Ìtàn ààrẹ John Pompe Magufuli dàbi ti Yar'Adua Nàìjíríà àti Atta Mills ti Ghana

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìtàn àti ikú ààrẹ John Pompe Magufuli dàbi ti ààrẹ Nàìjíríà nígbà kan ri Umar Musa Yar'Adua, Pierre Nkurunziza ti Burundi, John Attag ti Ghana àti àwọn ààrẹ mẹ́rin míìràn ti wọ́n kú sórí oyè.
Bí àwọn ààrẹ ilẹ adúláwọ̀ ṣe máa n lo sáà wọ́n tán lórí oyè, bẹ́ẹ̀ ni àwọn míràn máa n kú sórí àléfà.
Bí ti ààrẹ Tanzania, John Magufuli se ku ti aríyànjiyàn sì wà lórí ikú rẹ̀ ni náà lo ri ti kò si ẹni to mọ idí ikú àwọn olórí orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Afíríkà mííràn.
Àwọn ààrẹ orílẹ̀ -èdè mẹjọ ni a ṣe àkọ́jọ pọ̀ wọ́n ti wọ́n ku si ori aléfà.
Ààrẹ John Pompe Magufuli (2021)

Oríṣun àwòrán, AFP
Ààrẹ orílẹ̀ -èdè Tanzania John Pompe Magufuli náà ti darapọ̀ mọ́ àwọn olórí orílẹ̀-èdè to kú sórí àléfà.
Okú ni ọjọ́ kétàdinlógún, oṣù kẹta, ọdún 2021 lẹ́yìn oṣù péréte tó jáwé olúbori nínú ìbò ààrẹ lẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta.
Gẹ́gẹ́ ìgbákejì ààrẹ ṣe sọ Semia Suluhu Hassan ààrẹ àná kú látparí àìsàn ọkàn tó ti n bá fíra láti bi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.
Ìkéde yìí wáyé lẹ́yin bi ọ̀sẹ méjì ti kò sí ẹni tó kófìrí rẹ̀ ni àwùjọ, tí àwọn ènìyàn sì bẹ̀rl si ni tẹnubọlẹ̀ nípa ìlera rẹ̀ àti pé níbo ni ààrẹ wà.
Ààrẹ Pierre Nkurunziza (2020)

Oríṣun àwòrán, AFP
Ààrẹ Burundi tẹ́lẹ̀rí kú ni ẹni ọdún márùnléláàdọ́ta nínú oṣù kẹfà ọdún 2020. Gẹ́gẹ́ asṣójú orílẹ̀-èdè náà Willy Nyamitwe, NKuruziza ṣe sọ pé àìsàn ọkàn lo pa aèyí tó yàtọ sí ahesọ to n tànkálẹ̀
Gẹ́gẹ́ bi àtẹjíṣẹ́ kan lórí twitter lọjọ kẹjọ oṣù kẹrin ọdún tó kọjá pé " àgbárí jọ àwọn dókítà ko le dóòlà ẹmí rẹ̀ lẹ́yìn to ni àìsàn ọkàn"
Ọdún mẹ́ẹ̀dógún ni Pierre lo gẹ́gẹ́ bi ààrẹ Burundi
Ààrẹ Michael Sata (2014)

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Zambia Micael sata ku ni éni ọdún mẹ́tàdínládọ́rin, lẹ́yìn to lọ gba ìtọ́jú ni ilé ìwòsàn kan ti wọ́n ko dárúkọ ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ọjọ́ kejìdílọgbọ́n oṣù kẹwàá, 2014.
Ìròyìn sọ pé àìsàn to jọ mó ti ọkà náà lo paa.
Lẹ́yìn ìjáwé olúborí rl ni ọdún 2011, oniruuru ẹ̀rí to ko fídímúlẹ̀ lo n tàn ka gbogbo oríll-èdè Zambi. Nígbà ti wọ́n ko rii ni àárín àwùjọ mọ́, ni ọ̀pọ̀ ènìyàn bẹ̀rl si ni sọ̀rọ̀ nípa ìlera rẹ̀
Ààrẹ John Atta Mills (2012)

