O ni wiwa ti oun wa lati idile talaka lo jẹ iwuri fun oun, lati sisẹ fun awọn ọmọ orilẹ-ede Tanzania.

O si seleri pe oun yoo sisẹ karakara fun idagbasoke igbeaye irọrun fun awọn araalu.

O sisẹ diẹ gẹgẹ bi olukọ Kẹmisiri ati ìṣirò, lẹyin to kuro nileewe girama, ko to o tẹsiwaju lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ.

Awọn ololufẹ Magufuli

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fun ọdun diẹ, o sisẹ gẹgẹ bi onimọ Kẹmisiri, Industrial Chemist, ko to o kọwe fi isẹ silẹ, lati dije fun ipo aṣofin ni ẹkùn Chato.

Kiakia lo de ipo igbakeji minisita, nitori iwa 'ijafafa, afojusun, ati aigba igbakugba'.

Nigba ti yoo fi di ọdun 2015, Magufuli ti n gbero lati fi aarẹ. Iroyin sọ pe ẹgbẹ Chama Cha Maoinduzi (CCM) gan-an lo fa kalẹ. Ẹgbẹ naa lo ti wa ni ipo isakoso fun ọdun mẹrinlelaadọta.

Eto idibo ọdun naa lo lagbara julọ ninu itan orilẹ-ede Tanzania, sugbọn Magufuli bori ìdá mejidinlọgọta.

O wọle saa keji pẹlu idà mẹrinlelọgọrin. Àmọ́ ẹgbẹ alatako sọ pe esi ibo naa ni mago-mago ninu.

Ipolongo pe ki awọn adari yooku ni Africa wo awokọse rẹ dinku, nigba ti awọn ẹgbẹ oṣelu alatako, ẹgbẹ araalu ati awọn orilẹ-ede aláwọ̀ funfun bẹrẹ si ni bu ẹnu ẹtẹ lu, nitori pe 'o n fiya jẹ awọn alatako, o gbẹsẹ le ominira àwọn oniroyin, o tun fi ọwọ lile ati amojuto mu àwọn ileesẹ ilẹ okeere'.

Sugbọn, gbogbo nkan yii ko ni ipa kankan lára Magufuli, to ma n gbe ara rẹ bi ọrẹ araalu ni Africa, ọmọ ijọ Aguda to ni ìfọkànsìn, to si n gbogun ti awọn orilẹ-ede ilẹ okeere to fẹ jẹ orilẹ-ede Tanzania run.

O si ṣe e ṣe ko jẹ eyi lo fa ihuwasi rẹ si amojuto itankalẹ coronavirus.

Iwa si ni yoo sọ oju ti wọn o fi ma a wo Magufuli titi lai.