Ifon chiefs vs Police: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní òun kò pe àwọn olóyè Ifon nítorí màálù tó kú

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa Najiria ti sọ pe awọn o ranṣẹ pe awọn oloye ilu Ifon ni ipinlẹ Ondo lati wa sọ tẹnu wọn lori iṣẹ iwadii ti awọn ọlọpaa n ṣe lasan ni.
Awọn oloye ọhun ti kọkọ ke gbajare pe ileeṣẹ ọlọpaa ranṣẹ pe awọn wa si ilu Abuja nitori maalu ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Abdullahi.
Amọ, aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa to ba BBC Yoruba lati ilu Abuja, DSP Ibrahim Agu ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa kan fẹ gbọ tẹnu wọn lasan ni.
- Ẹ̀jẹ̀ mi ni Damilare, ṣé ẹ lè dá abúrò mi padà fún mí? Mo ṣèlérí láti tọ́jú rẹ̀ - Mide-Funmi Martins
- Fifi òfin de dída máàlù kiri kò lè dẹ́kun àawọ̀ láàrin àwọn àgbẹ̀ àti darandaran àyàfi...- Fayemi
- Atukọ̀ bàálú tó já l'Abuja gbìyànjú gidi, ṣùgbọ́n omi pọ̀ ju ọkà lọ fún un - Ó sojú mi kòró
- Gẹ́gẹ́ bí àṣà, mo ti mọ̀ tipẹ́ pé mo máa jẹ ọba Akinghare II - Oba Oloyede
- Bí ẹranko igbó ṣe bu ìdí obìnrin kan tó ń bẹ̀rẹ̀ yàgbẹ́ jẹ
- Àwọn olóṣèlú gbọdọ̀ máa fi Ògún búra, bí Nàìjíríà bá fẹ́ dẹ́kun ìwà àjẹbánu - Guru Maharaj ji
Ileeṣẹ ọlọpaa ti kọkọ fi atẹjade kan jade sita pe ki Oloye Olaniyi Olotu to jẹ akọwe igbimọ awọn oloye ili Ifo, Oloye Olijewu, Saliu Omotosho, Oloye Ekon and Oluode ilu Ifon wa ni tẹnu wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn fẹ fi ọrọ wa wọn lẹnu wo lori ẹsun igbimọ pọ lati huwa ọdaran, idunkoko mọ ẹmi ẹni ati igbiyanju lati jinigbe.
Nigba ti o n fesi si ọrọ naa, alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro rọ awọn oloye naa lati yọju sawọn ọlọpaa niluu Abuja.
Ọgbẹni Ikoro ṣalaye pe bi ileeṣẹ ọlọpaa ti ranṣẹ pe wọn ko tumọ si pe ọdarab ni wọn.
O yẹ ki wọn lọ wi tẹnu wọn lori ọrọ naa ki wọn si gbagbe rẹ.
Ọgbẹni Ikoro sọ pe ko si ohun ti awọn ọlọpaa fẹ fi wọn ṣe ju pe wọn fẹ fi ọrọ wa wọn lẹnu wo.
Awọn oloye naa tiẹ sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko tii ri ohun kan ṣe lori ọrọ ọba ilu, Oba Israel Adeusi ti wọn sọ pe awọn agbebọn kan ṣeku pa.
Ṣugbọn awọn ọlọpaa n pe awọn wa si ilu Abuja lori ọrọ maalu kan to ku.
Amọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ondo ṣalaye pe oun ko mọ ohun kan nipa iṣẹlẹ maalu to ku, o ni ọsẹ to lọ ni ọga ọlọpaa DPO ilu pe oun lori ọrọ naa.
Ikoro fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa si n ṣe iwadii lori iṣẹlẹ iṣekupani oba ilu Ifon.














