‘Ìjọba àti àgbáyé ti gbàgbé Chibok’

    • Author, Azeezat Olaoluwa
    • Role, BBC reporter
    • Reporting from, Chibok, Nigeria

Chibok: Ìlú tí ayé gbàgbé lẹ́yìn tí àwọn agbésùnmọ́mí jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 276 lọ níbẹ̀

Woman holding photos while crying

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma

Ninu oṣu Kẹrin ọdun 2014 ni ọpọ eeyan kaakiri agbaye bẹrẹ si n jẹ ọrọ Naijiria lẹnu lẹyin ti awọn agbebọn ji akẹkọọ 276 gbe niluu Chibok, ni Ariwa Naijiria.

Ọdun mẹwaa lẹyin iṣẹlẹ naa nnkan ko tii yipada latari oniruru iṣẹlẹ ijinigbe to n waye lagbegbe naa.

Pẹlu omije loju ni Esther Yakubu fi n ṣeranti igbe aye inira to n gbe lẹyin ti wọn ji ọmọ rẹ Dorcas gbe lọdun mẹwaa sẹyin.

O ni “O ti pe ọdun mẹwaa ti ọmọ mi ti wa lakata Boko Hamra. Ko rọrun rara.

“Awọn kan ni ki n gbagbe nipa rẹ, pe ṣebi mo bi awọn ọmọ miran, ṣugbọn mo maa n ranti ti n ba ti da wa nikan.”

O ni inu oun maa n bajẹ ti oun ba ti n ri awọn dukia ọmọ naa loun ṣe ko wọn danu ayafi awọn aworan diẹ.

Lẹyin iṣẹlẹ ijinigbe naa ni gbogbo agbaye bẹrẹ si n bere idapada awọn ọmmọdebinrin akẹkọọ ọhun pẹlu ami #bringbackourgirls lori ayelujara.

Lara awọn to da si ọrọ naa ni iyawo Aarẹ Amẹrika tẹle, Michelle Obama, ati obirin to gba ami ẹyẹ Nobel Laureate, Malala Yusufzai, to fi mọ ọpọ awọn gbajumọ ilu mii.

Malala Yousafzai standing next to parents of the abducted Chibok girls in Nigeria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin ọdun mẹwaa ti iṣẹlẹ naa waye, pupọ ninu awọn ọmọ ọhun ni wọn ti doola, ti awọn kan ninu wọn tun moribọ.

Amọ ṣa, 87 ninu awọn 276 ti wọn ji gbe lo ṣi wa ni ahamọ awọn agbebọn naa ti ko si sẹni to mọ irufẹ ipo ti wọn wa bayii.

Dorcas wa lara awọn to ṣi wa lahamọ, ọmọ ọdun mẹrindinlogun pere ni lọdun ti wọn ji wọn gbe.

Iya rẹ, Esther, sọ pe o ṣoro fun oun lati gbagbe nipa ọmọ naa.

O ni “mo fẹ ki ijọba tu awọn ọmọ wa silẹ ki wọn si pada wale, a fẹ ri awọn to ṣi wa laaye ki a le fi oju wa ri wọn.

“Ni ti awọn ti ko si laaye mọ, a fẹ mọ ipo ti wọn wa boya wọn ti ku ni ki a le mọkan kuro nibẹ.

“Ti Dorcas ba n gbọ mi bayii, mo maa sọ fun pe mo ṣi wa laaye ati pe ilu Chibok ṣi wa ko le tiraka lati pada wale.”

Chibok central market high street

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma

Ile ẹkọ tuntun

Sign of Chibok secondary school outside the new school buildings.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma

Ijọba ti ṣatunṣe ile ẹkọ awọn ọmọ naa, iyẹn Government Secondary School lọdun 2021 lẹyin ọpọ ọdun iṣẹlẹ ijinigbe ọhun.

Ijọba tun wo ilegbe ti Boko Haram ti ji awọn ọmọ naa, nitori naa ko si apẹrẹ iṣẹlẹ naa nibẹ mọ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ṣẹṣẹ tun ile ẹkọ naa ṣe, ọda ti wọn fi kun un ti n ṣi, eyii to ṣeeṣe ko jẹ nitori oru ati bi oju ọjọṣe ri nibẹ.

Muhammad Chiroma ni olori ilẹ ẹkọ ọhun tuntun ti ijọba yan lọdun 2021.

Chiroma sọ fun akọroyin BBC pe eto abo ibẹ ti dara ju ti tẹlẹ lọ.

O ni awọn obi to mu awọn ọmọ wọn kuro nile ẹkọ ti n da wọn pada.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, abo to peye ti wa fun awọn, oun si gbagbọ ninu akitiyan awọn ologun lati fun wọn ni aabo to peye.

Amọ ṣa, laarin oṣu Kejila ọdun 2023 si oṣu Kinni, ọdun 2024 yii, Boko Haram tun ti kọlu agbegbe naa leralera, ninu eyii ti nnkan bii eeyan mẹrinla ba lọ.

Igbiyanju ijọba

Sẹnetọ to n ṣoju Chibok lati inu ẹgbẹ oṣelu APC, Muhammad Ali Ndume ni ijọba ko kawọ gbera lori awọn akẹkọọ naa.

O ni “Ohun ti mo maa sọ fun awọn obi naa ni ki wọn ṣe suuru, ki wọn si tẹsiwaju ati maa gbadura pe awọn ọmọbinrin wọn yoo pada wale.

Ndume sọ pe owo itusilẹ ti ijọba to kuro lori alefa san lati gba itusilẹ ọmọ to le ni ọgunrun tunbọ ṣakoba fun awọn to wa ni ahamọ ni.

Senator Mohammed Ali Ndume, Borno South District

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma

O ni “Ọlọrun nikan lo mọ iye owo ti wọn san fun itusilẹ wọn, mo gbagbọ pe lati igba naa ni wọn ti ro pe ti wọn ba le ji eeyan gbe, owo tabua ni yoo tẹle.

“Aṣiṣe nla gbaa ni, aṣiṣe naa lo si ṣilẹkun eto abo to mẹhẹ ti a n koju lonii yii.”

Ijọba Naijiria sọ lasiko naa pe oun ko san owo itusilẹ kankan fun ajinigbe naa, eyii to take ọrọ Ndume yii.

Ẹwẹ, Ndume kọ lati gbagbọ pe oun ti ja awọn eeyan Chibok kulẹ.

O pari ọrọ rẹ pe oun gbagbọ pe awọn ọmọ 87 to ṣi wa ni akata Boko Haram yoo si pada wale laipẹ.