Farmers-herdsmen crisis: Fayemi ní fifi òfin de dída máàlù kiri kò lè dẹ́kun àawọ̀ láàrin àwọn àgbẹ̀ àti darandaran

Kayode fayemi ati darandaran

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kayode Fayemi

Gomina ipinlẹ Ekiti to tun jẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria, Ọmọwe Kayode Fayemi ti ni fifi ofin de dida maalu kaakiri kọ ni ojutu si aawọ to n ṣẹlẹ laarin awọn darandaran atawọn agbẹ ni Naijiria.

Ọmọwe Fayemi sọrọ yii lori eto kan lọjọ Aiku lori amohunmaworan Channels niluu Eko.

Fayemi sọ pe fifi ofin de dida maalu kaakiri lai wa bi awọn darandaran yoo ṣe maa ko ẹran wọn jẹ oko ko ni fopin si wahala to n bẹ silẹ laarin awọn agbẹ atawọn darandaran.

''Gbogbo gomina lo ṣe adehun lati wa ọna ti awọn darandaran yoo fi maa tọju maalu wọn lai pa ẹnikan kan lara.

A ni lati wo bi a ṣe le tẹle eto sinsin ẹranko lọna igbalode yala nipa kikọ ọgba fun wọn ati pipese ọna mii lati maa fun wọn lounjẹ,'' Fayemi ṣalaye.

Gomina Fayemi tun sọ pe gbogbo nkan yii ko le ṣẹlẹ lọjọ kan tori aawọ naa ti n ṣẹlẹ fun ọjọ pipẹ.

Fayemi ni diẹ diẹ ni ofin ki awọn darandaran ma ma da maalu kaakiri yoo fi mulẹ ti awọn ọlọsin ẹran yoo si bẹrẹ si ni kọ gba fawọn ẹran wọn.

Bakan naa ni Fayemi tun fikun ọrọ rẹ pe ijọba gbọdọ ṣe iranwọ fawọn ọlọsin ẹran gẹgẹ bi wọn ṣe n ran awọn agbẹ onirẹsi ati awọn to n gbin ẹgẹ lọwọ.

Gomina ipinlẹ Ekiti tun sọ pe ai tete da ṣheria fawọn darandaran to tasẹ agẹrẹ lo jẹ ki awọn ma sọ pe ipinlẹ Ekiti n ṣegbe lẹyin awọn darandaran.

Àkọlé fídíò, Gẹ́gẹ́ bí àṣà, mo ti mọ̀ tipẹ́ pé mo máa jẹ ọba Akinghare II - Oba Oloyede