iphone 13 price in Nigeria: Àwọn ǹkan ti a mọ̀ nípa àbùdá tuntun tó wà lára fóònù náà

iphone 13 realease date: Àwọn ǹkan ti a mọ̀ nípa àbùdá tuntun tó wà lára fóònù náà

Oríṣun àwòrán, Future

Bí àwọn ọmọ Nàìjíríà àti ọ̀pọ̀ ènìyàn lágbàyé ṣe n sọrọ̀ lórí iphone 12 lọ́wọ́ ni ní àwọn ilé iṣẹ́ náà tún ti n ronu bi wọ́n yóò ṣe tún gbé ẹ̀dà míràn jáde.

Lósàn òní ni ariwo gba orí ayélujára kan nípa ẹ̀rọ ìbánisọrọ̀ iphone 13 tí o sì ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù kí ó tó jáde si orí igbá.

Gẹ́gẹ́ bi ǹkan ti àwọn ilé iṣẹ́ náà sọ, ọ̀pọ̀ gbọ́yìsọ̀yí ni àwọn ti n ri lórí ayélujára nípa ẹ̀rọ iléwọ́ náà.

Àkọlé fídíò, Aṣọ funfun, ìṣáná, ọ̀bẹ̀ ilá...,ṣé ò lè sọ ìtumọ̀ àwọn àrokò yìí nílẹ̀ Yorùbá?

Kíni àwọn ǹkan tó yàtọ̀ nínú fóònù náà?

  • Gẹ́gẹ́ bi ilé iṣẹ́ náà ṣe sọ. ẹ̀rọ iléwọ́ náà yóò ni 120hz LTPO display lara ẹ̀yà kíní àti ìkejì
  • Bátírì tó n lò yóò tún lágbára síi
  • iphone 13 yoo le wa lori ayelujara tó jẹ́ 5G
  • Pabanbarì ni àwọn ẹ̀rọ ayawòràn rẹ̀ (camera) yóò jẹ́ èyi ti yóò ni sensor LiDAR lorí àwọn iphon 13 ti ko fi bẹ̀ẹ̀ gbówó lórí àti èyí tó jẹ
  • Ní ti bi o ṣe rẹwà sí, ìròyìn sọ pé, iphone tuntu yii ko ni ni ojú ihò kankan lára tí yóò sì máá lo ǹkan ti wọ́n pè ni MagSafe wirless charging
iphone 13 realease date: Àwọn ǹkan ti a mọ̀ nípa àbùdá tuntun tó wà lára fóònù náà

Oríṣun àwòrán, Future

Ìgbàwo ni fóònù náà yóò jáde?

Gẹ́gẹ́ bi ilé iṣẹ́ náà ṣe ti má n gbé àwọn ẹ̀rọ́ iléwọ́ wọ́n jáde tẹ́lẹ̀ iphone 13 ṣeeṣe ko jáde ni ọja Ẹti kéérin nínú oṣù kẹ̀sán ọdún 2021, eyí ti ṣe ọjọ́kẹrinlélógún oṣù kẹ̀sán.

Bótiolẹ̀ jẹ́ pé, iphone 12 wó inu oṣù kéwàá kó tó jáde ni ọdún 2020 níttori àjàkáll ààrùn coronavirus, àlabojutọ ètò nilé iṣẹ́ Apple Ming-Chi Kuo sàlàyé pe, àgbéjade fóònù tuntun kò ni yẹ̀ ni àsìkò tó má n jáde

Èló ni iphone 13 tuntun?

Àtẹjade tuntun kan lati ọwọ́ Ming-Chi Kuo sàlàyé pé ilé iṣẹ́ náà yóò se agbékálẹ̀ irúfẹ́ iphone onípele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mẹ́rin fún iphone 13

Àwọn ti ẹ̀ ó maa retí 5.4-inch iPhone 13 mini, 6.1-inch iPhone 13, 6.1-inch iPhone 13 Pro àti 6.7-inch iPhone 13 Pro Max.

Nípa iye tí owó rẹ̀ yóò jẹ́ ìròyìn sọ pé, owó rẹ̀ ko ni fi bẹ̀ẹ̀ pọ̀ jú ti iphone 12 lọ tó túms si pé iye rẹ̀ yóò wà ni $699 (#332,025,00), $799 (#379,799,00), $999 (#474,525,00) àti $1,099 (#522,025,00), Apple kò fi bẹ́ẹ̀ yẹba lórí iye tó n ta ẹ̀rọ̀ ilkéwọ́ rẹ̀ láti ìgbà de ìgba.

Kíni orúkọ iphone tuntun yìí

Sá'jú àsìkò yìí ni ọ̀ps tí n sọ pé, iphone 13 ni yóò máá jẹ́ nítorí àwọn èyí tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, sùgbọ́n ni àsìkò yìí, ójọ́ bi ẹni pé, iphone12s ni yóò maa jẹ́.

Báwo ni Iphone13 ṣe ri gan?

iphone 13 realease date: Àwọn ǹkan ti a mọ̀ nípa àbùdá tuntun tó wà lára fóònù náà

Oríṣun àwòrán, Future

iphone 13 realease date: Àwọn ǹkan ti a mọ̀ nípa àbùdá tuntun tó wà lára fóònù náà

Oríṣun àwòrán, Ajay Suresh