Oríṣun àwòrán, JOHN ATTA MILLS/FACEBOOK
Ààrẹ Ghana John Attah Mills tí ààrun jẹjẹrẹ pa, kú sí ilé ìwòsàn kan ní ìlú Accra lọ́dún 2012.
Àtẹjáde kan láti ọfíísì ààrẹ ẹni ọdún mẹj]idínláàdọ́rin ni ààrin wákàti díẹ̀ tó papòdà sọ pe ó ṣe àìsàn sùgbọ́n ko sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé.
Ọdún 2008 lo górí àléfa, tó si ṣe ìjọba fún ọdún mẹ́ta péré.
Ààrẹ JBingua wa Mutharika (2012)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ààrẹ míràn tó tún kú ni 2012 ni Bingu wa Mutharika ti Malawi
Àìsàn ọkàn náà lo pa òun náà nínú oṣù kẹrin ọdún, lẹ́[yin ọjọ́ méji ló gbèkurujẹ lọ́wọ́ ẹbọra lẹ́ni ọdún mẹ́jìdílọ́gọ́rin.
Ọdún mẹ́jọ lo fi sin orílẹ̀-èdè rẹ̀ ti ó sì ni àṣeyọri tó pọ̀ gidi, nítori ètò ounjẹ àti iṣk ọ̀gbìn tó gùnlé.
ÀàrẹMeles Zenawi (2012)

Oríṣun àwòrán, AFP
Oṣù kẹjọ ni àsojú ìjọba orílẹ̀- èdè Ethopia Meles Zenawi kú lọ́ddun 2012 lẹ́ni ọdún mẹ́tàdílọ́gọ́ta nilé ìwòsàn ilẹ̀ òkèrè kan gẹ́gẹ́ bí ìjọba ṣe sọ.
Ìjọn orílẹ̀-èdè Ethopia kò sọ ni pàtó irú ikú tó paa sùgbọ́n àgbẹnusọ EU kan sọ pe Brussels ni Belgium ló kú sí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣu ni Meles ko fi yọju si àwùjọ, ti ìròyìn nípa ilera rẹ si gbálẹ̀ kan nígbà ti ko péjú síbi ìpàdé kan tó wáye ni Addis Ababa.
Ọdún mọ́kànlélógún ni Meles fi jẹ à[rẹ láti ọdún 1991 si 1995 to si di asoju ijọba láti ọdun 1995 si 2012
ÀàrẹMoammar Gadhafi (2011)

Adari orílẹ̀-èdè Libya tẹ́lẹ̀rí ti àwọn agbénipa pa. Ó kú ni ìlú rẹ̀ Sirte ni éni ọdún mọ́kàndiláàdọ́rin, nígbà ti àwọn alatako ìjọba pá lẹ́yìn tó dar;i fún ọdún mẹ́jìlélógójì.
Moammar gorí àléfà lọdun 1969 lásìkò ti wọ́n dítẹ̀ gbàjọba ti wan sì yọ ọba Idris ti àwọn ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì gbé síbẹ̀.
Lásìkò rẹ̀ fún bi ọdún méjìlélógójì náà lo sé àgbékalẹ̀ ètò ìṣèjọba tírẹ̀, ó gbárùkò tí àwọn ọmọogun abẹ́lé bi IRA ni ìhà Nothern Ireland àti Abu Sayyaf ti Philipine, bákan náà lo n sàkóso North Africa to si jk olórí tó n fi ipa ṣe ìjọba to si burú janjan.
Ààrẹ Umaru Musa Yar'Adua (2010)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ààrẹ Yar'Adua kú lẹ́ni ọdún mẹ́jìdílọ́gọ́ta nítori àìsàn Pericarditis àìsàn tó niṣe pẹ̀lú ọkàn ni orílẹ̀-èdè Saudi Arabia
Ó di ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2007, lẹ́yìn à[rẹ olusegun Obasanjo, ó si jẹ́ ààrẹ náà fún ọdún mẹ́ta.
Lẹ́yìn tó wọ́lé gẹ́gẹ́ bi ààrẹ Nàìjíríà ni ìlera rl bẹ̀rẹ̀ si ni mẹ́hẹ.
Ààrẹ Joan Bernaredo Vieira (2009)

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ààrẹ Guinea Bissau ni àwọn agbénipa pa nínú oṣù kẹta ọdún 2009 ni ẹni ọdún mọ́kàndiláàdọ́rin
Gẹ́gẹ́ bi àtẹjáde nigbà náà, àwọn ọmọogun lo yin nibọn gẹ́gk bi ọ̀nà láti gbẹ̀san.
Lọ́dun 1978, ó dí àsojú ìjọba ó sì gba ìjọba lọ́dún 1980tí ó sì wà lórí àléfà fún ọdún mọ́kàndílógún.
O tún di ààrẹ alágbáda tó sì lo ọdún mẹ́rin míírà.
Ní ọdún 2005, Vieira ó tún jáwé olúborí nínú ìdìbò ààrẹ mííràn.
Ó dari fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n
















