Coronavirus Update:Ìjọba orílẹ̀-èdè Oman fòfin de Nàìjíríà àti orílẹ̀-èdè Mẹ́sàn míràn

Coronavirus Update:Ìjọba orílẹ̀-èdè Oman fòfin de Nàìjíríà àti orílẹ̀-èdè Mẹ́wàá míràn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba orilẹede Oman ti fofin de irinajo lati orilẹede miran wa si orilẹede wọn fun ọjọ marundinlogun.

Ijọba Oman ni awọn gbe igbesẹ naa lọna ati dẹkun itankalẹ aarun Coronavirus to n peleke si nibẹ.

Awọn orilẹede mẹjọ ninu mẹwaa ninu wọn lo jẹ awọn orilẹede nilẹ Afrika.

Awọn orilẹede naa ni Sudan, South Africa, Nigeria, Tanzania, Ghana, Ethiopia, Guinea ati Sierra Leone.

Amọ, awọn ọmọ orilẹede Oman laṣẹ lati rin irinajo kuro ni orilẹede naa, to fi mọ awọn oṣiṣẹ ijọba lati orilẹede miran ati awọn ẹbi wọn ni wọn laṣẹ lati rin irinajo.

Ijọba ni awọn araalu Ila Oorun Iwọ Afrika to n wa si orilẹede wọn ni wọn jẹ ida mejidinlogun awọn to ni arun naa lorilẹede wọn.

Àkọlé fídíò, 'Mo fọ kọ́mú, pátá, ògiri ilé lórí 200,000 láìlèfọhùn lórílẹ̀èdè Oman'

Amọ, awọn orilẹede ti wọn fofin de yii ko ba awọn lara mu, paapaa awọn ti wọn ti jọ ni ajọsepọ lati bi ọdunmọdun sẹyin.Lara awọn orilẹede ti wọn fofin de ni Naijiria ti aarun Coronavirus naa ti peleke si nibẹ.

Amọ, orilẹede Tanzania ni awọn ko ni aarun naa mọ ni agbegbe wọn, sugbọn aarẹ wọn tun ti paṣẹ fun awọn eniyan lati tẹle ofin to de aarun Coronavirus.

Ajọ eleto ilera lagbaye, WHO ni eniyan 140,000 lo ti ni aarun covid-19 ni orilẹede Oman, ti awọn eniyan to le 1500 si ti ku latari arun ọhun.Bakan naa ni iye awọn to n lugbadi aarun nibẹ n peleke si.

Àkọlé fídíò, Oman Returnees: Ọ̀kan lára àwọn obìnrin méjì náà ní òun ṣiṣẹ́ ọdún kan láì mú ₦5 padà wálé