New Minimum Wage: NLC ní bí àtúntò yóò bá bá owó oṣù òṣìṣẹ́, ọ̀dọ́ gómìnà àti aṣòfin ní yóò ti bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @NLC
Awọn olori ẹgbẹ osisẹ ni Naijiria ti bẹnu atẹ lu awọn to dipo aṣẹ mu lori bi wọn se fẹ sagbekalẹ abadofin kan, ti yoo gbe akoso owo osu to kere julọ ni Naijiria kuro labẹ akoso ijọba apapọ sọdọ awọn ijọba ipinlẹ.
Aarẹ ẹgbẹ osisẹ ni Naijria Ayuba Waaba lo fi ọrọ yii lede lasiko ipade kan pẹlu awọn olori ile asojusofin Naijiria lọjọ Isegun.
Lasiko ipade yii, Waba ni oun to ba da fun Taiye, o di dandan ka le se bẹẹ fun Kehinde naa, tori eyi, ki atunto naa bẹrẹ lati ọdọ awọn asofin ilẹ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- CCTV yọ Barry Jhay lórí ikú Kashy, òtítọ̀ ọ̀rọ̀ fojú hàn nígbẹ̀yìn
- Ẹgbẹ́ Òṣùgbó fi tipá gbé òkú Ọba ní Ijebu, mọ̀lẹ́bí fárígá
- Krìsìtẹ́nì àti Mùṣùlùmí ń sọ òkò lura wọn ní Ilorin torí aáwọ̀ lílo Hijab
- Ilé ẹ̀kọ́ 10 tíjọba Kwara tìpa di ṣíṣí padà, akẹ́kọ̀ọ́bìnrin le lo Hijab níbẹ̀
- Boko Haram gboró, ó dáná ṣun ìbùdó ológun, iléẹ̀kọ́ àti ilé ìwòsàn
- Agbébọn pa èèyàn 58 tó ń ti ọjà bọ̀, jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀, fi oúnjẹ ṣòfò
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí márùn ún míràn lórí ikú ọmọ Fasoranti
- Wakili àtàwọn méjì míì dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn, ìjínigbé àti olè kàn wọ́n
Waaba kọwọrin nibi ipade yii pẹlu awọn olori ẹgbẹ osisẹ mii bi ti Trade Union Congress, ọgbẹni Quadri Olaleye.
O sọ pe: ''A setan lati fẹsẹ ipinu wa rinlẹ. Bi a ba fẹ se atunto owo osu, mo lero pe lọdọ awọn to dipo ijọba mu lo yẹ ko ti bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, @NLC
Nigba ti wọn satunyẹwo owo osu pẹlu ida aadọta lọdun 211, atunto ida ẹgbẹrin ni wọn mu ba owo osu awọn to dipo mu ni ijọba''
''Nitori naa, to ba se pe a n wo boya ijọba ni agbara lati san owo yii, ibi to yẹ ki a ti bẹrẹ niyẹn.
Owo osu to kere julọ la wa n beere fun, to si se wi pe awọn kan ti n gba owo to ga julọ''
Lọwọ-lọwọ bayi, ajọ to n mojuto owo osu awọn Gomina ni ipinlẹ Naijiria ko se ipinya kankan lori owo osu Gomina, lori agbara ati iye owo to n wọle fun wọn.
Gbogbo Gomina patapata, gẹgẹ bi Waaba se salaye, lo n gba iye owo kan naa.
Bẹẹ lo ni ko si iyatọ ninu owo awọn kọmisana ati awọn olori ile asofin.
Fun idi eyi, o ni ki wọn mase jẹ ki awọn ipinlẹ kan maa san owo to kere julọ fun awọn osisẹ, kawọn mii si ma san an rara.
Nibi ipade naa ni olori ile asojusofin Naijiria, Femi Gbajabiamila ati awọn olori ile mii wa, to fi mọ ẹni to sagbekalẹ abadofin yii nile asofin asoju, Garba Datti Muhammad.
Eni to sagbekalẹ abadofin yii ti sọ niwaju ile lọjọ Kẹtalelogun osu Keji pe, ofin naa yoo gba ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ laaye lati dunadura nipa iye owo osu to ba wu wọn ni ibamu pẹlu ominira ti ofin ilẹ yii se fun wọn.
Sugbọn Waba sọ pe lawọn orileede mii to ti goke agba, ijọba apapọ lo si lasẹ lori iye owo osu to kere julọ fawọn osisẹ.
Gbajabiamila, ninu esi lori ọrọ yii ni awọn asofin lẹtọ lati fi abadofin sọwọ sile.
O wa rọ awọn ẹgbẹ osisẹ lati jiroro pẹlu awọn asoju wọn tabi ki wọn wa sọ tọkan wọn nigba ti ile ba pe araalu lati wa da si abadofin naa.
O ni wọn tun le lo anfaani ileesẹ iroyin lati sọ ẹdun ọkan wọn.
O ni ki ile to gbe igbesẹ lori ọrọ yii, awọn yoo sagbeyẹwo rẹ daada lati le buwọlu ofin ti yoo se araalu, paapa awọn osisẹ Naijiria lanfaani.
Ki lo kan El-Rufai ninu ọrọ to wa nilẹ yi?
Awọn ẹgbẹ osisẹ ti fẹsun kan Gomina ipinlẹ Kaduna Nasir El Rufai pe oun ati awọn akẹgbẹ rẹ kan ni igi wọrọkọ to n tako abadofin yii.
Wọn fi ẹsun naa kan ninu iwe kan ti wọn fi sọwọ si ile asofin lasiko ipade pẹlu awọn olori ile.
Gẹgẹ bi wọn ti wi, aridaju wa pe Gomina Nasir Elrufai ati awọn Gomina mii lo n sagbatẹru abadofin.
Bi a ko ba gbagbe, asofin to mu aba yii wa, Garba Datti Mohammad, n soju ẹkun Sabora Gat tipinlẹ Kaduna nile asojusofin Naijiria.
Amọ Gomina El Rufai ko ti fesi si ẹsun ti wọn fi kan an yii.
















