Astrazeneca Vaccine: Ìjọba Osun àti Ogun fi orúkọ ibùdo ìlera fún gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára pamọ́

Oríṣun àwòrán, Nigerian Government
Lẹyin ti ijọba apapọ tẹwọ gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti AstraZeneca ṣe, labẹ eto Covax, wọn ti pin abẹrẹ ọhun kaakiri awọn ipinlẹ Naijiria.
Gẹgẹ bi eto naa ṣe lọ, awọn oṣiṣẹ eto ilera atawọn alaisan Covid-19 ni yoo kọkọ gba abẹrẹ naa, ko to kan awọn eeyan ilu miran.
Ṣaaju ni Aarẹ Muhammadu ti gba abẹrẹ tirẹ loju awọn ọmọ Naijiria, lati fi ọkan wọn balẹ pe ko si ewu ninu gbigba abẹrẹ ajẹsara ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- CCTV yọ Barry Jhay lórí ikú Kashy, òtítọ̀ ọ̀rọ̀ fojú hàn nígbẹ̀yìn
- Ẹgbẹ́ Òṣùgbó fi tipá gbé òkú Ọba ní Ijebu, mọ̀lẹ́bí fárígá
- El Rufai àtàwọn gómìnà míì ló n tako sísan owó oṣù tó kéré jùlọ - NLC
- Krìsìtẹ́nì àti Mùṣùlùmí ń sọ òkò lura wọn ní Ilorin torí aáwọ̀ lílo Hijab
- Ilé ẹ̀kọ́ 10 tíjọba Kwara tìpa di ṣíṣí padà, akẹ́kọ̀ọ́bìnrin le lo Hijab níbẹ̀
- Boko Haram gboró, ó dáná ṣun ìbùdó ológun, iléẹ̀kọ́ àti ilé ìwòsàn
- Agbébọn pa èèyàn 58 tó ń ti ọjà bọ̀, jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀, fi oúnjẹ ṣòfò
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí márùn ún míràn lórí ikú ọmọ Fasoranti
- Wakili àtàwọn méjì míì dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn, ìjínigbé àti olè kàn wọ́n
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo ti n woye ibi ti wọn ti le gba abẹrẹ naa lagbegbe to sun mọ wọn.

Oríṣun àwòrán, @Reuters
Ipinlẹ Eko
Kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ Eko, Akin Abayomi kede lọjọ Iṣẹgun pe ibudo ilera mejidinlaadọrun un, 88, ni wọn ti le gba abẹrẹ naa l'Eko.
Awọn ibudo naa to gbe soju opo Twitter rẹ ree:
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Lara awọn ile iwosan ti wọn ti le gba abẹrẹ ọhun ni ile iwosan awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun wa.
Ipinlẹ Ogun
Ile iwosan mẹtadinlaadọfa, 107, ni awọjn eeyan ipinlẹ Ogun ti le gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19, ṣugbọn wọn ko tii fi adirẹsi awọn ileewosan naa lede.
Awọn oṣiṣẹ eto ilera nikan ni wọn ṣi n fun labẹrẹ naa lọwọ yii.
Gẹgẹ bii nkan ti kọmiṣọna eto iroyin ipinlẹ naa, dokita Tomi Coker sọ fun BBC Yoruba, wọn yoo jẹ ki awọn eeyan ilu mọ ibi ti wọn ti le gba abẹrẹ naa, ti wọn ba ko abala keji rẹ wọle.
O ni "ko ni bojumu ka fi adirẹsi ibi ti awọn araalu ti le gba abẹrẹ naa sita, ṣugbọn ka má fun wọn nitori awọn oṣiṣẹ eto ilera nikan ni a n fun lọwọ, idi ree ti a ṣe fi orukọ awọn ileewosan naa pamọ lasiko yii."
Coker pari ọrọ rẹ pe, o kere tan, ileewosan marun nun ni awọn eeyan ti le gba abẹrẹ naa nipinlẹ Ogun.
Ipinlẹ Osun
Kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ Osun, Olasunkanmi Isamotu sọ fun BBC Yoruba pe, ileewosan mẹtadinlọgọrun, 97, ni awọn eeyan ti le gba abẹrẹ Covid-19 ni ipinlẹ ọhun.
Ṣugbọn ko si aṣọ loju adirẹsi awọn ile iwosan naa fun BBC Yoruba lasiko yii.













