Insecurity in Yorubaland: Olugbon ní àwọn ọba ṣetán láti ti olóòtọ́ọ́ oníṣẹ̀ṣé lẹ́yìn lórí ìpèsè àbò

Oro

Oríṣun àwòrán, @tostvnetwork

Olugbon ti Orile Igbon ni ẹkun Ogbomoso, Ọba Francis Olusola Alao ti fesi si ọrọ awọn oniṣẹṣe to sọ pe awọn lagbara lati wa ojutu si eto abo to mẹhẹ nilẹ Yoruba.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Olugbon sọ pe iṣẹsẹ lagba lotitọọ, amọ opurọ lo pọ ninu awọn onisẹse, olootọ aarin wọn ṣọwọn.

''Mi o sọ pe awọn to n sọ otitọ ninu wọn ko si o, amọ bi awọn awọn aafa ati wolii eke ṣe pọ kaakiri, naa lo wa laarin awọn oniṣẹse pẹlu.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọba Olusola Alao ni ọpọ eeyan kan n fẹ ki awọn akọroyin maa gba ọrọ lẹnu wọn lasan ni.

''Ti awọn oniṣẹṣe ba fẹ fi otitọ ṣe e, ti wọn ba le wa ojutu si eto aabo to mẹhẹ nilẹ Yoruba, awa lọbalọba maa ti wọn lẹyin''.

Àkọlé fídíò, Nigerian Drone Maker: Roqeeb Aderogba ní ìgbà mẹ́fà l‘òun kùnà láti ṣe dírónù, kó tó yege

Oju gba mi ti fawọn onisẹse to se ayẹta ti

Kabiyesi ni ohun to maa n kọ oun lominu nipa ọrọ awọn oniṣẹṣe ni pe awọn to n fi otitọ ṣe e ko pọ rara.

Olugbon fi awọn kan to pe ara wọn ni ọmọ ẹgbẹ Agbekoya, ti wọn sọ pe awọn ni oogun ayẹta ibọn ṣe apẹẹrẹ.

''Lẹyin ti wọn pe ọfọ tan si ewurẹ kan lara ni wọn da ibọn bo, ṣugbọn ọta ibọn fa ewurẹ naa ya pẹrẹ pẹrẹ ni.

''Oju gba wọn ti, wọn ni lati maa sọ fun mi pe, awọn ti dan oogun naa wo kawọn to wa,'' Olugbo ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Farmers Herders Crisis: Rẹ́rẹ́ rún, ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò lágbègbè Ariwa Yewa

Adura nikan lọna abayọ seto aabo to mẹhẹ - Onpetu

Ẹwẹ, Onpetu Ijeru, Ọba Sunday Oyediran ti sọ pe adura ni ojutu si eto abo to mẹhẹ nilẹ Yoruba ati kaakiri orilẹede Naijiria.

Kabiyesi ni ko si ohun ti agbara Ọlọrun ko ka.

Onpetu ni ko si ohun to buru nibi ọrọ ti awọn oniṣẹṣe sọ pe awọn lagbara lati wa ojutu si ọrọ eto abo to mẹhẹ nilẹ Yoruba.

Kabiyesi ni ''ẹni to lagbara ko ni lọ sori redio tabi sọ fawọn akọroyin pe oun lagbara bi awọn oniṣẹṣe ti n ṣe.''

Nipa ọrọ ẹsin tawọn oniṣẹṣe sọ pe o n mu ifasẹyin ba ilẹ Yoruba, Onpetu ni ẹsin lo mu idagbasoke ba ilẹ Yoruba.

Kabiyesi ni ẹsin lo mu oriṣiiriṣii nkan amayedẹrun wa si ilẹ Yoruba ati orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Wakili tẹẹ rí yẹn kìí ṣe ẹran rírọ̀, ó ń díbọ́n ní o - Iba Gani Adams

A kọ òrìṣà babańlá wa sílẹ̀ ló jẹ́ kí ọ̀daràn darandaran máa pa wá bí ẹ̀fọn - Àwọn Oníṣẹ̀ṣe

Ni bayii ti oniruru ẹgbẹ ti n wa ọna abayọ si eto abo to mẹhẹ ni Naijiria, awọn ẹlẹsin ibilẹ ti sọrọ lori igbaradi wọn lati fopin si ipaniyan, ijinigbe ati gbogbo iwa ọdaran nilẹ Yoruba.

Lara awọn ipinlẹ ti ọrọ naa kan bii iṣan ọrun ni ipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti n koju iṣoro ija laarin awọn agbẹ atawọn Fulani darandaran, to n fi ibọn AK-47 da maalu.

N ṣe lo da bii pe gbogbo bi awọn eeyan ṣe n lọgun inira ti awọn ọdaran Fulani ọhun n fun wọn to, ijọba apapọ ko ka ọrọ naa kun.

Eyi lo fa ti oriṣiriṣi ẹgbẹ ati ẹya ni Naijiria fi n sọ pe ti ijọba ko ba le daabo bo wọn, awọn yoo daabo bo ara awọn.

Eredi ree ti awọn adari awọn ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ Ogun naa fi sọ pe awọn ní ọna abayọ lọwọ si eto abo naa to mẹhẹ, paapaa nilẹ Yoruba.

oro

Oríṣun àwòrán, Oro Festival

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abeokuta, Olu Iṣẹṣe ti ipinlẹ Ogun, Ọmọwe Ifarotimi Adifagbola sọ pe oriṣiriṣi awọn oriṣa lo wa ti awọn le ke pe lati daabo bo iran Yoruba.

Adifagbola ni o ṣeni laanu pe, awọn ẹlẹsin ibilẹ naa ti ṣina lẹyin ti wọn gbe ara le ẹsin atọhunrinwa, ti wọn si kọ ẹsin awọn babanla wọn silẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "awọn to n gbe ẹsin ẹlẹsin lori ti fa wa ṣẹyin gidi gan, a ti kọ awọn oriṣa awọn babanla wa silẹ ọjọ ti pẹ, eyi si lo jẹ ki awọn ọdaran darandaran yii maa pa wa bi ẹni pa ẹfọn."

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta

"Bo tilẹ jẹ pe awọn kan n sọ pe a ko si loju ogun, irọ ni o, oju ogun ni a wa. A si ni lati ke pe awọn oriṣa awọn babanla wa, ti mo si ni igbagbọ pe wọn jẹ wa ni oo."

Nigba to n da si ọrọ naa, Ọba Iṣegun ti Obada, Oloye Ololade Sunday ṣalaye pe "ko si ọdaran darandaran kankan ti yoo le da wahala silẹ nilẹ Yoruba ti wọn ba gba awọn ẹlẹsin ibilẹ laaye lati doju ija kọ wọn."

Sunday ni awọn agbegbe ti awọn janduku ọhun le maa dojukọ ni awọn ibi ti wọn ko ti bọwọ fun ẹsin abalaye ati aṣa.

Àkọlé fídíò, Bone setting: Adimula Kehinde Akinfenwa ṣàlàyé nípa irúfẹ́ ẹranko tí wọ́n fi ń to eegun èy

O ni ko le ṣeeṣe ki Oloye Sunday Igboho maa jijagbara fun ilẹ Yoruba ti ko ba ni agbara iṣẹṣe lọwọ.

Ẹwẹ, Ololade pari ọrọ rẹ pe, yoo ṣoro lati ṣe awọn oro kan lai si ifọwọsowọpọ ijọba nibẹ, nitori awọn nikan lo ní aṣẹ lati kede konile-o-gbele lasiko irufẹ oro bẹẹ.