Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá ní àhámọ́ ikọ̀ Boko Haram, wọ́n ṣàwárí akẹ́kọ̀ọ́ Chibok míì

Ìkọ ẹ̀ṣọ́ ààbò tó ń mójútó àwọn igbó ní ẹkùn ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà lọ́wọ́ àwọn agbéṣùmọ̀mí ti dóòlà akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Chibok mìíràn, Lydia Smith lọ́wọ́ ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Boko Haram.
Ìròyìn sọ pé àwọn ọmọ ogun 82nd division tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Gwoza ló dóòlà Lydia àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta lọ́jọ́rú.
Lydia tó fa ara rẹ̀ lé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà lọ́wọ́ ní Gwoza ni wọ́n sọ pé ó wà nínú oyún oṣù márùn-ún àti pé láti ìlú Pemi ní Chibok ni òun ti wá.
Ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹrin ni ó pé ọdún mẹ́wàátí àwọn ikọ̀ Boko Haram jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 276 gbé ní ilé ẹ̀kọ́ wọn ní Chibok, ìpínlẹ̀ Borno.
Àwọn 57 móríbọ́ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé náà lásìkò tí wọ́n jí wọn gbé.
Bákan náà ni àwọn 123 tún gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àkàtà àwọn ikọ̀ Boko Haram lẹ́yìn tí ìdúnàádùrá wáyé láti gba ìtúsílẹ̀ wọn.
Ìjọba àtàwọn ológun ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ri pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní àhámọ́ àwọn Boko Haram ni àwọn gba ìtúsílẹ̀ wọn.
“Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí wọ́n jí akẹ́kọ̀ọ́ 276 gbé ní Chibok, mo ṣì ń retí ọmọ mi”
Ọdun mẹwaa sẹyin ni awọn agbesumọmi ji akẹkọbinrin ti iye wọn jẹ 276 gbe ni niluu Chibok, ni Ariwa Naijiria.
Inu oṣu Kerin ọdun 2014 ni iṣẹlẹ naa waye, iṣẹlẹ ọhun si ti da ọgbẹ ayeraye si ara ilu naa ati ọkan awọn eeyan rẹ.
Gbogbo agbaye lo gbọ nipa iṣẹlẹ naa lọdun naa lọhun, ti ọpọ eeyan kaakiri agbaye si ke si awọn ijọba orilẹeede agbaye lati doola awọn akẹkọọbinrin naa pẹlu ami #bringbackourgirls lori ayelujara.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo ti gbagbe nipa iṣẹlẹ yii, ọpọ awọn olugbe ilu naa lo n sọ pe bi ana ni ọrọ ọhun ṣi ri loju awọn.
Dorcas Yakubu wa lara awọn ọmọ ti wọn ji gbe, ọmọ naa ko si tii pada wale titi di oni yii lẹyin to farahan ninu fidio kan lọdun 2016.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma
Ninu ifọrọweọ pẹlu BBC, iya Dorcas sọ pe ojojumọ ni oun maa n ronu nipa ọmọ naa, ti oun si maa n gbadura fun nibiki to ba wa.
Iya akẹkọọ mii ti wọn ji gbe, iyẹn Rebecca Samuel, sọ pe oun gbagbọ pe ọmọ oun ṣi maa pada wale.
Iya Rebecca sọ pe ọmọ naa yoo pada wale lọjọ kan bo tilẹ to ogun .
Ẹwẹ, ọga agba ile ẹkọ awọn akẹkọọbinrin ọhun, Muhammad Chiroma sọ pe ijọba ti ṣatunṣe rẹ, awọn ologun si n sọ agbege rẹ loorekoore.
Chiroma ni awọn akẹkọọ tuntun ni awọn n gba wọle ni gbogbo igba.
Sẹnetọ to n ṣoju Chibok, Ali Ndume ni tirẹ sọ pe ijọba ko gbabe ilu naa, ijọba si n ṣiṣẹ lọwọ lati doola awọn akẹkọo Chibok atawọn mii to wa lakata awọn ajinigbe.
















