Zaiah, Adesua Etomi Wellington Banky W baby : Ẹ̀yin náà le fẹ́ sọ ọmọ yin ni orúkọ yìí, ẹ wo ìtúmọ̀ orúkọ ọmọ náà

Oríṣun àwòrán, @bankywellington
Gbajugbaja Olorin ati osere, Banky Wellington, ti awọn eniyan mọ si Banky W ati iyawo rẹ ti bi ọmọ tuntun jojolo.
Ọjọ Aje ni ori ikansiraẹni, Instagram ni ọkọ ati iyawo naa ti fi idunu wọn han si ita, ti wọn si dupẹ lọwọ Ọlọrun.
Adesua ninu akole to fi lede sọ wi pe ' Ọlọrun to lagbara, ọrọ rẹ ko yi pada ri'.
'Ọsẹ mẹrin sẹyin ni mo gba ẹbun ọjọ ibi mi, ọmọkunrin mi'.
Bakan naa ni Banky W loju opo ikansiraẹni Instagram tire naa ki iyawo rẹ ku oriire to si dupẹ ayọ ọmọ tuntun jojolo ti Ọlọrun fun wọn.
O ni 'Aye mi, iyawo mi, iya ọmọ mi'.
'Ti o ba ṣeeṣe ki eniyan rẹwa ju eleyii lo, o rẹwa, o si tun jẹ obinrin alagbara''.
'Ọlọrun sọ ẹkun wa di ẹrin, o si sọ ohun ti a padanu di orin fun wa''.
Eleyii ti yi aye wa pada, ayọ si ni orin ti a o ma kọ''.
Kaakiri ni ọkọ ati iyawo ti jẹ ilumọọka, ti awọn eniyan si fẹran wọn ni agbo idaraya.
Ọdun 2017 ni wọn ṣe igbeyawo, ti ariwo si la gbogbo ori ayelujara kaakiri.
Kíni ìtumọ̀ Orúkọ Zaiah
Gẹ́gẹ́ bi ìwé atúmọ̀ orúkọ se sọ pé ida aadọta le diẹ orukọ ti awọn eniyan n jẹ ni agbaye wa lati inu orukọ ẹya awọn Heberu nígba ti ida mejidinlọgbọn jẹ Arabiiki.
àti oé idá mọ́kàndílógún jk èdè òyìnbó.
Ẹni kan lori ayelujara lati orilede Uganda ni orukọ ọmọ naa Zaiah tumọ si Ìgbàlà ni Olúwa (God is Salvation).

Oríṣun àwòrán, Adesua
Ẹlomiran lati Maryuland ni ilẹ Amerika salaye pe Zaiah jẹ orukọ ti wọn fayọ lara Saiah eyi ti awọn mejeji si wa lati ara Isaiah ninu bibel, ti ìtumọrẹ si jẹ Igbala ni Oluwa bakan naa.
Ẹnikan lat Virginia ni ilẹ Amerika bakan naa ni lati orilede Heberu ni orukọnaa ti jẹyọ ti itumọ rẹ si jẹ "Ebun Oluwa"
Awọn miran lati Ireland sọ pe Zaiah tumọ si pe "Arẹwa"
Ẹwẹ iwadii fi han pe Zaiah jẹ orukọ to wọpọ laarin awọn elede Arabiki, orukọ naa ko si mọ akọ tabi abo
Nkan tó yẹ ki o mọ̀ nípa Adesuwa Etomi

Oríṣun àwòrán, Adesua
- Apeja orúkọ rẹ ni Tolulope Adesua Etomi, o si ti kọ ni asiko kan pe inu oun maa dun bi awọn to mọ ohun dele se maa n pe oun ni Tolu.

Oríṣun àwòrán, Adesua
- Omo bibi ipinlẹ Edo ni Adesua, ti o si kawe gboye ninu inu imọ ere ori itage pẹ sabuke to yanranti julọ ni fasiti Wolverhampton U.K
- Lati kekere lo ti fẹran ere ori itage, ọmọ ọdun meje si ni o ti kọkọ bẹrẹ si ni ṣere ninu ẹgbẹ eleran klan nile ẹkọ alakọbẹrẹ Corona ni V.I
- Adesua ni abu gbẹyin nile wọn laarin ọmọ mẹta ti awọn obi rẹ bi, Ologun ni baba rẹ nigba ti iya rẹ jẹ onimọ ẹrọ.
- Lati ọmọ ọdun mẹtla ni Adesua ti lọ si ilẹ Gẹẹsi to si pada wa ni ọdun 2013, O pada wa lati U.K nitori o ni awọn iṣẹ akanse kan tó n sẹ to si pinu lati duro fun osu mẹta.
- Gbajugbaja osere yii sọ ni ọpọ igba pé awọn eniyan ko mọ pe alawada kẹrikẹri ni oun jẹ.

Oríṣun àwòrán, Adesua

Oríṣun àwòrán, Adesua
- Ọjọ kẹrinla oṣu kẹrin, Ọdun 2014 ni ere to lamilaaka ti Adesua kọkọ se ti wọn si gbe jade ni Sinima, lasiko to ba Enem Isong se ere ti wọn pe akọle rẹ ni "Knocking On Heavens Door"
- Adesuja gba ami ẹyẹ Africa Magic Viewers Choice Award (AMVCA) gẹgẹ bi ẹni to mọ ere se julọ
- Awọn sinima miran ti Adesua ti se ni The Call, Brave, Falling, A Soldier's Story, Out Of Luck, Couple Of Days, àti The Spirit Slowly Dies, The Arbitration, Music In The Desert ati The Wedding Party.

Oríṣun àwòrán, Adesua
















