Fuel price hike: Ìjọba kò ti yọ́wọ́ kúrò nínú ìkúwọ́ owó epo, sùgbọ́n ìdí tí epo yóò fi wọ́n si rèé-IPMAN

Fuel Hike: IPMAN ti kesi awon omo Naijiria lati gbaradi fun owongogo epo bentirol laipe

Ileeṣẹ to n ṣe karakata epo lorilẹede Naijiria, IPMAN ti kesi awọn ọmọ Naijiria lati gbaradi fun ọwọngogo epo bẹntiro

National Operations Controller ẹgbẹ awọn elepo ni Naijiria (IPMAN), Mike Osatuyi lo sọ bẹẹ lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori iroyin to n kaakiri lori ọwọngogo epo bẹntirol ti awọn araalu n sọrọ nipa ẹ.

Osatuyi ni o kere tan awọn ọmọ Naijiria yoo ma ra epo ni igba Naijiria o kere tan, abi ko ju bẹẹ lọ.

O ni owo epo to gbe owo lori ati owo ilẹ okeere dọla to gbe owo lori lo fa a ti ọwọngogo fi ba epo bẹntirol ni Naijiria.

'Iye ti dọla ba jẹ ati owo epo rọọbi lo n jẹ ki epo wọn nitori naa owo epo ko le din ni igba naira abi ju bẹẹ lọ'

Bakan naa lo fikun wi pe owo ti ijọba ba ri lori epo nitori awọn nikan ni wọn n gbe epo wọle ni wọn fi n ṣe nkan fun araalu.

Arakunrin Osatuyi ni o da oun loju wi pe gbogbo nkan ni yoo gbe owo lori nitori epo bẹntirol lo ma n sọ bi ọja yoo ṣe ri lọrilẹede Naijiria.

' Owo ti ijọba ṣi n san lori epo bẹntirol bi owo iranwọ ni ọdọọdun fẹrẹ to biliọnu meji naira amọ ko si ninu agbekalẹ eto isuna mọ lorilẹede Naijiria.'

'Epo bẹntiro ni okun ẹmi ọrọ aje orilẹede Naijiria, owo ti ijọba si fi n ṣe nkan fun araalu wa lati owo ori epo'

Nitori naa ni o parọwa si araalu lati faragba a, ati pe ki ijọba fi ọgbọn ṣe e nitori o le e da wahala silẹ lorilẹede Naijiria, ti ohun gbogbo ba gbe owo lori.